Haiti President assasinated: Àwọn agbébọn pa Jovenel Moise nílé rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Àwọn agbébọn ti pa ààrẹ orílẹ̀-èdè Haiti ní ilé rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtù Ọjọ́rú gẹ́gẹ́ bí ìjọba ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè Haiti, Claude Joseph sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé àwọn agbébọn náà pa Jovenel Moise ni ilé rẹ tó wà ní Port-au-Prince ni ago kan òru àsìkò wọn.
Ìròyìn sọ pé ìyàwó olóògbé náà farapa nínú ìkọlù ọ̀hún.
Ààrẹ Haiti tí wọ́n tilẹ̀ pá nílé rẹ̀, ọ̀gá Joseph ni gbogbo ọ̀nà ni àwọn n gbà láti rí dájú pé ètò ìjọba yóò tẹ̀ síwájú.
- Hàà! Yomi wàá ṣẹ̀wọ̀n o! Oò ṣe bí ọlọ́pọlọ rárá, ò kàn ń fi àṣírí Baba Ijesha àti Iyabo Ojo gòkè ni - Femi Branch
- Àwọn ọmọ ìkókó níléèwòsàn kàgbákò agbébọn! Wọ́n jí wọn gbé pẹ̀lú nọ́ọ̀sì
- Ta a ló yìnbọn pa Jumoke, ọmọ ọdún 14 nítòsí ibi ìwọ́de Yoruba Nation ní Ojota?
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
Jovenel Moise, ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta gorí oyè nínú oṣù Kejì, ọdún 2017 lẹ́yìn tí ààrẹ ìgbà náà Michel Martelly fipò sílẹ̀.
Àsìkò Moïse kò fararọ rárá nítorí onírúurú ẹ̀sùn ni wọ́n fi kàn án láti orí ìwà àjẹbánú, ọ̀pọ̀ náà ló sì ń wọ́de ìfẹ̀hónúhàn lòdì sí àwọn ètò ìjọba.
Ṣáájú nínú ọdún yìí ni ìfẹ̀hónúhàn ní olúùlú Haiti ti wáyé tí ọ̀pọ̀ sì pè fún ìkọ̀wé fipò sílẹ̀ rẹ̀.
Àwọn ẹgbẹ́ alátakò orile-ede náà sọ pé sáà ọdún márùn-ún Moïse yẹ kí ó ti parí ni ọjọ́ keje, oṣù Kejì, ọdún 2021 níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Martelly kọ̀wé fipò sílẹ̀ ni.
Ọ̀gbẹ́ni Moïse tẹpẹlẹ mọ fún wọn òun kò bọ́ sípò títí di ọjọ́ keje, oṣù Kejì, ọdún 2017.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló na ìka àléébù si ètò ìdìbò, tí wọ́n sì padà wọ́gile àbájáde ìdìbò ọdún 2015.
Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún padà ṣe ètò ìdìbò mìíràn tó gbé Moïse wọlé.














