Jacob Zuma: Wo bí Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí yìí ṣe jọ̀wọ́ ara fún àwọn Ọlọ́pàá láti tì í mọ́lé

Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní wọ́n ju Zuma sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan àti oṣù mẹ́ta.
Ààrẹ South Africa tẹ́lẹ̀ Jacob Zuma ti lọ fa ara rẹ̀ lè ọlọ́pàá lọ́wọ́ leyin ti wọ́n dájọ́ oṣù mẹ́ẹ̀dógún fún nítorí ó deja sí ilé ẹjọ́.
Àwọn ọlọ́pàá náà sì ti mú lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Estcourt, èyí jẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ìlú rẹ ni ẹkùn KwaZulu-Natal lọ́jọ́ rú.
Àwọn ọlọ́pàá kilọ tẹ́lẹ̀ pé tí kò bá yọjú títí òru ọjọ́rú àwọn yóò wà mú fúnra àwọn.
Zuma, ẹni ọdún mọ́kandinlọ́gọ́rin ni ilé ẹjọ́ wọ́n ẹ̀wọ̀n fún lẹ́yìn to kọ̀ láti yọjú síbi ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kan.
Bí wọ́n ṣe ju Zuma sẹ́wọ́n tí dá onírúurú ẹjọ́ sílẹ̀ ni South Africa pàápàá jù lọ bí àwọn ọlọ́pàá ṣe fún ní gbedeke aago mọ́kanlá òru Ọjọ́rú láti fà ara rẹ̀ kalẹ̀.
Ilé ẹjọ́ lọ fún ní gbèdéke yìí lẹ́yìn tó kọ̀ láti fara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú.
Nínú àtẹ̀jáde kékeré kan ni ilé iṣẹ́ rẹ Jacob Zuma Foundation tí sọ pé, Jacob Zuma tí gba láti tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ àti pé òun yóò fà ara òun lè àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n lowo
Ọmọ rẹ̀ , Dudu Zuma-Sambudla, padà kọ sójú òpó Twitter rẹ pé bàbá òun wà lọ́nà ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣùgbọ́n kò sí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn fún òun.
Kò tíì ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn orileede South Africa pé ààrẹ to gbé ìjọba silẹ kankan lọ ẹ̀wọ̀n.
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹfà, ọdún 2021 ni wọ́n dájọ́ Zuma nítorí pé kò tẹ̀lé àṣẹ ilé ẹjọ́ pé kò mú ẹ̀rí lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ láàrin ọdún mẹsan tó fi jẹ ààrẹ.
Àwọn oníṣòwò pẹ̀lú ni wọ́n naka àléébù sì pe wọn ń pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóṣèlú láti pàṣẹ lórí lédè náà nígbà tí Zuma wá nípò, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà ni Zuma ń tẹnu mọ pé ọ̀tẹ̀ òṣèlú ni òun ń kọjú
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Rẹ African national Congress (ANC) gan lọ lè kúrò nípò lọ́dún 2018.
Àwọn ènìyàn ló dabo dòyí yí ilé rẹ ka gẹ́gẹ́ bí ọna láti má jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá mu lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kí ó tó lọ fa ara rẹ̀ sílẹ̀ ni Ọjọ́rú.















