Kano Killer Juice: Ìjọba Eko, Osun, Katsina, Cross River àti Sokoto figbe ta lẹ́yìn tí ẹlẹ́rindòdò gbẹ̀mí èèyàn mẹ́wàá

Obinrin to n mu ohun mimu ẹlẹrindodo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba ipinle Kano ti kede pe, eeyan mẹwaa ti dero ọrun, ti awọn irinwo miran si ti dero ile iwosan, lẹyin ti wọn mu ẹlẹrindodo kan ti wọn ko darukọ rẹ.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ naa ti kọkọ sọ pe ẹlẹrindodo yii kan naa gba ẹmi eeyan mẹta, to si sọ eeyan mẹtalelọgọjọ dero ile iwosan.

Kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ ọhun, Aminu Tsanyawa, sọ ninu fidio kan ti wọn fi ṣọwọ si awọn akọroyin pe, ninu awọn irinwo to wa nile iwosan, nnkan bi aadọta lo n gba itọju lọwọ lori aisan to jọ mọ kindinrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi ijọba Kano ṣe n lọgun pe ki awọn eeyan ṣọra fun ẹlẹrindodo naa, awọn ijọba ipinlẹ Eko, Katsina, Cross River, Sokoto ati Osun naa ti n kilọ fun awọn eeyan ipinlẹ awọn lati ṣọra fun mimu oniruru ẹlẹrindodo.

Gomina Kano, Ganduje

Oríṣun àwòrán, Kano State Government

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni ki awọn eeyan ma foya, wọn ki wọn nilọ lati maa wo ọjọ ori ẹlẹrindodo ki wọn to maa mu.

Nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Kano lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta, Aminu Tsanyawa sọ fun awọn eeyan pe aisan naa ti tan de ijọba ibilẹ mẹtala.

Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ naa sọ pe lara awọn ami ti awọn to lugbadi aisan ọhun n fi han ni itọ pipọn, iba ati oju pipọn.

Lẹyin naa ni wọn rọ awọn eeyan naa lati sọra fun irufẹ ẹlẹrindodo ti wọn yoo maa mu, paapaa lasiko Ramadan yii.

Iwadii ti ajọ NAFDAC ṣe fi han pe lara awọn eroja ti wọn fi po ẹlẹrindodo naa ni "Hyroxylamine" wa, eyi ti wọn ni awọn agbesumọmi maa n lo lati fi ṣọṣẹ.

Àkọlé fídíò, Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

NAFDAC fi kun pe ọwọ ti tẹ awọn to wa nidii ileeṣẹ to n po ẹlẹrindodo naa, iwadii si ti bẹrẹ.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti kilọ fun awọn eeyan ipinlẹ rẹ lati maa wo ọjọ ori ẹlẹrindodo ki wọn to maa mu.

Kọmiṣọna fun ọrọ to n lọ, Gbenga Omotoso sọ fun awọn akọroyin pe ki awọn araalu ma ṣe mu ẹlẹrindodo ti ko ba gba ontẹ ajọ NAFDAC.

Nigba to n sọrọ lori ẹlẹrindodo to n ṣekupa awọn eeyan ni Kano, Omotoso sọ pe awọn ko ni gba ki ẹnikẹni ta ẹlẹrindodo naa nipinlẹ oun.

Ni ipinlẹ Osun, olubadamọran pataki si gomina Gboyega Oyetola, Siji Olamiju ti kilọ fun awọn araalu lati sọra fun mimu ẹlẹrindodo ti wọn ko ba mọ daadaa.

Àkọlé fídíò, Slain Ekiti Police woman: Ìyá rẹ̀ ní àìrìṣẹ́ṣe ló mú kí Bukola Olawoye gba iṣẹ́ ọlọ́pàá

O sọ pe o rọrun lati ko ẹlẹrindodo to n paayan ni Kano wọ ipinlẹ Osun nitori bi awọn eeyan oke ọya ṣe pọ ni ipinlẹ naa, nitori naa oju ni alakan fi n ṣọri.

Olamiju ni "a ti gbọ nipa ẹlẹrindodo ti NAFDAC sọ pe o n pa awọn eeyan ni Kano, a fẹ fi akoko yii rọ awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn eeyan ipinlẹ Osun lati maa sọra fun ẹlẹrindodo ti wọn ko ba mọ daada lasiko awẹ yii."

O pari ọrọ rẹ pe iṣẹ ti bẹrẹ pẹlu ajọṣepọ NAFDAC lati ṣawari ẹlẹrindodo naa, ki wọn le ko kuro nipinlẹ Osun to ba jẹ pe o ti wa lori igba.