Ogun Accident: Ọkọ̀ akérò forí sọ ọkọ̀ akólẹ̀, èèyàn mẹ́tàlá kú, míjìlá míì farapa

Ijamba ọkọ

Oríṣun àwòrán, FRSC

Kowee ke, ko ha ni ọjọru ana nigba ti ọpọ ẹmi bọ ninu isẹlẹ ijamba ọkọ kan to waye lopopona marosẹ Ibadan silu Eko.

Oludari ileesẹ FRSC nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, to fi idi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe ere asapajude ati yiya ọkọ silẹ nibi ti ko tọ, lo sokunfa ijamba naa.

Gẹgẹ bo se wi, deede aago mẹrin ku isẹju mẹẹdogun nirọlẹ ni isẹlẹ naa waye, ninu eyi ti eeyan mẹẹdọgbọn ti fara gba, ẹmi mẹtala bọ nigba ti mejila fi ara pa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkọ bọọsi akero Mazda ti ijamba naa sẹlẹ si, lo jẹ alawọ funfun, ti nọmba rẹ jẹ APP28YE, lo fori sọ ọkọ akolẹ tileesẹ naa n sakoso rẹ, ti ko si ni nọmba kankan lara.

Umar ni wọn ti gbe awọn eeyan to fara pa ninu ijamba ọkọ naa lọ sile iwosan Idera to wa nilu Sagamu fun itọju nigba ti wọn gbe oku awọn alaisi si ibudo igbokusi to wa nile iwosan naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ajọ to wa fun akoso igboke-gbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Ogun, OSTCEC, Babatunde Akinbiyi ni ọmọde mẹrin lo wa ninu awọn eeyan to ba ijamba ọkọ naa rin.