Saraki: PDP yóò mókè ní Kwara, yóò tún gba ipò ààrẹ

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Aarẹ ile asofin agba, Dokita Bukọla Saraki ti fọwọ gbaya pe fawọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu PDP pe didun lọsan yoo so fun ẹgbẹ oselu naa ninu idibo ọdun 2019.

Bakan naa lo rọ wọn lati mase naani agbara ijọba apapọ to wa labẹ ẹgbẹ oselu to n se ijọba orilẹede yii lọwọ.

Bukọla Saraki fọwọ idaniloju yii sọya lasiko to n sefilọlẹ igbimọ eleto ipolongo fẹgbẹ PDP, ẹlẹni mejilelogoji, eyi to waye nilu Ilọrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìfipálówó: Bàbá ọmọ tí wọn gé lórí ní òun rán an láti l gbowó lẹ́nu ATM ni

Saraki fi kun pe ẹgb oselu PDP ni awọn amuy to y lati ẹyin ẹgbẹ APC to n sejọba lọwọ janl ninu ibo to n bọ.

"Ẹyin ololufẹ PDP, ẹ ko gbọdọ bẹru nipa agbara ijọba apapọ ninu ibo to n bọ, mo ti koju wọn agbara ijba apapọ ni ẹẹmeji ọtọọtọ ri, ti mo si fẹyin wọn janlẹ."

Bula Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Aarẹ ile asofin agba tun tọkasi pe, ibo 2019 ni awọn ipenija tiẹ lootọ, gẹgẹ bii awọn eto idibo yoku, amọ o ni iriri atẹyinwa ti fi han pe, tawọn ba gbe igbesẹ to tọ, tawọn si rin bo se yẹ, kedere lẹgbẹ oselu PDP yoo moke lọdun 2019.

O tẹsiwaju pe, yatọ si pe PDP yoo bori ni ipinlẹ Kwara, yoo tun moke ninu ibo aarẹ pẹlu.