Commonwealth: Eléré ìdárayá Cameroon mẹ́jọ di àwátì

Bọ́ọ̀lù kan níwájú àmì ìdánimọ̀ ìdíje Commonwealth tó ń lọ lọ́wọ́ ni Gold coast, lórílẹ̀ede Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eléré ìdárayá mẹ́jọ láti Cameroon sálọ ní Australia

Orílẹ̀èdè Cameroon ti kéde pé, mẹ́jọ nínú àwọn eléré ìdárayá orílẹ̀èdè náà, tó lọ sí ìdíje Commonwealth tó ń lọ lọ́wọ́ ni Gold coast, lórílẹ̀ede Australia, ni wọ́n ti di àwátì báyìí.Àtẹ̀jáde tí wọ́n fi síta fihàn wí pé, ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn eléré ìdárayá mẹ́rìnlélógún tí wọ́n kó lọ sí ìdíje ọ̀hún, làwọn èèyàn yìí jẹ́.

Àwọn alákóso ikọ̀ Cameroon sí ibi ìdíje Commonwealth náà, ti fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún tó àwọn agbófínró orílẹ̀èdè Australia létí.

Àwọn eléré ìdárayá tí orílẹ̀-èdè cameroon ń kópa ní ètò ìrìn ẹ̀yẹ níbi ìṣíde Commonwealth

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn eléré ìdárayá tí orílẹ̀-èdè Cameroon kó lọ sí ìdíje Commonwealth ló ti sálọ

"Ìpín mẹ́ta ni àwọ́n eléré ìdárayá tó sálọ náà pín sí. Ní òru ọjọ́ kẹ̀jọ ni àwọn mẹ́ta kọ́kọ́ sálọ kúrò ní ibùdó tí wọ́n fi àwọn eléré ìdárayá wọ̀ sí.Àwọn méjì míràn tún sálọ, kí àwọn mẹ́ta míràn tó tún di àwaátì lálẹ́ àná."Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mẹ́fà nínú wọn kópa nínú àwọn ìdíje kan kí wọ́n tó júbà ehoro, méjì nínú wọn kò tilẹ̀ kópa rárá.