Òní ni àyàjọ́ ọjọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀bìnrin Chibok sọnù

Ẹgbẹ BBOG

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ BBOG se àyàjọ́ ọjọ́ tí àwọn akẹ́kọ̀bìnrin Chibok sọnù
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹrin, ọdun 2014, nileewe girama awọn obinrin ni ilu Chibok, nipinlẹ Borno, awọn akẹkọbinrin kan nṣe idanwo aṣekagba girama wọn lọwọ pẹlu ireti pe esi idanwo ayọ ni adura to ku fun wọn lẹyin eyi.

Boya ni wọn mọ wi pe adura wọn lẹyin ọjọ yii yoo kọja esi ayọ bikoṣe itusilẹ wọn kuro ninu ahamọ nitori ṣa dede ni awọn agbebọn kan lati ikọ boko haram ya wọ ileewe wọn ti wọn si ko awọn akẹkọbinrin ọrinlelugba o din mẹrin lọ.

Okiki kan nigba naa kakiri agbaye lori bi ijọba to wa lode lorilẹede Naijiria lasiko naa ṣe kuna lati daabo bo awọn akẹkọ naa.

Awọn ikọ BBOG n ṣe ipade

Oríṣun àwòrán, @obyezeks

Àkọlé àwòrán, Nilu Abuja, idanilẹkọ yoo waye eleyi ti Pasitọ Tunde bakare yoo ṣe

Ọjọ abamẹta ni yoo pe ọdun kẹrin ti awọn agbebọn Boko Haram ji awọn akẹkọbinrin naa gbe, mejilelọgọfa wọn lo ṣi wa laharamọ awọn agbebọn yii.

Ọkan o jọkan eto ni ajọ to n lewaju ipe fun itusilẹ awọn akẹkọbinrin yii ti la kalẹ bayii.

Ọkunrin kan de ẹnu rẹ pẹlu iwe pelebe BBOG

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ni amẹrika, ipade adura yoo waye fun idapada awọn ọmọ naa

Lati naijiria si ilu ọba titi de orilẹede Amẹrika ni iwọde ati eto yoo ti waye lati tubọ tẹnumọ itusilẹ awọn ọmọ yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni amẹrika, ipade adura yoo waye ni ijọ Society for Advancement of Judaism lẹyin ti adura jumaat ti waye lọjọ ẹti ni ibudo ẹsin islam to wa ni ilu New York.

Nilu Abuja, idanilẹkọ yoo waye eleyi ti Pasitọ Tunde bakare yoo ṣe.

Awọn ilumọọka gbe iwe BBOG dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Okiki kan nigba naa kakiri agbaye lori bi ijọba to wa lode lorilẹede Naijiria lasiko naa ṣe kuna lati daabo bo awọn akẹkọ naa

Ninu ọrọ to fi sita lori ikanni twitter rẹ, aṣiwaju ikọ to n pe fun itusilẹ awọn akẹkọ naa, BBOG, Ọmọwe Oby Ezekwesili ni 'awọn ti ṣeleri pe ko ni si idaduro ni ipe awọn titi di igba ti ijọba apapọ yoo ko awọn ọmọ naa pada. Eyi lo si mu wa duro ṣinṣin di oni"

Aisha Yesufu ni tirẹ ni, "Fun ọdun mẹrin, awọn ọmọbinrin mejilelaadọfa wa ni ahamọ. Itiju nla niyi fun ijọba. Leah Sharibu ti lo ọjọ mejilelaadọta ni ahamọ, ki ni a n beere fun?"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: