Yomi Fabiyi, Iyabo Ojo kọ́ ló ń wọ́ wálẹ̀ o, ara rẹ̀ gan lò ń wọ́ wálẹ̀ - Femi Branch

Yomi Fabiyi ati Femi Branch

Oríṣun àwòrán, Femi Branch, Yomi Fabiyi

Ọpọlọpọ oṣere ọkunrin lo kọ lati fọhun lori ọrọ fiimu "Oko Iyabo" ti Yomi Fabiyi ṣe sita eyi to da wahala silẹ lọwọlọwọ amọ bo ṣe ń gbe ọkan lara wọn ninu bi èébì, Femi Branch ti fibinu sọrọ.

O kọkọ ṣafiwe bi awọn akẹgbẹ wọn kan ṣe maa n fi anfani iṣoro ati ibanujẹ to jẹ ọrọ ọlọrọ fi di eeyan nla labẹ didibọn pe wọn n ṣeranwọ fun ẹni naa.

"Ko wu mi lati ṣe fidio yii tori mo mọ pe nkan to n ṣẹlẹ yii gan ni Yomi ti ọrọ yii kan fẹ tẹlẹ - lati fi ibanujẹ awọn eeyan ni igbesoke ko fi ta ọja ara rẹ faraye".

Ṣugbọn Femi Branch ni lootọ nigba toun gbọ pe o n peelo fiimu yii lọwọ oun ro pe yoo daa bi ọgbọn ni ko ma ta ba ẹnikẹni taara amọ o ni Yomi o fi ọpọlọpọ ṣee rara.

"Yomi mo ni lati sọ fun ẹ pe nigba ti mo ri gbogbo nkan to wa ninu fiimu Oko Iyabo yẹn, o ri mi lara gidi gan, Bo tilẹ jẹ pe mo mọ pe Iyabo Ojo lo fẹ fi bu, mo ro pe waa ṣi lo ọpọlọ ni ko ma lọ taara amọ o ba mi lojiji pe oo tilẹ ṣe ohunkohun to n mu iṣẹ da yatọ rara, asaan iṣẹ ti ko lọ́pọlọ gbaa lo ṣe jade".

Àkọlé fídíò, Ṣé o lè gbé orí rẹ lọ sọ́dọ̀ fárífárí alábẹ kó dán bí àwọn tó ní àwọn kò lè lo "clipper láéláé yìí?

Femi tun n fi Ọlọrun bura pe itiju nla ni Yomi jẹ si ẹgbẹ awọn to n ṣe sinima tori o ju ara rẹ silẹ gan ni. O ni Yomi kan n ro pe oun mọ iṣẹ ni amọ ko mọ nkankan rara.

"Mo kabamọ pe mo mọ ẹ, lootọ mo kọkọ gbe lẹyin rẹ ni ti pe o n ja fun ki wọn gba ẹtọ onikaluku laaye tori wọn ni ẹtọ lati sọrọ mo gba mo si ro pe waa daa lee nibẹ yẹ ni ṣugbọn o ri mi lara gidigidi lati lẹ sọ pe mo mọ ẹ ri".

O ni o ro pe Iyabo lo fẹ fa walẹ ni amọ ara rẹ (Yomi gangan lo n wọ walẹ). Femi ni ọrọ yii tun wa kan ọmọ ọlọmọ to jẹ ọmọde.

"Yomi, oo ma loju ti o, bi mi o ba mọ̀ pe iwọ funrarẹ bimọ ni mi o ba ma... ama boo tilẹ ṣe tun wa bimọ, ko tọ siẹ lati jẹ ẹni ti wọn npe ni baba".

O ni o ya oun lẹ́nu pe yomi le maa fi ilakọja ọmọ kekere ti ko mọ nkankan fi ma ta kaiti ninu fiimu. "O dẹ n ṣe fiimu yẹn bi nkan ṣe ri gangan, hàà Yomi waa ṣẹwọn o!".

O ni adajọ̀ ti baba sọ pe ki ẹnikẹni ma sọrọ m nipa rẹ amọ ọrọ yii gaan ni yomi tun wa ṣe sita si fiimu gẹlẹ bi wọn ṣe ni o ri.

Lo ba ni oun n fi ọrọ ranṣẹ si ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria lati fi ofin mu yomi Fabiyi tori ko ye oun nkan ti Yomi gbojule ti ko fi mọ pe oun ti ru ofin ti yoo kan maa ṣe nkan bii pe o le muu jẹ.

O ni ṣe awọn agbẹjọro rẹ o ri akọsilẹ fiimu rẹ ki wọn si gba a nimọran lorii rẹ lori fiimu ailọpọlọ yii.

"O ṣẹṣẹ ko panpẹ si ara rẹ lọwọ ni, inu mi dun si ohun ti o ṣe gan".