Taraba: Emir ìlú Taraba ní bí àwọn Fulani Darandaran tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà òun, wàhálà wọn ti pọ̀jù

Oríṣun àwòrán, Others
Emir ilu Muri nipinlẹ Taraba, Abbas Tafida ti fun awọn Fulani darandaran ni ọgbọn ọjọ lati kuro ninu igbo to wa ni ipinlẹ naa ki wọn to fi tipàtipa le wọn danu.
Emir naa lo kede gbendeke yii lasiko adura Eid ni ọjọ Iṣẹgun.
Eyi ko ṣẹyin bi ijinigbe, ipaniyan ati ikọlu ṣe peleke si nipinlẹ naa ti iwadii si fihan pe awọn ọdaran Fulani darandaran lo wa ni idi iṣẹlẹ naa.
- ''Ó ṣeéṣe kí Sunday Igboho fi ẹ̀wọ̀n jura lórí gbígbà ‘Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú"
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- Ìjọ́ mi kìí ṣe alágbé, kìí ṣe owó ló mú ká lé pásítọ̀ mọ́kànlélógójì - Oyedepo
Emir naa ni awọn Fulani darandaran lo wa nidi iwa ọdaran to n ṣẹlẹ ninu ilu naa, to si fun wọn ni ọgbọn ọjọ lati fi kuro ni awọn inu igbo abi ki wọn fi tipatipa le wọn jade.
O kesi awọn adari awọn Fulani darandaran yii lati ṣe afihan awọn ọbayejẹ to wa ninu wọn.
Emir naa ni: ''Nitori iṣekupani to n waye lojoojumọ nibẹ ni a ṣe fun awọn Fulani darandaran ni gbedeke lati kuro ni awọn inu igbo to wa ni ipinlẹ''
''O ti su wa, a kii ri oju orun lori ibẹru pe awọn darandaran yii le wa ṣe ikọlu si wa, bẹẹ ni ebi si n pa awọn araalu, lailai a ko le jẹ ki eleyii tẹsiwaju.''
- Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria - Amòfin
- Èpè Aole ló ṣì ń ja ìran Yoruba lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho àti Yoruba Nation - Sokoti Alagbede
- Wo bí ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho yóò ṣe lọ ní ìlú Cotonou, Benin Republic lónìí
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí bọ́ lọ́jọ́ kejì ọdún Ileya ní márosẹ̀ Ibadan sí Eko
- Igboho kò gbọdọ̀ padà sí Nàíjíríà, Benin Republic ẹ tú u sílẹ̀ kó lè lọ gbá ''Asylum" ní Germany- Joe Okei-Odumakin
Nibayii, awọn ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Myetti Allah ko i tii fesi si aṣẹ Emir naa.
Ipinlẹ Taraba to wa ni ila-oorun Ariwa orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ iṣẹlẹ ibi ti n waye to fi mọ ijinigbe, ipaniyan ati awọn iwa ọdaran miran ni agbegbe ọun.













