Nigeria Cash Crunch: Ọ̀dá owó n bá ìjóba àpapọ̀ fíra, àwọn gómìnà Yorùbá ní kò sí gìrì

Oríṣun àwòrán, AFP
Àwọn aṣojú ìjọba ni ìhà ìwọ̀-òòrùn Gúúsù Nàìjiríà ti ni, lábẹ́ àkóso bótiwùkórí, àwọn kò le jẹ òṣìṣẹ́ lówó oṣù kankan.
Ọ̀rọ̀ yìí kò ṣẹ̀yin bí àwọn aṣojú ìjọba àpapọ̀ méjì kan ṣe ké gbàjare pé, orílẹ̀-èdè yìí nílò ìrànwọ́ owó ní wàrànṣesà, láti pese ohun eelo amáyédérun fún ara ìlú.
Bó tílẹ̀ jẹ́ pé mínísítà fún ètò ìsúná Zainab Ahmed bẹnu atẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí gómìnà ìpínlẹ̀ Edo sọ pé, ìjọba apapọ̀ lọ tẹ́ owó tó tó ọgọ́ta bílíọ̀nù nàìrà lósù tó kọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àjọ̀dún òkú rèé níbi tí alààyè ti ń tọrọ owó, ọmọ àti ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ ẹ̀mí àìrí
- Obìnrin bíi 1000 láti orílẹ̀èdè 17 bẹ Ọọ̀ni wò fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Oduduwa
- Ẹ gbà wá, ọ̀daràn darandaran tún ṣá àgbẹ̀ míì pa, ọ̀rọ̀ yìí yóò di wàhálà láìpẹ́ - Baálẹ̀ Àgbẹ̀ Tapa
- Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ tó bá fààyè gba ìpolongo Oduduwa Nation, a fà á lé DSS lọ́wọ́ ni - Ìjọba Osun
- Ajimobi kú, ìdàgbàsókè dúró, ojú kan nípìnlẹ̀ Ọyọ wà - Sheikh Bello
- Ọ̀pọ̀ Yorùbá kò fẹ́ àtúntò mọ́, wọ́n fẹ́ ká dá dúró ni, èrò tèmi nìkan kọ́ - Gani Adams
- Ọ̀gá iléèwé mẹ́ta wọ gàù lọ́dọ̀ ìjọba Ọsun torí ìpolongo ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Odùduwà
Gomina Godwin Obaseki ni owo ti wn tẹ ọhun lo jẹ kí wọ́n ri owó ajẹmọ́nú ìpínlẹ̀ olosoosu awọn ijọba ipinlẹ pín fún wọ́n.
Amọ Ahmed sọ pé ìjọba kan nílò láti mú àlékún bá owó àpawọlé fún ìjọba.
Ìdí rèé tí BBC Yorùbá ṣe bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kan ni ìjọba ìpínlẹ̀ sọ̀rọ̀, lórí ìgbáradì wọ́n bí owó ajẹmọ́nú olóṣooṣù láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀ kò bá wọlé lásìkò tó yẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bí owó ìjọba apapọ kò bá wọlé, ìpínlẹ̀ Oyo ko le jẹ gbèsè:
Àkọ̀wé ìròyìn fun gómìnà nípínlẹ̀ Oyo, Taiwo Adisa sàlàyé pé láti ìgbà ti gómìnà Seyi Makinde ti gorí àléfà, idá mẹ́rìndílọ́gbọ̀n ní ètò ọ̀rọ̀ ajé fi rú gọ́gọ́ sí, fún ìdí èyí tipẹ́ tipẹ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti wa wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdá nipa ọda owo naa.
Ó ní ètò ọ̀rọ̀ Aje jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àfojúsùn onígunmẹ́rìn Gómínà Makinde, nítorí náà ni àwọn ṣe tí n gbé ẹ̀ru wiwo naa láti ilẹ̀.
O ni bí owó ìjọba kò bá tilẹ̀ wọlé, ìpínlẹ̀ Oyo ko le jẹ gbèsè.
Adisa ni tó bá ṣe díẹ̀ sí, owó tí ìjọba àpapọ bá ń sàn yóò kan dà bi àfikún owó ni, nítorí lọ́wọ́ báyìí, ìjọba ń sapa láti jẹ́ ki ètò ọ̀rọ̀ ajé rú gọ́gọ́ sí ni, nípa dídí àwọn ọ̀nà tí owó ìjọba ń gbà sòfò.
"Kótó dí pe ọdún mẹ́rìn yìí yoo fẹnu kọ́lẹ̀, ìdá ọgọ́ta iyé owó tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo nílò ni yóò maa pèsè fún ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ ijọba apapọ kọ ni ipnilẹ Eko ti n gba owo fun ipese ohun meremere:
Bákan náà ni kọ́mísọ̀nà ọ̀rọ̀ tó n lọ ní ìpińlẹ̀ Eko Gbenga Omotosho náà sàlàyé pé láti ilẹ̀ ní gbogbo ènìyàn ti mọ̀ pé ìpínlẹ̀ Eko kìí fí owó ìjọba apapọ̀ ṣe gbogbo ǹkan mère mère ti wọ́n ń rí ni ìpińlẹ̀ Eko.
Ó ni àfojú sùn Eko ni láti dàbi àwọn orílẹ̀-èdè tó ti tójúbọ́ ni àgbáyé nítori náà, wọ́n n lo owo orí ara ilú láti ṣe iṣẹ́ ribiribi ti wọ́n n ṣe, tí ọ̀pọ̀ ko si gbẹ́yìn nínú owó orí sísan.
Omotosho ni oníruurú ètò ni ìjọba n se láti mú ǹkan dẹ̀run fún àwọn èlétò-ọ̀rọ̀ ajé tó bá fẹ́ dá ilé iṣẹ́ sílẹ̀, èyí sí n jẹ́ kí ètò ọ̀rọ̀ ajé gbòòrò sí ni ìpínlẹ̀ Eko.
Oore ọfẹ Ọlọrun nijọba Osun fi n gbera tẹlẹ, ẹru ko ba wa:
Bákan náà ni ọ̀rọ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Osun gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé ìròyìn Gómìnà Ismail Omipidan ṣe sọ.
O ni láti ìgbà ti gómìnà Adegboyega Oyetola ti gorí oyè láti ọdún méjì sẹ́yìn, kò sí owó kan tó dàbí alárà tó n wá láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀.
- Ìsìn àrà ọ̀tọ̀ wáyé níjọ Canterbury Cathedral láti yẹ́ Ọmọọba Phillip sí
- Ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ Chibok pé ọdún méje, ọjọ́ wo ni wọn yóò padà sílé?
- Wo ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn Ààrẹ́ Buhari àtàwọn èèkàn ọmọ Nàìjíríà míì sí Ọbabìnrin Elizabeth fún ìpapòdà ọkọ rẹ
- Èèmọ̀! West Brom fi omi àbùkù wẹ̀ fún Chelsea lọ́sàn án gangan nílé wọn
"Ní oṣù míràn wọ́n kìí fí owó kankan ránṣẹ́ sí ìpínlẹ̀ Osun, èyí sì tí jẹ́ kí a sán sòkòtò wa le láti ilẹ̀, a kìí dúró de owó láti ọ̀dọ̀ ìjọba àpapọ̀."
Omipidan ni "nítorí ìdí èyí ni a ṣe mú ètò ọ̀rọ̀ ajé, ibi ìgbáfẹ́, wíwa kùsà, àti iṣẹ́ ọ̀gbìn ni ọ̀kúnkúndùn."
O sàlàyé pé ìpińlẹ̀ Osun yàtọ̀ gédégédé sí àwọn ìpínlẹ̀ tó kù láti ẹ̀yin wá, oré ọ̀fẹ́ Ọlọ́run si ni ìjọba fí n gbéra, nítori náà kò sí ǹkan tó lé ṣẹ̀lẹ̀ tí ẹ̀rù yóò bá ìpińlẹ̀ Osun.













