UEFA: Real Madrid yóò kojú Bayern, Arsenal àti Athletico yóò wáákò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn alaṣẹ ajọ ere bọọlu ilẹ Yuroopu, UEFA ti gbe ilana ifẹsẹwọnsẹ ipele to kangun si aṣekagba jade. Ni idije rẹ mejeeji.
Idije Champions league
Ninu eto ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi sita fun idije UEFA Champions league, ẹgbẹ agbabọọlu Bayern Munich ti orilẹede Germany ati Real Madrid ti orilẹede Spain ni yoo maa waako nigbati Liverpool ti ilẹ Gẹẹsi yoo maa kojú Roma lati orilẹede Italy.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ kayefi lo wáyé ni ipele to ṣaaju eyi to kangun si aṣekagba pẹlu bi esi ti awọn eeyan ko nireti ṣe n jade.
Bayern Munich gbẹyẹ mọ Sevilla lọwọ ti ori si ko Real Madrid yọ ki wọn to ri Juventus bì ṣubu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ kò rí bẹẹ fun Barcelona lasiko ti wọn gbe goolu mẹrin si ọkan lọ ka Roma mọle nitori gbogbo rẹ ni Roma da pada ti wọn si ja Messi atawọn akẹgbẹ rẹ ju silẹ.
Liverpool fi agba han Manchester city ninu ifẹsẹwọnsẹ mejeeji tí wọn gba lati tẹsiwaju si ipele yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ kẹrinlelogun ati ikarundinlọgbọn oṣu kẹrin ni ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ni ipele yii yoo waye.
Idije ife ẹyẹ UEFA
Ikọ agbabọọlu Arsenal ti ilẹ Gẹẹsi yoo maa fi ìwo lu ìwo pẹlu Athletico Madrid ti orilẹede Spain.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Marseile lati orilẹede France yoo si maa koju Salzburg ti orilẹede Austria.
CSKA Mosco ni Arsenal na pẹlu apapọ ayo mẹfa si mẹta, ti Athletico si gbo ewuro si oju Sporting Lisbon lati orilẹede Portugal pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan ṣoṣo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Marseile fi ajulọ han RB Leipzig ti RB Salzburg pẹlu yọ ọwọ kilanko Lazio lawo idije ife ẹyẹ UEFA naa.
Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye.












