Farouk Yahaya: A ti ń rán ọ̀pọ̀ ọ̀daràn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run láti lọ jẹ́jọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn - Ólórí iléèṣẹ́ ológun tuntun

Farouk Yahaya

Oríṣun àwòrán, The nation

Olori ileeṣẹ ologun Naijiria ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣẹṣẹ bura fun, Ọgagun Farouk Yahaya ti sọ pe awọn n tẹle aṣẹ ti aarẹ pa lati kọju ija si awọn ọdaran jakejado Naijiria.

Yahaya, lasiko to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ti Aarẹ Buhari bura fun tan nile ijọba nilu Abuja, sọ pe ọpọlọpọ agbebọn, agbesunmọmi, ati awọn ọdaran miran ni awọn ti "ran lọ si ọdọ Ọlọrun, lati lọ jẹjọ fun ẹṣẹ wọn".

Bakan naa lo jẹjẹ pe gbogbo otitọ ati ifọkansin oun yoo wa fun aarẹ, ati orilẹ-ede Naijiria.

O ni oun dupẹ lọwọ aarẹ fun igbẹkẹle to ni ninu oun, to fi yan oun si ipo.

O sọ pe "a ti n ṣe aṣeyọri lọpọlọpọ, ao si ma aṣe amulo awọn aṣeyọri naa pẹlu iriri wa lati ṣẹgun."

"Fun awọn agbebọn ati ọdaran to n fi oju tẹmbẹlu wo eto aabo Naijiria, a ti n tẹle aṣẹ ti aarẹ pa pe ka ba wọn sọrọ ni èdè ti wọn gbọ.

Nkan ti a si n ṣe niyii, debi pe a ti ran ọpọlọpọ wọn si ọdọ Ọlọrun, lati lọ jẹjọ fun ẹsẹ wọn.

"Ao si tẹsiwaju lati ma a ṣe bẹ ẹ."

Nigba ti oun naa n sọrọ, minisita fun eto aabo ni Naijiria, Ọgagun Bashir Magashi sọ pe olori ileeṣẹ ologun naa bẹrẹ iṣẹ rẹ daadaa.

"Ọpọlọpọ ayipada ti wa ninu ilana ti a n gba koju eto aabo, lati igba to ti de ipo. Gbogbo nkan n lọ deedee bo ṣe yẹ.

"O da mi loju pe ti a ba n lọ bayii, ko ni i pẹ ti ao fi jade kuro ninu iṣoro igbesunmọmi."

Ọgagun Magashi sọ pe ko si nkan to buru ninu bi aarẹ ṣe paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ alaabo ma a ba awọb ọdaran sọrọ ni èdè ti wọn gbọ.

"Ko ṣe e ṣe ki a fi aaye gba ọ lati wa laye, ti o ba ni nkan ijagun lọna ti ko ba ofin mu, nitori pe a le lo nkan ijagun naa lodi si ọ."