Sunday Igboho: Ọ̀pọ̀ ‘ẹ̀ṣẹ̀’ tí ajìjàgbara ṣẹ ìjọba rèé, tó fi di ẹni tí wọn ń wá

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Yoruba ni n ko le wa ku, kii jẹ oye ile baba rẹ, bẹẹ si ni aileja ni jẹ ita baba mi ko de ihin.

Kii se iroyin mọ pe wọn mu Oloye Sunday Igboho ni ilu Cotonou lorilẹede Benin ninu osu keje odun 2021 ti wọn si tu u silẹ pe ko kan lọ tọju ara rẹ ni ọjọ Keje Oṣu Kẹta ọdun 2022.

Amọ, o yẹ ka le ran ara wa leti nipa awọn ohun ti Igboho se, to fi di ẹni ti ijọba apapọ n le kiri.

Ti a ba n sọrọ nipa awọn eeyan to dide lati gbeja ẹya ti wọn ti wa, ọkan lara won ni Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Igboho.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ni pe lasiko ti ipenija eto aabo gbona jainjain ni agbegbe rẹ, ni Igboho dide lati gbe iran rẹ nija.

Lati igba yii wa si lo ti di ajijagbara ti awọn eeyan n sa tọ lọ lati gbe wọn nija, ko to wa di pe o bẹrẹ si pe fun iyapa Naijiria ati idasilẹ orilẹede Yoruba.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Odu ni Sunday Igboho saaju asiko yii, to si ti maa n se atilẹyin fun oloselu bii Rashidi Ladoja ati awọn eeyan miran ti iya n jẹ.

Amọ awọn igbesẹ to gbe ree, to fi ba pao ibinu ijọba Naijiria pada.

Igboho wọnu igbo Kishi lọ:

Amọ isẹ ijijagbara rẹ yii bẹrẹ nigba to lọ si inu igbo to wa nilu Kishi nipinlẹ Oyo lati wa awọn agbebọn darndaran to fi igbo naa se buba lati jale ati paayan.

Isẹlẹ yii waye ni osu Kẹwa ọdun 2020 to kọja, ti Igboho, awọn ọdẹ ibilẹ, ati fijilante si pawọpọ sisẹ naa, to si ko awọn afurasi ọdaran to ko ninu igbo ọhun le awọn agbofinro lọwọ.

Igboho ke si awọn ọmọ Yoruba lati fi iwọde sami ayajọ ominira lọdun 2020:

Ni osu kan lẹyin isẹlẹ yii ni Sunday Igboho kede pe ta ba dakẹ, tara ẹni maa n ba ni dakẹ ni, to si ke si awọn ọmọ Yoruba lati jade fun iwọde.

Ọjọ Kinni osu Kẹwa ọdun 2020 ni wsn fi iwọde naa si, eyi ti wọn seto lati waye ni oke okun pẹlu.

Amọ Sunday Igboho ko lọ sigboro ni ọjọ naa lati se iwọde ọhun bi o tilẹ jẹ pe oun ati awọn ọmọlẹyin rẹ duro siwaju ile rẹ lati sọrọ pẹlu asia lọwọ wọn.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

Sunday Igboho kede pe ki Seriki Fulani ati awọn afurasi ọdaran Fulani kuro ni ilu Igangan:

Ni ọjọ kẹẹdogun osu Kinni ọdun 2021 ni Sunday Igboho lọ si ilu Igangan lagbegbe Ibarapa, to si ke si awọn Fulani to wa ni agbegbe naa lati ko aasa wọn kuro nibẹ.

O si kede ọjọ meje pe ki wọn fi palẹ ẹru wọn mọ, bibẹẹkọ, oun yoo wa ba wọn nibẹ lati le wọn.

Nigba ti ọjọ pe, o lọ sagbegbe naa lootọ, to si ba awọn eeyan ibẹ sọrọ, amọ ni kete to kuro tan ni idarudapọ waye, ti wọn si jo ile Seriki Fulani ati awọn dukia rẹ.

Sunday Igboho lọ sinu igbo Yewa ati Ondo lati le awọn afurasi ọdaran darandaran:

Bakan naa ni Igboho tun lọ si agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun ni ọjọ Kinni osu keji ọdun 2021 lati lọ le awọn afurasi ọdana daranran to n pa awọn eeyan, fipa ba ni lopọ tabi ja awọn araalu ni ole.

Lasiko yii si ni awọn eeyan agbegbe naa n fo fayọ pe alaafia to awsn lọwọ nitori awọn afurasi ọdaran naa ti fi agbegbe awọn silẹ tori abẹwo Igboho.

Koda, wọn ni iroyin Igboho lasan ti to lati da jinnijinni bo awọn afurasi ọdaran naa, ti wsn si n sa kijokijo, ti wsn ba ti gbọ orukọ Igboho.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Sunday Igboho gunle iwọde fun idasilẹ Yoruba Nation:

Lẹyin ti Sunday Igboho sinmi lile awọn ọdaran darandaran, lo ba gunle ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, eyi to tumọ si iyapa fun orilẹede Naijiria.

Sunday Igboho ati ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, ti alagba Banji Akitoye n dari rẹ, gbe awọn iwọde yii lọ kaakiri igun mẹrẹẹrin to wa nilẹ Yoruba.

Yatọ si pe iwọde fun Yoruba Nation yii waye lawọn ilu nla nla nilẹ Kaarọ Oojire, ko si ipinlẹ kankan lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ti iwọde naa ko de rara.

Bẹẹ ni wọn tun n gbe iwọde fun idasilẹ Yoruba Nation lọ sawọn ile ẹkọ, aarin ọja, ibudokọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi ikede fun idasilẹ Yoruba Nation si se n waye ni Naijiria naa ni wọn n se iwọde ni oke okun, eyi to mu ki ikede naa maa gbilẹ lojoojumọ.

Lati igba yii wa si ni Sunday Igboho ti n ri pipọn oju ijọba Naijiria lori ẹsun pe o fẹ da ilu ru, to si n pe fun ituka orilẹede yii.

Bẹẹ ni ọpọ igba ni wọn ti gbiyanju lati mu si ahamọ, nipa lilọ si ile rẹ, ti igbesẹ ijọba si n ja si pabo.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Amọ ni ọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021, ni awọn osisẹ DSS ya bo ile Sunday Igboho ni ọganjọ oru, wọn pa eeyan nibẹ, ti wọn si ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ nibẹ.

Koda, wọn ko eeyan mejila kuro ninu ile naa lọ si ọọfisi wọn ni Abuja, ti awọn onitọun si wa ni ahamọ DSS titi di oni.

Lẹyin o rẹyin ni iroyin gbalẹ pe ọwọ ti tẹ Oloye Sunday Igboho nilu Cotonou lorilẹede Benin lasiko to fẹ tẹ baalu leti lọ si orilẹede Germany.