Yomi Fabiyi; N kò lo àpètán orúkọ, ohùn tàbí àwòrán ẹnikẹ́ni nínú fíìmù Oko Iyabo

Yomi fabiyi

Oríṣun àwòrán, yomi fabiyi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ilumọọka osere tiata nni, Yomi Fabiyi, to n lewaju ninu awuyewuye to suyọ lori ẹsun asemase ti wọn fi kan Baba Ijesha, tun ti sọrọ sita.

Yomi, ẹni ti ọpọ eeyan n naka abuku si lori fiimu ọkọ Iyabo to se sita, tun ti gbe fidio miran sita pe ẹnikẹni to ba ro pe fiimu naa tako ẹtọ ọmọniyan le gba ile ẹjọ lọ.

Osere tiata naa ni oun ko ni da eebu pada fun ọpọ eeyan to n sọ oko ọrọ si oun lori agbejade sinima naa nitori o ni "kii se gbogbo aja to n gbo, ni eeyan maa n kọbi ara si."

"Inunibini ko kan ti aimọ iwa wu, nitori naa ni eeyan se gbọdọ gbajumọ ibi to n lọ.

To ba boju wẹyin, to si duro si idi otitọ, nigba to ba ya, wa jare nitori bi irọ ba lọ titi fun ogun ọdun, otitọ yoo le ba ni ọjọ kan.

Àkọlé fídíò, Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta

Ẹ lọ fa ila si idi ọrọ mi, ọjọ kan n bọ ti awọn to korira rẹ, bu ọrọ tabi sọ ọrọ abuku si ọ, yoo ri daju pe asise nla gbaa ni wọn se.

Yoo ye wọn pe aimọkan lo n da wọn laamu, ẹ yago fun loju opo ayelujara ati loju aye, ko dara rara."

Yomi Fabiyi ni ọpọ eeyan to n sọ oko ọrọ si oun lori fiimu Oko Iyabo ti oun gbe jade ni ko tii wo sinima naa rara, gbogbo eebu ati oko ọrọ ti wọn si n sọ ni wọn ko ni idi lati se bẹẹ.

Osere tiata naa ni gbogbo awọn eeyan to ti wo sinima naa lo n beere pe ki lo de ti ọpọ eeyan se n bu ẹnu atẹ lu sinima yii?

"Eeyan kan le lọ sile ẹjọ lati beere fun idajọ ododo ti wsn ba lo apetan orukọ rẹ ninu ere itage, ohun rẹ tabi aworan rẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Amọ ti onkọtan ati olootu ere ba ti le bọwọ fun awọn nnkan wọnyi, o yẹ ki ẹyin lee le bọwọ fun ninu esi tẹ ba n fọ sita nipa wọn.

Mo ti ya fiimu Oko Iyabo, ki ileẹjọ to kede ọjọ ti yoo maa gbọ ẹjọ Baba Ijesha, bẹẹ si ni itan naa yatọ patapata si ohun to sẹlẹ si Baba Ijesha."

Yomi Fabiyi ni gbogbo aye to wi wo sinima naa lo ri pe ko si ohun ti ko dara rara ninu sinima yii, tabi pe o n se agbega iwa sise asemase pẹlu ọmọde.

O wa pari ọrọ rẹ pe ẹnikẹni ti agbejade sinima naa ko ba dun mọ ninu, tabi pe o tẹ ẹtọ wọn mọlẹ, le gba ile ẹjọ lọ lati gba idajọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: