Human Rights day: Aṣíwájú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní Àìbọ̀wọ̀ fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ń fa wàhálà ètò àbò

Àkọlé fídíò, Human Rights day: Aṣíwájú ajàfẹ́tọ̀ọ́ ní Àìbọ̀wọ̀ fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ló ń fa wàhálà ètò àbò

Ọjọ ẹti ọjọ kẹwa oṣu kejila ni ayajọ ibọwọ un ẹtọ ọmọniyan lagbaye, BBC News Yoruba ba aṣiwaju amofin lori ẹtọ ọmọniyan lagbaye, Amofin Adeola Oyinlade Sọrọ lori pataki ọjọ yii lorilẹede agbaye, paapaajulọ lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ Amofin Oyinlade ni ko si irọ ninu awọn abajade igbelewọn eyi ti awọn ajọ ajafẹtọ lagbaye bii Amnesty International n gbe jade lori ibi ti ọrọ de duro lori ibọwọ fẹtọ araalu lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni aibọwọ fun ẹtọ araalu gan ni eku ẹda to da eyi silẹ lori wahala ipenija abo lorilẹede Naijiria ni lọwọlọwọ.

O ni ko si bi eto abo to gboopsn ṣe lee wa ni orilẹede ti ko ba bọwọ fun ofin.

Ninu ọrọ kan ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ laipẹ yii pe ni ti oun, abo lagbara ju ibọwọ fun ẹtọ araalu lọ, amofin Adela Oyinlade ti o ṣẹṣẹ gba ami ẹyẹ amofin ti o dantọ julọ lagbaye lori ọrọ ija fun ẹtọ araalu lati ọwọ ẹgbẹ awọn amofin lagbaye, IBA, ṣalaye pe ko lee si abo bi ko ba si ibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.

O ni ijọba to wa lode bayii ṣi ni iṣẹ lati ṣe lori bibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.