Adeboye: Màá fi ọlọ́pàá gbé ẹni tó bá lo fọ́tò mí sára kàlẹ́ńdà

Adejare Adeboye

Oríṣun àwòrán, @rcgchristchurch

Olusọagutan Adejare Adeboye ti n fi ewe ọmọ mọ awọn ọmọlẹyin ijọ Redeem lagbaye pe ki wọn pinwọ iwa fifi aworan oun ati aya oun sara awọn ẹbun ti wọn ba n pin.

Adeboye ni eniyan lasan ni oun, oun kii si se Ọlọrun rara.

Lasiko to n kasẹ isin ipagọ ẹmi mimọ ọlọdọọdun ijọ Redeem nilẹ, ni Adeboye sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe awọn ọmọ ijọ naa kan tun maa n lo aworan iyawo oun sara ẹbun pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Kékeré ni mo ti mọ̀ pé iṣẹ́ apanilẹ́ẹ̀rín l'ọ̀nà mi'

"Emi kii se Ọlọrun. Ẹ ye ri mi tabi fi mi we Oluwa rara nitori eniyan ẹlẹran ara ni mi, ẹ ye fi aworan mi ati ti aya mi sara awọn eroja kankan."

Adeboye fikun pe oun ko f ri ibinu Ọlọrun, yoo si dara kawọn eeyan naa ma mu oun kọsẹ niwaju Ọlọrun pẹlu aworan oun ti wọn fi n pe Ọlọrun yii.

Adejare Adeboye

Oríṣun àwòrán, @rcgchristchurch

"O ti de si etigbọ̀ mi bayii pe awọn eeyan kan n lo fọto mi lara kalẹnda, iwe, ẹbun tẹ n pin ati ‘keyholder’. Eyi ko tọna rara, ma si fi ọlọpaa mu ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n se bẹẹ."

"Eniyan Ọlọrun lasan ni mi, emi kii se Ọlọrun, Ọlọrun ko ni ba eniyan kankan pin ninu ogo rẹ, emi ko si setan lati ku, Esu, emi ko setan lati ku o"