7/7 Cultism Day: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá fi ìkìlọ̀ síta nítorí àyájọ́ 7/7 táwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Aiye fẹ́ ṣe

Aworan eto igbani wọle sẹgbẹ okunkun
Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ọna ni eto igbani wọle maa n gba ninu awọn ẹgbẹ okunkun

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kilọ fawọn ẹlẹgbẹ okunkun lati ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, lori ayẹyẹ 7/7 ti wọn fẹ ṣe lọjọ keje oṣu keje ọdun 2021 yii.

Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko fi sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Muyiwa Adejobi, ni awọn agbofinro ti wa lojufo lati fi ọwọ ofin mu ẹnikẹni tó ba ṣe ayẹyẹ naa nipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹnikẹni ti wọn ba ko ara wọn jọ lati ṣe ayẹyẹ 7/7 yóò foju wina ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko wa kilọ fawọn ẹgbẹ okunkun Neo Black Movement of Africa, ti ọpọ mọ si Black Axe pe, ki wọn mase de ipinlẹ Eko lati ṣe ohun kohun nitori awọn ọlọpaa ko ni gba fún wọn.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu ti wa paṣẹ fawọn ọga ọlọ́pàá agbegbe lati maa kaakiri ipinlẹ Eko lati mu ẹnikẹni to ba n ṣe ayẹyẹ 7/7.

Àkọlé fídíò, Ṣé o lè gbé orí rẹ lọ sọ́dọ̀ fárífárí alábẹ kó dán bí àwọn tó ní àwọn kò lè lo "clipper láéláé yìí?

Odumosu wa rọ araalu at'awọn obi lati mojuto awọn ọmọ wọn kí wọn maa ba di ọmọ buruku to n darapọ mọ ẹgbẹ okunkun nitori ọlọpaa yoo fi ọwọ ofin mu wọn.

Amin iyasọtọ kan

Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kánkan tó bá dá aṣà àjọ̀dún July 7 yóò fojú winá òfin

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti fi ikede sita fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n gbero lati ṣe ayajọ ọjọ ẹgbẹ okunkun nilẹ naa.

Ọjọ yi ti wọn pe ni 7/7 ni ọlọpaa ni ọpọ ikọlu ati itajẹsilẹ ti maa n waye.

Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa fi sita lorukọ Kọmisana ọlọpaa, Olawale Olokode, wọn ni wamuwamu ni awọn wa lati rii pe iru nkan bẹẹ ko waye.

Ọlọpaa ni iroyin to tẹ awọn lọwọ ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii fẹ fi ayajọ yi da omi alaafia ilu ru ṣugbọn awọn ko ni gba fun wọn.

''Kọmisana ti paṣẹ pe ki gbogbo awọn ọga ọlọpaa ati awọn olori ikọ ọlọpaa duro ṣẹpẹ lati koju ẹnikẹni to ba fẹ da ilu ru''

Atẹjade naa tun sọ pe ki awọn obi ati alagbatọ fa ọmọ wọn leti lati yago fun apejo kankan yala ṣaaju lasiko tabi lẹyin ọjọ yi.

Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria
Àkọlé àwòrán, Àdá, àáké, ati fila pupa jẹ́ diẹ lara ami idanimọ awọn ẹgbẹ okunkun ni Naijiria

Wọn ni ẹnikẹni to ba kọ eti ikun si ikilọ yi yoo foju wina ofin.

Bẹẹ naa ni ikilọ yi de ọdọ awọn to ni ile itura ati aaye inaju pe ki wọn ma ṣe faaye gba awọn olubi lati lo ọdọ wọn fun iru apejọ to le da omi alaafia ilu ru.

Ipinlẹ Oṣun wa lara awọn ipinlẹ ti ẹgbẹ okunkun ti gbalẹ.

Lai pẹ yi ni a ka iroyin kan pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ṣa gẹrigẹri kan pa ni ṣọọbu rẹ ladugbo Oke-Ijetu Oshogo.

Koda alabara gẹrigẹri naa kan to wa nibẹ lasiko ikọlu yi faragbọgbẹ.