Iyabo Ojo: Èmi kí yóò kú ikú kíkú kán nítorí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, Yomi Fabiyi

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Insatagram

Oṣerebinrin Iyabo Ojo ti kesi awọn to n ro ibi ro oun wi pe gbogbo wọn ni wọn yoo ba Ọlọrun oun nibẹ.

Iyabo Ọjọ sọ bẹẹ ninu atẹjade to kọ si oju opo ikansiraẹni Instagram, lẹyin ti o fi fidio lede nibi ti baba kan to gbe aṣọ iṣẹmbaye sọrun.

Ninu fidio ọhun ni baba agbalagba naa to dabi babalawo ti n sọrọ kubakugbe si Iyabo Ojo, to si ro iku si.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ má jẹ́ kí òkú ọmọ mi ráre o ìjọba! Ẹ gbée fún mi kí n lọ sin ín - Ìyá ọmọ ti wọ́n pa ní ìwọ́de Yoruba Nation

Amọ Iyabo Ojo ninu atẹjade ni oju opo rẹ sọ wi pe ibẹru kankan ko si fun ọmọ Ọlọrun, a ti pe ẹni to ba ro iku ro oun, ni yoo fi ori ara rẹ gbe.

''Baba Ijesha, Yomi Fabiyi ati gbogbo ẹni buruku ati awọn obinrin to n ṣe atilẹyin fun awọn ẹni ibi, ko fẹ ki ẹ mọ wi pe igbiyanju yin lori aye mi yoo jasi asan, ẹ kan n daamu ara yin lasan ni o.''

''Ẹ kiyesi o, Ọlọrun nkan lo ni agbara lati gba ẹmi ẹnikẹni ni igba ati asiko to ba yẹ''

''Ọlọrun nikan ni yoo gba gbogbo ogo lori aye mi, titi di igba naa, asan lori asan ni igbiyanju yin.''

''Bi o le bẹru eniyan laye, ti ko si si ẹni to le dami duro lati s otitọ ni igba gbogbo.''

''Bakan naa ẹ ma gbagbẹ, ẹni to ba ni Ọlọrun, o ni ohun gbogbo.''

''Mi o bẹru iku nitori gbogbo wa ni yoo lọ, amọ asiko Ọlọrun nikan lo ṣe koko.''