William Ndubuisi ni àjọ ANC ní India ló gbé Cocaine tí owó rẹ̀ tó N18,167,990.30 wọ Mumbai

India

Oríṣun àwòrán, Others

Àjọ Anti Narcotic Cell ni India ti fẹsùn kan Ndubuisi ọmọ Nàìjíríà kan pé ó gbé Cocaine wọ Mumbai

Ọwọ ajọ to n gbogunti ilo oogun oloro ni orilẹ-ede India ti tẹ ọkunrin ọmọ Naijiria kan ni Mumbai.

Ndubuisi Williams Umunna to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogoji ni ọwọ sinku awọn agbofinro India mu.

Wọn ni o gbe kilogiraamu aadọfa Cocaine ti owo rẹ to N18,167,990.30 to jẹ 33 lakh.

Agbofinro ni Azad Maidan lo gba iroyin naa ni eyi to jẹ ki wọn ri Ndubuisi mu ni aarọ ọjọ Bọ ni agbegbe Loha ni Wadibunder.

Won ni asọ ni afurasi ọmọ Naijiria yii n ta ni agbegbe Kharghar ni Navi Mumbai.

Àkọlé fídíò, Alhaja Rukayat Batimoluwasi Oniwaka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀

Iroyin naa ni pe igbakeji kọmisọnna ọlọpaa, Datta Nalawade fi ẹsun pe Ndubuisi n ta egbogi oloro fun awọn eeyan ni nMumbai ni wọn fi kan an.

Nalawade ni pe wọn ti gbe igbẹjọ naa lọ si abẹ ofin Narcotic Drugs and Psychotropic Substance Act, 1985 ni eyi ti yoo jẹ ko le foju ba ile ẹjọ bi o ti yẹ.

Bakan naa lo ni igbesẹ n lọ lọwọ lati wadii awọn ti Ndubuisi n ta egbogi oloro naa fun.

NDLEA

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Saaju ni Ajọ́ NDLEA ni NAijiria naa ti kọ́kọ́ mu awọ́n meji kan

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ obìnrin olórúkọ púpọ̀ kan tó gbé kílò 465kg 'skunk' sábẹ́ Hijab ní Benue

Chioma Afam tó ń jẹ́ orísìí orúkọ ni NDLEA ti mú lórí gbígbé oògùn olóró ní Benue

Eni ọdun mẹrindinlogoji ni Chioma tó n jẹ orukọ orisii labẹ Hijab tó n wọ fi gbe oogun oloro.

Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ obìnrin olórúkọ púpọ̀ kan tó gbé kílò 465kg 'skunk' sábẹ́ Hijab ní Benue

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Owo ajo to n gbogun ti asilo oogun oloro ni Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA.

Owo NDLEA tẹ olorukọ pupọ yii ni ipinlẹ Benue pẹlu alajọ sisẹ pọ rẹ kan, Peace Chidinma Caleb.

Peace je ẹni ọdun mejilelogun ti wọn ka iwọn 296,000 odindin Diazepam ati Exol-5 mọ lọwọ lati Onitsha nipinlẹ Anambra lọ si ipinlẹ Gombe.

Diẹ lara orukọ miran ti wan maa n pe Chioma ni Amina, Uzoamaka ati Ifunaya lẹnu isẹ.

Awọn mejeeji ni wọ Hijab sisẹ ibi yii ki ọwa to tẹ wọn ninu ọkọ ni Makurdi lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlogun, osu keje, ọdun 2021 nipinlẹ Benue.

Wọn ni ipinlẹ Gombe ni wọn n lọ lati lọ ta kilogiramu metalelogoji Diazepam, ati Exol 5 kilo metalelogbon ni eyi to je tabuleti 296,000 lapapọ ti wan ko sinu apo aromiyọ nla.

Àkọlé fídíò, Iyalaje Oodua: Toyin Kolade ṣàlàyé ìdí tí Ooni Ogunwusi ṣe fi jẹ Ìyálájé Oodua

Saaju ni awọn NDLEA nipinlẹ Ondo, tri mu Olu Ameh to jẹ ọlọkada lọja Aiku.

Olu ko egbogi oloro kilo 465 igbo lọna Ijagba Ute nijaba ibilẹ Ose.

O ni Okunrin Joseph in Ago Akure, ni ijoba ibile Akure to dẹ tun fẹ ta a ni Egbonwon ni abule Ijesha.