Yomi Fabiyi Vs TAMPAN: Òfin tẹ ṣe kò nímọtù, ń kò gba fọ́ọ̀mù yín tẹ́lẹ̀

Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Realyomifabiyi/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Yomi Fabiyi, tii se gbajumọ osere tiata ti ẹgbẹ TAMPAN kede pe awọn ti ni ko lọ rọọkun nile nitori fiimu Oko Iyabo to se, ti fesi pada.

Yomi, ẹni to gbe ikede kan sita loju opo Instagram rẹ lori asẹ ti TAMPAN se pe ko yẹba diẹ na ninu ẹgbẹ naa, ti wa ni igbesẹ naa ko tu irun kankan lara oun.

Osere tiata naa ni ọmọ ẹgbẹ ANTP kuku ni oun nibẹrẹ pẹpẹ, to ba si buru tan, oun yoo pada si inu ẹgbẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Bi ila ko ba se e gbe, a maa n gbe Ilala. Ẹni to sọ mi nu, lo sọ nnkan gidi nu, ẹni to ri mi he, lo ri nnkan gidi he."

Yomi Fabiyi ni oun ko kuku gba fọọmu tabi fi ọwọ si lati di ọmọ ẹgbẹ TAMPAN tabi dara pọ mọ ẹgbẹ awọn oludari ere.

Ọrọ ti Yomi Fabiyi sọ

Oríṣun àwòrán, Realyomifabiyi/Instagram

"Wọn kan ni ki n wa sanwo iforukọsilẹ ni, mo si se bẹẹ amọ n ko fọwọ si iwe kankan lati di ọmọ ẹgbẹ.

Iwe ti ẹ kọ si mi ko tọna rara, ko nitumọ si mi gẹgẹ bi ẹni to n gbe sinima jade.

Ti maa ba tiẹ sọrọ rara, yoo da lori titẹ ẹtọ ọmọniyan loju, ti mo ba si fẹ gbe yin lọ sile ẹjọ, ohun ti eyi yoo da lori ree."

Yomi Fabiyi wa pari ọrọ rẹ pe eeyan kii padanu ohun ti ko ba ni lati ilẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post