Abiola Ajimobi: PDP ti fèsì padà fún Muideen Bello pé owó ló máa ń sọ bí wáàsí rẹ yóò ṣe rí

Sheikh Muhydeen Ajani Bello ati Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Sheikh Muhydeen Ajani Bello/Seyi Makinde Facebook

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ti ṣapejuwe ọrọ ti Sheik Muyideen Bello sọ nipa ijọba PDP ipinlẹ Oyo labẹ Gomina Seyi Makinde, gẹgẹ bi ọrọ to kudiẹ kaato.

PDP sọ ninu atẹjade to fi sita pe, gbogbo ọrọ ti Sheik Bello sọ tako ijọba Makinde lo tako ilana ẹsin islam ati awẹ Ramadan to n lọ lọwọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oselu naa ni gbogbo ohun ti Sheik Bello sọ ni ko wa ni ibamu pẹlu ipese ohun eelo amayedẹru ti ijọba Makinde ti pese fun araalu nipinlẹ Oyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

PDP ni Sheik Bello kuna lati sọrọ soke nipa wahala awọn ẹlẹgbẹ okunkun One Million Boys ni ipinlẹ Oyo ati bi awọn agbalagba to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ, ṣe n to lati gba owo ifẹhinti wọn labẹ ijọba APC to wa lori oye ki PDP to gba ijọba.

Sheikh Muhydeen Ajani Bello

Oríṣun àwòrán, Sheikh Muhydeen Ajani Bello/Facebook

PDP sọ ninu atẹjade naa pe oju aye ni Sheik Bello n ṣe nibi waasi iranti Gomina Abiola Ajimobi to ti sọrọ tako PDP, wọn ni o n sọrọ lati tẹ awọn to pe sibi waasi naa lọrun ni.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn eeyan ipinlẹ Oyo ko ba fẹ lati gbọ ọrọ Ọlọrun ti yoo ṣe wọn lanfaani ju bi Sheik naa ti tabuku ijọba PDP to wa lode bayii lọ.

PDP ni awọn eeyan ti Sheik Bello n tabuku ijọba Gomina Makinde loju wọn naa lo dibo fún PDP ti wọn si le APC lọ.

Àkọlé fídíò, Slain Ekiti Police woman: Ìyá rẹ̀ ní àìrìṣẹ́ṣe ló mú kí Bukola Olawoye gba iṣẹ́ ọlọ́pàá

PDP sọ pe waasi to niiṣe pẹlu ifẹ, alaafia ati otitọ lo yẹ ki Sheik Bello maa ṣe lati tu awọn eeyan ninu nitori ohun ti wọn n la kọja lọwọ lorilẹede Naijiria.

Ẹgbẹ naa ni oju awọn ọmọ Naijiria ti ri to pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhe lati igba ti ẹgbẹ oṣelu APC ti bẹrẹ sí ni tukọ orilẹ-ede Naijiria.

Amin iyasọtọ kan

Ajimobi kú, ìdàgbàsókè dúró, ojú kan nípìnlẹ̀ Ọyọ wà - Sheikh Bello

Abiola Ajimobi ati Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ijọba ipinlẹ Oyo ti ke si onimọ nipa ẹsin Islam kan, Sheik Muideen Bello lati gbe agbada oselu wọ, to ba nifẹ lati se oselu, dipo ko maa da asọ ẹsin boju kiri lati se oselu.

Akọwe gomina ipinlẹ Oyo feto iroyin, Taiwo Adisa lo fesi pada bẹẹ fun onimọ ẹsin naa lori esi to fọ pe ko si idagbasoke kankan nipinlẹ Oyo.

Sheik Bello lo kede nibi waasi awẹ Ramadan ọlọdọọdun ti wọn fi n se iranti oloogbe Abiola Ajimobi pe, ni kete ti gomina ana naa ti kuro nipo, ni eto idagbasoke ti duro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Waasi ọlọdọọdun naa, akọkọ iru rẹ, lo waye ni mọsalasi Ajimobi, Oke Ado Ibadan nibi ti ọpọlọpọ awọn ọrẹ ati ojulumọ Abiola Ajimobi, to di oloogbe lọdun to kọja, lo wa nibi idanilẹkọọ naa.

Sheikh naa to gbe waasi rẹ kalẹ lori pe ko si nkan ti ko ni èrè lọdọ Allah, sọ pe, ko si nkan aritọkasi kankan ninu isejọba to wa nipinlẹ Ọyọ lọwọ lọwọ.

Nigba to n fi ipaya rẹ han lori eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ Oyo, Bello sọ pe ko ti i si ayipada kankan nilu Ibadan. O ni "a ko le rin bo ṣe wu wa mọ".

O ni, o yẹ ki awọn eeyan bẹru Ọlọhun, ki wọn o si gbọran si awọn Wòlíì lẹnu.

"Mo n sọ fun yin pe nkan ti a ba ṣe ni àwọn eeyan yoo sọ. Ogún rere ni Ajimobi fi silẹ. "

O ni ipele pé 'wọn ṣi n gbaradi ni wọn wa, a ti pada si ipele igbaradi. A ko le gbagbe Lam Adesina àti Abiola Ajimobi (àwọn mejeeji to ti di oloogbe bayii).

Seyi Makinde Facebook

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Afọju gan mọ pe ilọsiwaju ti ba ipinlẹ Oyo lati ọwọ Seyi Makinde:

Amọ nigba to n fun Bello lesi ọrọ yii, Adisa ni onimọ ẹsin Islam naa kii se olugbe ipinlẹ Oyo, nitori naa, ko le mọ nipa aseyọri gidi ti gomina Makinde ti se lori aleefa.

"Afọju gan mọ pe aseyọri wa nipinlẹ Oyo lati ọwọ gomina Seyi Makinde, ti ajọ to n se odiwọn akọsilẹ nipa ọrọ aje Naijiria, NBS naa si fidi eyi mulẹ.

"Ida mẹrindinlọgbọn ninu ọgọrun ni ajọ NBS fi kede pe idagbasoke ati ọrọ aje ipinlẹ Oyo ru gọgọ si lasiko ijọba Seyi Makinde.

Awa sa kọ ni ajọ NBS wa labẹ rẹ, abẹ ijọba apapọ ni, nitori naa ohun ti Sheik Bello sọ ko ni itumọ."

Ara oju ọna ti ijọba Makinde n se lọwọ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Bakan naa ni Adisa tẹsiwaju pe ijọba Seyi Makinde n tun ohun to ti bajẹ, to ba nilẹ se ni amọ ko maa pariwo kiri pe nnkan ti bajẹ.

O wa tọkasi oju ọna Moniya si Ilu Iseyin, ti ijọba Makinde sẹsẹ se, to si n bi Bello leere pe se ko gba ibẹ kọja lẹnu lọọlọ yii ni lati mọ ni agbega to ba ọna naa.

"Wakati mẹrin ni wọn fi n rin lati Ibadan lọ si Iseyin tẹlẹ ki Makinde to gori aleefa, amọ nibayii, isẹju marundinlaadọta pe ni wọn fi n rin ọna naa bayii.

Oju ọna Onipepeye ati Akobo naa wa nibẹ, ti ijọba Seyi Makinde ti pari rẹ, to si ti dun rin."

Àkọlé fídíò, Egbejila Fish Village: Àwọn ọlọ́sìn ẹja ní àwọn fi iṣẹ́ báńkì sílẹ̀ wá ṣe ọ̀sìn ẹja ni

Akọwe gomina Makinde feto iroyin tun salaye pe lara awọn agbasẹse ti Ajimobi gbe isẹ fun, amọ ti ko sisẹ naa lo si jẹ ijọba ipinlẹ Oyo ni owo bii irinwo biliọnu naira.

Adisa wa n gba Muideen Bello nimọran lati gbe agbada oselu wọ, ko si ye fi ẹsin boju, lati maa se oselu.

Amin iyasọtọ kan

Okorocha bọ́ sí gbaga EFCC lẹ́yin ọjọ́ díẹ̀ tó gba àmì ẹ̀yẹ n'Ibadan

Olubadan n fun Rochas Okorocha ni ami ẹyẹ́

Oríṣun àwòrán, CCII

Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade kaakiri ori ayelujara pe gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, Rochas Okorocha ti wa ni akata ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC nilu Abuja.

Ọọfisi rẹ to wa nilu Abuja ni EFCC ti nawọ mu Okorocha lori ẹsun pe o n gbe owo tuulu lọ soke okun, tawọn iroyin kan si ni wọn ti fi si ahamọ.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwujaren fidi iroyin naa mulẹ pe awọn osisẹ ajọ naa ti gbe Okorocha.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba toun naa n fidi isẹlẹ yii mulẹ, Oludamọran pataki fun Senetọ Okorocha, Sam Onwuemeodo, sọ pe ko si nkan to buru ninu bi ajọ EFCC se pe Okorocha si ọọfisi wọn.

Rochas Okorocha n juwọ si awọn eeyan lati inu ọkọ

Oríṣun àwòrán, CCII

Ọgbẹni Onwuemeodo ṣalaye pe lẹyin ti Rochas fi ipo gomina ipinlẹ Imo silẹ ni ọdun 2019, ni ijọba ipinlẹ naa kọ iwe ẹsun nipa rẹ si ajọ EFCC.

O ni "EFCC ṣe iwadii lori ayelujara awọn ẹsun naa, o si ti gbe ọrọ lọ si oriṣiriṣi ile ẹjọ ni Naijiria.

" Ti EFCC ba wa a ránṣẹ pe Okorocha fun awọn àlàyé lori awọn ọrọ to wa nile ẹjọ, ko si nkan to buru nibẹ, paapaa bi ajọ naa ṣe ṣẹṣẹ ni Alaga tuntun. "

O ni isẹ ajọ naa lo n ṣe, ati pe Okorocha yoo ma a fọwọsowọpọ pẹlu rẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere.

Àkọlé fídíò, Egbejila Fish Village: Àwọn ọlọ́sìn ẹja ní àwọn fi iṣẹ́ báńkì sílẹ̀ wá ṣe ọ̀sìn ẹja ni

"Igba akọkọ kọ re e ti EFCC yoo ránṣẹ pe e. Wọn n pe e, o si da wọn lohun."

Àmọ́ ṣa, ó ni awọn yoo ma a wo boya ajọ EFCC yoo jawọ ninu awọn ẹjọ naa, tabi yoo tẹsiwaju pẹlu wọn nile ẹjọ.