TB Joshua burial: Wọ́n ti sin òkú TB Joshua sí Synagogue! Wo bí ìsìnkú ṣe lọ

Oríṣun àwòrán, Tb joshua ministries
Wọn ti sin oku oludasilẹ ijọ Synagogue Church of All Nations, SCOAN, Wolii Temitope Balogun Joshua.
Ni nkan bi aago mẹta ọsan kọja iṣẹju diẹ ni wọn gbe ara rẹ sinu iboji.
Nibi eto isinku naa to waye ni inu ọgba ijọ rẹ to wa ni adugbo Ikotun nipinlẹ Eko lati ri gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ati aya Ooni Ile-Ife, Olori Naomi Silekunola Ogunwusi.

Oríṣun àwòrán, Tb joshua ministries
Ẹwẹ, kọmisanna fun ọrọ abẹle nipinlẹ Eko, Olanrewaju Elegushi lo ṣoju ijọba ipinlẹ Eko nibẹ.
Bakan naa ni Ọba Willard Mswati Gomani lati orilẹede Malawi naa wa.
Eto isin idagbere lo kọkọ waye ninu ṣọọṣi Synagogue, ko to o di pe wọn gbe oku rẹ lọ si ile ikẹhin ti wọn ṣe si abala kan ninu ṣọọṣi naa.
Nigba to n sọrọ nibi isin idagbere, Gomina Rotimi Akeredolu sọ fun awọn eniyan ilu Arigidi to jẹ ilu abinibi oloogbe, lati mase fi oju ọmọ ilu lasan wo o.

Oríṣun àwòrán, Tb joshua ministries
O ni lootọ ni wọn ko sin si ilu Arigidi, amọ eekan agbaye ni.
Bakan naa ni ojiṣẹ Ọlọrun kan to wa nibẹ, Bisọbu Steven Ogedengbe lati ipinlẹ Ondo sọ pe ko si pasitọ to ṣe iṣẹ àmì, to si tun le ẹmi eṣu jade bii TB Joshua.
Bi eto isinku Temitope Joshua ṣe lọ
Nibi isin idagbere to kọkọ waye ninu ṣọọṣi, Gomina Akeredolu lo ka ẹkọ Bibeli akọkọ.

Oríṣun àwòrán, TB joshua ministries/facebook
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ akọrin ile ijọba ipinlẹ Ondo kọ orin idaraya.
Awọn akọrin ati awọn agbaagba ijọ, to fi mọ awọn ọmọ oloogbe ati iya wọn, Evelyn, lo yi iboji naa ka nigba ti eto isinku n lọ lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Ó tó gẹ́, Sunday Igboho fẹ́ gbé ìjọba lọ ilé ẹjọ́ bí wọn kò bá tú àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
- "Gbàjarè! Àwọn èèyàn tí DSS kó nílé Sunday Igboho nílò ìtọ́jú kíámọ́sá"
- "Odeeshi"! Baba Ijesha, Yomi Fabiyi àti gbogbo àwọn tó fẹ́ pa mi, èèyàn lásán niyín o - Iyabo Ojo
Bakan naa, aṣọ funfun balau ati gele funfun ni awọn to kopa nibẹ wọ, ti awọn ẹgbẹ akọrin si fi ọja alawọ pọpu ati goolu kọ ọrun wọn.
Alawọ funfun paapaa ni posi ti wọn fi sin.
Iyawo ati awọn ọmọ oloogbe, to fi mọ gomina Akeredolu lo kọkọ bu iyẹpẹ si inu iboji naa, ti wọn si tun ju ododo sinu rẹ.
Lẹyin naa ni awọn akọrin ati awọn alakoso ijọ Synagogue to wa nibẹ.


















