Sunday Igboho: Iléeṣẹ́ ológun ní ẹni tó bá lo jàgídíjàgan láti fẹ́ pín Naijiria yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun lorilẹede Naijiria, Lucky Irabor ti sọ pe ileeṣẹ naa ti ṣetan lati doju ija kọ awọn ajijagbara to n lo jagidijagan lati pin Naijiria.
O ni ileeṣẹ ọmọ ogun ko ni wahala kankan pẹlu awọn to n gbe igbe aye wọn ni ilana to ba ofin mu.
Ọgagun Irabor lo sọ ọrọ naa niluu Oweri nibi ipade awọn ọga ologun to ti fẹyinti kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- Ẹ fura o! Kọ́lẹ́rà ti pa èèyàn 66 ní Abuja, tó sì mú èèyàn 873
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Bí mo ṣe jàjàbọ́ rè é lọ́wọ́ àwọn agbẹ́bọ̀n tó jà ọkọ̀ ìjà òfúrúfú mí bọ́ - Ọmọogun Abayomi Dairo sọ ìrírí rẹ̀
- Dubai se òjò àtọwọ́dá láti fi gbógun ti ooru tó mú jù
- Emir ìlú Taraba fún àwọn Fulani Darandaran ní gbèńdéke ọjọ́ 30 láti kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ òun
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- Ìjọ́ mi kìí ṣe alágbé, kìí ṣe owó ló mú ká lé pásítọ̀ mọ́kànlélógójì - Oyedepo
O ni "Ko si ohun to kan ileeṣẹ ọmọ ogun pẹlu awọn ẹya to sọ pe awọn fẹ yapa kuro lara Naijiria nitori ọrọ oṣelu ni."
"Sugbọn a ko ni la oju wa silẹ, ki awọn eeyan naa maa lo jagidijagan lati mu afojusun wọn ṣẹ, a ko ni gba ki ẹnikẹni da ilu ru loju wa."
Irabor sọ pe ofin wa ni Naijiria, eyi to fun araalu laaye lati fi erongba rẹ lede, ṣugbọn ẹnikẹni to ba n ta ẹjẹ ẹlomiran silẹ labẹ ijijagbara yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Ọgagun naa sọ pe awọn ko ni gba ki ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan lo iwa ipa lati tu Naijiria ka.
O ṣalaye pe "Ofin wa ni Naijiria lori ọna lati yanju irufẹ awọn ọrọ yii, idi niyi ti awọn fi n sọ pe jagidijagan kọ ni ọna abayọ si ohun ti awọn ajijagbara n fẹ.
Lori ipade pẹlu awọn ajagunfẹyinti to waye ni Imo, o ni ọrọ lori bi wọn yoo ṣe daabo bo awọn ọmọ Naijiria naa ni awọn sọ nibẹ.

















