Sunday Igboho: Amòfin ní ìjọba Benin Republic ló yarí mọ́ Nàiíjíríà lọ́wọ́, ni Igboho kò fi tíì dèrò ilé

Ijọba orilẹ-ede Benin Republic ti bẹgi dina akitiyan ijọba Naijiria lati ku giri gbe oloye Sunday Igboho wa si ọọfisi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS l'Abuja.
Iroyin ni ijọba apapọ gbiyanju lati gbe Igboho wa si Naijiria lana Ọjọru, ṣugbọn ijọba Benin kọ jalẹ, nitori wọn ni igbesẹ ọhun ko ba ba ofin mu.
Ọkan lara awọn agbofinro orilẹ-ede naa to ba awọn akọroyin sọrọ ni idankọnkọ sọ pe ijọba Benin tako igbeṣe ijọba Naijiria nitori wọn gbagbọ pe gbogbo agbaye lo n tẹlẹ iṣẹlẹ naa ati ibi ti yoo fori sọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Èpè Aole ló ṣì ń ja ìran Yoruba lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho àti Yoruba Nation - Sokoti Alagbede
- Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí bọ́ lọ́jọ́ kejì ọdún Ileya ní márosẹ̀ Ibadan sí Eko
- Igboho kò gbọdọ̀ padà sí Nàíjíríà, Benin Republic ẹ tú u sílẹ̀ kó lè lọ gbá ''Asylum" ní Germany- Joe Okei-Odumakin
- Ó lé yọrí sí ogun, tí ìjọba Naijiria bá fi ìyà jẹ Sunday Igboho bí ọ̀daràn - Gani Adams
- Àjọ Anti Narcotic Cell ní India ti fẹ̀sùn kan Ndubuisi ọmọ Nàìjíríà kan pé ó gbé Cocaine wọ Mumbai
Ọkan lara awọn agbofinro Igboho, Pelumi Olajengbesi sọ fun awọn akọroyin pe igbesẹ naa n ṣafihan pe ijọba Benin jẹ eyii to bọwọ fun ofin ati ẹtọ ọmọniyan.
O ni ikọ agbẹjọro Igboho n ba ijọba Benin sọrọ lori ọrọ ọhun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, bo tilẹ jẹ pe ijọba Naijiria n fẹ ki wọn gbe Igboho wale pẹlu agidi, ijọba Benin ni awọn gbọdọ gbe ọrọ naa dele ẹjọ gẹgẹ bii alakalẹ ofin.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ijọba Naijiria ti kọkọ gbiyanju lati fi ṣikun ofin mu Igboho lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, loju ọna marosẹ Eko si Ibadan, ṣugbọn wọn kuna.
Lẹyin naa ni wọn kọlu ile rẹ to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, nibi ti wọn ti pa eeyan meji ti wọn si tun fi ṣikun mu awọn bii mejila miran.
Ninu atẹjade kan ti DSS fi lede, wọn ni awọn ba oriṣiriṣi ohun ija oloro nile rẹ bii ibọn ati ọpọlọpọ aṣọ oogun, ti wọn si kede pe ko jọwọ ara rẹ fun awọn lati wa sọ tẹnu rẹ.
Iṣẹlẹ naa lo mu Igboho poora ko to di pe wọn mu ni Cotonou, iyẹn lorilẹ-ede benin Republic lasiko to n gbiyanju lati tẹkọ leti lọ si Germany.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti n gbiyanju lati gbe Igoho pawa wa si Naijiiria, olori awọn agbẹjọro rẹ, Yomi Aliyu sọ igbe naa ko le bọ si nitori adehun ti Naijiria, Togo, Ghana ati Benin tọwọ bọ lọdun 1984.

Sunday Igboho kìí ṣe 'Terrorist', ẹ fi sílẹ̀ ní àhámọ́ - Àwọn Olùwọ́de faraya

Iwọde nla ti gbearsọ nilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Ọyọ lọsan Ọjọru.
Ọgọọrọ awọn eeyan to korajọ naa ni wọn n beere fun idande ajijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho.
Bẹẹ ba gbagbe, Igboho ni ijọba Naijiria mu ni papakọ ofurufu kan nilu Cotonou lorilẹede Benin lasiko to fẹ tẹ ọkọ leti lọ sorilẹede Germany pẹlu aya rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "A kò sinmi lórí ọ̀rọ̀ Yoruba Nation, Sept 14 lá yọjú sí United Nation"
- Ooni Ife àtàwọn èèkàn Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Amotekun àtàwọn jàndùkú kọlu ara wọn ní Ibadan, èèyàn méjì kú lọ́jọ́ Ileya
- Wọn yóò tẹ ẹ̀tọ́ Sunday Igboho mọ́lẹ̀ tó bá padà sí Nàìjíríà - Afenifere Renewal Group
- Ìwọ́de ńlá yóò wáyé lónìí ní London lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation yóò ṣe iwọ́de tako bí wọ́n ṣe mú Sunday Igboho
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- "Ìdí tí ìjọba Benin Republic kò ṣe ní le è fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ ree"
- Ìyàtọ̀ wà láàrin èsì àyẹ̀wò ikú Jumoke àti ohun tí ọlọ́pàá sọ
Awọn eeyan to korajọ lati fi ẹhonu han lori isẹlẹ naa ti wa koro oju si bi wọn se mu Sunday Igboho nitori pe o n gbeja iran rẹ.
Lara awọn to ba BBC Yoruba sọrọ niwaju ile Sunday Igboho to wa ladugbo Soka nilu Ibadan nibi ti iwọde naa ti gberasọ rọ awọn araalu lati jade fun iwọde naa.

"Ohun to sẹlẹ nile Sunday Igboho lọjọ Kinni osu Keje kii se ohun to dun mọ wa ninu rara, ki wọn wọle pa eeyan, ti wọn si sun n ba dukia jẹ.
Ẹyin DSS, a ti di akeku ejo, ẹ sọra fun wa. Eyi tẹ se, tẹ mujẹ, kii se pe ko si agbara, a ko fẹ itajẹsilẹ ni.
A si n sọ fun awọn olowo wa pe gbogbo ohun to n sẹlẹ yii, a dijọ ti ara bọ ni, ko si ẹnikẹni ti yoo le raye salọ kuro ni Naijiria, a jọ tẹsẹ bọ ni."
Awọn oluwọde naa ni kii se danadan ki ilẹ Yoruba wa ni ara Naijiria, ohun ti awọn si n fẹ ni pe ki wọn jẹ ki Yoruba ni orilẹede tiẹ.
"Sunday Igboho kii se Criminal ta mọ si ọdaran, dandan si kọ ni ka dijọ wa pọ.
Ẹsẹ si kọ ni ki eeyan ja fun ominira iran rẹ, nitori naa, ẹ ba wa fi Sunday Igboho silẹ ni ahamọ tẹ fi si.
Ko si ẹsẹ kankan ti Igboho sẹ, ijọba Naijiria ti rẹ Yoruba jẹ, rẹ wa ta, ti wọn si tun fẹ maa rẹ wa danu.
A wa n bẹ awọn ọba alaye lati dide tako iwa ika tijọba apapọ n hu si Sunday Igboho, ijọba fẹ yan jẹ ni, ẹ jọọ, ẹ mase gba ki wọn fi iya jẹ Igboho."
Awọn oluwọde naa wa n lọgun pe ohunkohun ko gbọdọ se Sunday Igboho nitori o ni ọmọ to pọ gan, ti yoo dide lati gbe nija, ti wọn ba fi ohunkohun se.
Bakn naa ni wọn rawọ ẹbẹ si ijọba Benin Republic pe ko mase fọwọ sowọpọ pẹlu ijọba Naijiria lati fi iya jẹ Sunday Igboho ati iran Yoruba lapapọ.

Àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation yóò ṣe iwọ́de tako bí wọ́n ṣe mú Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, others
Awọn ajijagbara Yoruba Nation yoo ṣe ifẹhonuhan niluu Ibadan lọsan oni lati pe fun itusilẹ oloye Sunday Igboho lẹyin ti wọn fi ṣikun ofin mu ni Beni Republic.
Agbẹnusọ Igboho, Olayomi Koiki lo fi ọrọ naa lede loju opo facebook rẹ ninu atẹjade kan.
Ninu atẹjade naa ni Koiki ti ke si gbogbo awọn oolufẹ Igboho ati Yoruba Nation lati tu sita niwaju ile Igboho.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ooni Ife àtàwọn èèkàn Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ìwọ́de ńlá yóò wáyé lónìí ní London lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- "Ẹ̀yìn ọba Yorùbá, ẹ dìde láti gbe Sunday Igboho níjà kó le jàré nílẹ̀ Benin"
- "Ìdí tí ìjọba Benin Republic kò ṣe ní le è fa Igboho lé Nàíjíríà lọ́wọ́ ree"
- Inú ìrora ni Sunday Igboho wà pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́-ṣẹkẹ̀ ní àhámọ́ - Agbẹjọ́rò
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
- Sunday Igboho àti aya rẹ́, Ropo ni ọlọ́pàá Interpol mu ní Cotonou - Agbẹjọ́rò
- Kìí ṣe tuntun pẹ ìjọba Buhari tí mú Sunday Igboho, àmọ́ ọ̀nà àbáyọ sí ìtúsílẹ̀ rẹ̀ rèé - Agbẹnusọ Sunday Igboho
- Buhari, tú Sunday Igboho sílẹ̀ bo ṣe tú Boko Haram tó ronúpíwàda sílẹ̀ - Ladoja
O ni "A bẹ gbogbo awọn ajijagbara Yoruba Nation lati peju siwaju ile Igboho ni aago mejila ọsan oni ni Soka, niluu Ibadan, fun ifẹhonuhan ti ko ni jagidijagan ninu. A fẹ ki gbogbo agbaye mọ irufẹ ẹni ti Igboho jẹ."
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fi ṣikun ofin mu Igboho ni papakọ ofurufu kan niluu Cotonou lasiko ti wọn ni o n gbiyanju lati wọ baluu lọ si Germany.
Lọsẹ to kọja ni awọn ajijagbara naa ti kọkọ ṣe iwọde kan lati fi ẹhonu wọn han lori bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣe kọlu ile Igboho lọjọ kinni oṣu yii.
Ẹwẹ, agbẹjọro rẹ, Yomi Aliyu ṣalaye fun BBC Yoruba pe Igboho yoo foju bale ẹjọ lonii yii kan naa nibi ti igbẹjọ yoo ti waye lori akitiyan ijọba apapọ lati gbe wa si Naijiria.



















