Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùbá

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

O tó gẹ́, kí a kó apá tí kò bá ṣe é ṣán mọ́ padà sórí ni Nàìjíríà- Oyinlola

Gomina ipinlẹ Osun nigba kan ri, Oloye Olagunsoye Oyinlola gba BBC Yoruba lalejo, O sọrọ ilẹ kun lori ibi ti Naijiria de duro

Oyinlọla fi ẹdsun ọkan rẹ han lori bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe yi ohun pada lori ọrọ 'Restructuring' ti gbogbo wọn fi ta Buhari fun Yoruba lasiko idibo.

O ni o dun oun pe Buhari ni pe oun ko mọ nkan to n jẹ 'Restructuring'mọ nisinyi.

Oyinlola

Oríṣun àwòrán, @Oyinlola

Oyinlọla gbadura idariji nitori pé ko si ootọ mọ.

O ni Oun mọ ọpọlọpọ ipa ti oun ko ninu igbesẹ to sọ Buhari di aarẹ Naijiria ṣugbọn pẹlu ibanujẹ ni o fi han pe wọn ko mu ikankan ṣẹ ninu ileri to pọ ti wọn ṣe paapaa lori eto aabo.

Olagunsoye ni ohun to fi dabi pe Boko Haram yoo dohun igbagbe laarin oṣu mẹfa ti Buhari ba de ibẹ tẹlẹ ni.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Others

Olusegun Obasanjọ kìlọ̀ fún wa pé Buhari kò lè gbé ẹrù Nàìjíríà ṣùgbọ́n a kò gbọ́ sí i lẹ́nu- Olagunsoye Oyinlola.

O to gẹ, ti apa ko ba ṣe e ṣan mọ, eeyan maa n kaa lori ni ibi ti ọrọ Naijiria de duro bayii.

Olagunsoye

Oríṣun àwòrán, @Oyinlola

Asiko ti to ki a pada si bo ṣe wa tẹlẹ laye Awolowọ ti onikaluku n mojuto ẹkun rẹ ni.

Eto ẹkọ, eto ọgbin, ile gbigbe, ọna ṣiṣe ati bẹẹ bẹe lọ ni koowa n mojuto bo ṣe wu u.

Ti iwájú kò bá ṣe é lọ, kí a kúkú padà síbi tí a ti bẹ̀rẹ̀- Olagunsoye Oyinlola

Bẹẹ ko sẹni ti a le maa bẹ pe ko maa ṣẹru nigba gbogbo nigba ti a ko pin nkan bi o ṣe yẹ.