Chibok Girls: Kà nípa àwọn ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ míràn tó wáyé ní Nàìjíríà lẹ́yìn ti Chibok

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ti pe ọdun meje bayi ti ijinigbe awọn akẹkọbinrin ile iwe girama Chibok ni ipinlẹ Borno ti waye.
Ọjọ naa ree bi ana loju awọn ti ko padanu ọmọ, ṣugbọn lọdọ awọn obi ati mọlẹbi awọn to ọmọ to dawati, ibanujẹ ojojumọ ni wọn n ba sun, ba ji.
Bo tilẹ jẹ wi pe pupọ ninu awọn akẹkọọ ọrinlenigbadinkan (279) ti wọn ji gbe, lo ti ribi sa mọ awọn ajinigbe lọwọ tabi ti ijọba doola wọn, amọ o si le ni ọgọrun akẹkọọ to wa ninu ide Boko Haram.
Ninu atẹjade kan ti Amnesty International fi sita lori ọrọ yii, wọn bẹnu atẹ lu ijọba Naijiria.
Wọn ni o ṣe ni laanu pe aimọye akẹkọọ Naijiria lo di awati nitori ijọba ko ri bi ojuṣe wọn lati daabo bo wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laarin oṣu Kejila ọdun 2020 si oṣu Kẹta ọdun 2021, wọn ti kede ijinigbe lawọn ileewe marun un to kere tan lẹkun ariwa Naijria.
Ifoya ijinigbe mii gẹgẹ bi Amnesty International ti ṣe sọ, ti mu ki wọn ti awọn ileewe bii ẹgbẹta miran pa lagbegbe ọhun.
Amnesty ni ko si ijiya fawọn ikọ Boko Haram to ji awọn ọmọ gbe, bẹẹ si ni awọn alaṣẹ kuna lọpọ igba lati daabo bo awọn ileẹkọ toun ti iṣẹlẹ ijinigbe nibẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀ẹ̀mẹrin ni ọ̀dá owó já mi kulẹ̀ lásìkò tí mo fẹ́ wọ Fáṣítì - Biola Adebayo
- "Ajínigbé ní tí a kò bá tètè sanwó, àwọn yóò gbé ọmọ mi sálọ, tí yóò sì kọ́ ìbọn yínyìn"
- Gani Adams yarí pé èdè Yorùbá gbọdọ̀ di ọ̀rànyàn nílé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀
- Báwo ní Nàíjíríà ṣe ná $30m fún ààbò akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yin ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ Chibok?
- Òjòóró ló wáyé lásìkò ìbò PDP l‘Osogbo - Fayose
- ''Ẹ gbà mí o, ọkọ mí ti lé mi nílé torí mo ya ‘tatoo’ Tinubu sára''
Lori ọrọ ijinigbe yii, a ni ki a ṣagbeyẹwo awọn ijinigbe akẹkọọ mii to waye lẹyin ti Chibok.
Awọn ijinigbe akẹkọọ to waye lẹyin ti Chibok:
Kankara
Nilu Kankara lawọn ajingbe ti jin akẹkọọ to le ni ọọdunrun gbe lọjọ Kọkanla oṣu Kejila ọdun 2020.
Awọn akẹkọkunrin wọn yi pada gba itusilẹ ṣugbọn wahala ati iporuru ọkan to ko ba awọn obi ati araalu kọja afẹnusọ.
Iṣẹlẹ yi mu ki awọn ijọba Kano, Zamfara,Jigawa ati Katsina gbe ilkun awọn ileewe ti pa ni kiakia.

Laarin awọn janduku ati ikọ Boko Haram, niṣe ni wọn n ṣe fakinfa pe awọn lawọn ji awọn akẹkọọ naa gbe.
Government Science Secondary School Kagara
Ipinlẹ Niger ni ileewe yi naa wa ni owurọ kutu lawọn ajinigbe si gbe awọn akẹkọọ nibẹ lọj Ktadinlogun oṣu Keji 2021.
Oṣu kan lẹyin iṣẹlẹ Kankara ni ti Kagara waye awọn agbebọn lo si ji awọn akẹkọọ yi gbe.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Governor Niger
Lọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Keji ni wọn gba itusilẹ.
Ileewe Kaduna lọjọ Kọkanla Oṣu Kẹta
Ileewe meji ni awọn agbebọn ṣe ikọlu si ni ipinlẹ Kaduna nibi ti Gomina Nasir El Rufai ti n ṣe akoso to fi mọ Federal College of Forestry Mechanization nibi ti wọn ti gbe akẹkọọ ọgbọn.
Ni ọjọ Kọkanla oṣu Kẹta ni wọn ji wọn gbe.Ibi ti wọn ti ji wọn ko si jina si ileeṣẹ awọn ọmọogun Naijiria.

Kete tawọn ajinigbe yi gbe awọn akẹkọọ naa ni wn fi fọnran fidio sita nibi ti wọn ti n fi iya jẹ awọn akẹkọọ naa.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ, nkan bi mẹtala awọn akẹkọọ yi lo ti ribi gba itusilẹ tawọn iyoku si yi wa ni ahamọ.
- Toyosi Adesanya yarí lórí ọ̀rọ̀ Foluke Daramola
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Nǹkan ṣe mí! Mo jẹ àmàlà àti Fúrá papọ̀ láti sọ Yorùbá àtí Fulaní di ọ̀kan - Shehu Sani
- Obìnrin ẹlẹ́sẹ̀ kan tó ń kirí omi rí àánú gbà lọ́wọ́ ìjọba Eko
- Twitter gbé olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Áfíríkà lọ Ghana, ọmọ Nàíjíríà yarí
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa ọmọ Ronke Oshodi Oke
Awọn eyi ti a kọ yi nikan kọ lo ṣẹlẹ ṣugbọn eyi taa ye gba wa lati kọ ree.
Titi di baa ṣe n kọ iroyin yi, awọn akẹkọọ Chibok to ku si wa ni ahamọ.














