Oluwo ni mo mọ̀, n kò mọ orukọ oye míràn -Ọọ̀ni

Olúwó àti Ọọ̀ni ilé ifẹ̀

Oríṣun àwòrán, OLUWO ILU IWO

Àkọlé àwòrán, Ọ̀pọ̀ ìròyìn ló ti kàn káàkiri ṣáájú àsìkò yìí pé àárín Olúwó àti Ọọ̀ni ilé ifẹ̀ kò gún

Ọọ̀ni ilé ifẹ̀,Oba Adeyeye Ogunwusi Ọ̀jájá kejì ti sọ pé Olúwó ni òhun mọ Olúwó ti ìlú Iwò sí kìí ṣe orúkọ mìíràn.

Ọọ̀ni Adeyeye Ogunwusi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé lọ́balọ́ba nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun tó wáyé ní ààfin Odùduwà ní ìlú Ilé ifẹ̀.

Bí a kò bá ní gbàgbé, láìpẹ́ yìí ni awuyewuye sọ nigba ti Olúwó ni Emir ni orùkọ oyè tí òun fẹ́ máa lo.

"Mo mọ arákùnrin mi gẹ́gẹ́ bíi Olúwó. Mi ò fẹ́ tẹ́tí sí àhesọ kankan."

Àwọn lọ́balọ́ba pẹ̀lú Ọọ̀ni ilé ifẹ̀

Oríṣun àwòrán, OLUWO ILU IWO

Àkọlé àwòrán, Àkọ́kọ́ ìpàdé tí Olúwó ti ìlú Iwò Oba Abdulrasheed Akanbi yóò bá àwọn lọ́balọ́ba ṣe lati ìgbà tó ti gun orí oyé ni ọdún 2015.

Bákan náà ni àwọn ọba alayé méjèèjì ilẹ̀ Yorùbá náà, Ọọ̀ni ilé ifẹ̀, Oba Adeyeye Ogunwusi Ọ̀jájá kejì àti Olúwó ti ìlú Iwò Oba Abdulrasheed Akanbi ní kò sí dúkùú kankan mọ́ làárín awọn.

Ọ̀pọ̀ ìròyìn ló ti kàn káàkiri ṣáájú àsìkò yìí pé àárín àwọn ọba alayé méjèèjì ilẹ̀ Yorùbá yìí kò gún, ṣùgbọ́n níbi ìpàdé náà, wọ́n ní kò sí ohun tó jọọ́.

Ìpàdé náà la gbọ́ pé ó jẹ́ àkọ́kọ́ tí Olúwó ti ìlú Iwò, Oba Abdulrasheed Akanbi, yóò báwọn ṣe lati ìgbà tó ti gun orí oyé ni ọdún 2015.

OLUWO ILU IWO

Oríṣun àwòrán, OLUWO ILU IWO

Àkọlé àwòrán, Olúwó ní àlááfíà wa láàárín àwọn ọba alaye ní ilẹ̀ Yorùbá

Ohun ti a gbọ ni wí pé awọn ọba alaye kan lo lọ pẹ̀tù si Olúwó ti ìlú Iwò Oba Abdulrasheed Akanbi lẹyin ipade ti wọn ṣe gbẹ̀yìn ni oṣu keje ọdun 2017.

"Mo kí arakùnrin mi, Olúwó ti ìlú Iwò dáadáa, gẹ́gẹ́ bí èyí ṣe jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ ní ààfin mi. kò sí ẹni to ni kí o máà wá síbí. Ilé rẹ nìyí."

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Olúwó ti ìlú Iwò Oba Abdulrasheed Akanbi ní àlááfíà wa láàárín àwọn ọba alaye ní ìpínlẹ̀ naa.

gbagede aafin ooni ile ife

Oríṣun àwòrán, facebook/Ooni ile ife

Àkọlé àwòrán, Awuyewuye sọ nigba ti Olúwó ni Emir ni orùkọ oyè tí òun fẹ́ máa lo

Bákan náà ni, Kábíyèsí Ọọ̀ni ilé ifẹ̀,Oba Adeyeye Ogunwusi Ọ̀jájá kẹ́ta tun yànnàná pataki iṣọ̀kan laarin àwọn lọ́balọ́ba ní ilẹ̀ Yorùbá.

"Gẹ́gẹ́ bímo ṣe máa ń sọ, èmi ni olùṣọ́ fún àwa tó kù. Ìṣọ̀kan Yoruba lo yẹ ki a máa lé bayii. Gbogbo wa ló sì yẹ ko maa huwa bi o ti tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ilẹ̀ Yoruba. A ní lati dúró gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣoṣo.

Bí ìṣọ̀kan yoo ṣe dé ilẹ̀ Yorùbá ati ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun ni a ń wá."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Imam Fuad tako Oluwo lori wiwe lawani