Multichoice: Ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé àpò àṣùwọn iléeṣẹ́ DSTV àti GO TV torí owó orí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ ti gbegi dina apo asunwọn owo ileesẹ Multichoice, to n gbe mohunmaworan DSTV ati GO Tv sita.
Alaye ijọba apapọ ni pe ileesẹ Multichoice n sa fun owo ori sisan, to si tun n lu awọn onibara rẹ ni jibiti.
Ileesẹ to n pawo wọle labẹle labẹ ijọba apapọ FIRS ni owo to to biliọnu mẹrin aabọ Dọla ni ileesẹ South Africa naa jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- Wo bí ètò ìsìnkú TB Joshua ṣe n wáyé ní ìlú abínibí rẹ̀
- Irọ́ pátápátá ni pé mo gba 50milion nairà látí ṣe alátakò Sunday Igboho - Olubadan
- Ìdí rèé tí àwa lọ́balọ́ba fi dákẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù Sunday Igboho - Oluwo tí Iwo
- Àmúṣẹ Yoruba Nation wà lára ǹkan tó gbé mi lọ síbi ìsìnkú T.B Joshua
- 'Ẹ má sọ pé lọ́balọ́ba kó sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù Sunday Igboho, Inú wa kò dún sí ìjọba'
- A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ba orúkọ mi jẹ́ tórí sabuké NYSC mi, mò ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò - Kemi Adeosu
Bakan naa ni ajọ FIRS tun na ika aleebu si ileesẹ naa pe o kuna lati dahun si awọn ibeere ti ajọ naa n bi i.
FIRS ni bi o tilẹ jẹ pe ida ọgbọn ninu ere ti ileesẹ Multichoice n jẹ lo n wa lati orilẹede Naijiria.
Gẹgẹ bi alaga ileesẹ FIRS, Muhammed Nami ti wi, sibẹ ileesẹ Multichoice ko fi aaye gba awọn lati yẹ iwe owo ileesẹ naa wo
Amọ ileesẹ naa wa n salaye pe oun n tẹle ofin to de owo ori sisan ni Naijria, ti ifikunlukun si ti n lọ laarin rẹ ati ileesẹ FIRS lati yanju ọrọ naa nitunbi n nubi.
Nibayii, ileesẹ FIRS ti wa pasẹ fun awọn ile ifowopamọ lati seranwọ lati gba owo bii biliọnu mẹrin ati aabọ Dọla pada ninu Triliọnu kan ati aabọ naira ti ijọba jẹ wọn.
Ileesẹ Multichoice yii lo ni ileesẹ tẹlifisan DSTV ati GOTV to wa lori ayelujara.
Losu kẹfa ọdun 2020 ni awọn asofin lorilẹede Naijiria bẹrẹ iwadii nipa isọwọsisẹ ileesẹ naa lori bo se n gba owo ni osoosu lọwọ awọn onibara rẹ, boya wọn wo mohunmaworan naa tabi bẹẹ kọ.

















