Sunday Igboho: Amòfin rẹ̀ ní yóò f'ojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbésẹ̀ láti gbé wá sí Naijiria

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, others

Agbẹjọro Sunday Igboho, Yomi Aliyu, ti sọ pe inu irora ni onibara oun wa lẹyin ti wọn fi panpẹ ofin mu lorilẹ-ede Benin republic.

O ni irora naa pọ nitori ṣẹkẹṣẹkẹ ni wọn fi de ninu ahamọ to wa niluu Cotonou.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ko ṣe itọju onibara oun daadaa nitori awọn to wa ni ikawọ rẹ ti gba aṣẹ kan lati oke wa, ati pe yoo foju bale ẹjọ lonii yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yom Aliyu lo fi ọrọ naa lede lasiko to n fesi lori ọrọ to n ja rain ṣaaju lori ayelujara pe wọn ti gbe onibara rẹ naa wa si Naijiria lati Benin.

Nigba ti BBC Yoruba kan si Aliyu, o ṣalaye pe lootọ ni wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Igboho lọwọ.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

O ni "Iroyin to tẹ mi lọwọ ni pe wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Sunday Igboho lọwọ, o si wa ninu irora ti ko ṣe fẹnusọ nitori o ti kọkọ fi ọwọ naa ṣeṣe lasiko ti wọn n gbiyanju lati mu ni papakọ ofurufu."

Aliyu ṣalaye siwaju si pe lootọ ni Igboho yoo foju bale ẹjọ lori igbesẹ lati gbe wa si Naijiria, amọ irufẹ ẹsun ti wọn ba fi kan an ni yoo sọ ibi ti ọrọ naa yoo dojukọ.

Bo tilẹ jẹ pe ko darukọ boya agọ awọn ọlọpaa ni Igboho wa, ṣugbọn o ni wọn fi to ohun leti pe ipo ti Igboho wa ko ṣe e gbọ seti nitori inu ṣẹkẹṣẹkẹ lo wa lọwọ ati lẹsẹ ni ahamọ.

Agbẹjọro naa ṣalaye pe "Wọn fi to mi leti pe aṣẹ kan lo wa lati oke wa pe ki wọn de tọwọ-tẹsẹ, inu irora nla lo si wa."

O ni o ṣeeṣe ki gbogbo igbiyanju ijọba lati gbe Igboho wa si Naijiria ja si pabo nitori ẹsun to rọ mọ ọrọ oṣelu ni wọn fi kan Igboho.

Aliyu ṣalaye siwaju si pe "Mo mọ pe wọn maa gbe oloye Sunday Igboho lọ sile ẹjọ lọjọru, nitori awọn ti wọn mu ati ijọba Najiiria yoo gbiyanju lati gba aṣẹ ile ẹjọ lati gbe wa si Naijiria,"

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

"Ṣugbọn o ṣeeṣe ki wọn ma ri aṣẹ naa gba niroti irufẹ ẹsun ti wọn yoo fi kan, eyii ti ko fi aye gba ijọba apapọ lati gbe wa si Naijiria."

"Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju ninu atẹjade kan, ọna ti wọn gba mu gan ko ba ofin mu nitori iwe idehun ti wa laarin ijọba Naijiria, Togo, Ghana ati Benin lori bi wọn yoo ṣe yanju irufẹ ọrọ yii."

Aliyu pari ọrọ rẹ pe, iwe adehun ti awọn orilẹ-de mẹrẹrin naa tọwọ bọ lọdun lọdun 1984 ko faye gba ijọba Naijiria lati gbe Sunday Ighoho wọle si Naijiria nitori irufẹ ẹṣẹ ti wọn ni o ṣẹ.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams