Fídíò yìí ṣàfihàn àwọn ọlọ́pàá nibi tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́
Ọkan lára àwọn àdarí ẹgbẹ́ tó ń jà fún dídápadà àwọn ọmọbìnrin Chibok tí Boko Haram gbé lọ (BBOG), Aisha Yesufu, ti ṣe àfihan àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin níbi tí wọ́n ti ń ta tẹ́tẹ́ lẹ́nu ìṣẹ́.
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin náà wà nínú àwọn tí wọ́n fi sí Unity Fountain, láti máa kápá àwọn ẹgbẹ́ BBOG tí ó fi ẹ̀hónú hàn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Yesufu ṣàlàyé bí ìwà àwọn ọlọ́pàá ṣe ba oun nínú jẹ́ nítorí pé, iṣẹ́ kò ká wọn lára pẹ̀lú gbogbo wàhálà tó wà lorilẹ̀ede Naijiria, tí àwọn ọlọ́pàá náà lè lọ kojú rẹ̀.