Oyo Covid-19 update, Delta variant of covid-19: Ó ṣeéṣe kí á kéde àwọn ìlànà tuntun láìpẹ́ - Ìjọba Oyo

Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Ijọbab ipinlẹ Oyo ti sọ pe awọn ti bẹrẹ si n gbe awọn igbesẹ tuntun lẹyin ti wọn ri ẹda Covid-19 tuntun ti wọn n pe ni Delta viariant ni ipinlẹ naa.

Agbẹnusọ gomina ipinlẹ ọhun, Taiwo Adisa lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Adisa ni iwadii ijinlẹ ti awọn onimọ ipinlẹ naa ṣe lo tete jẹ ki awọn kofiri ẹda arun tuntun ọhun.

Bo tilẹ jẹ pe o ni lootọ ni awọn ti fidi rẹ mulẹ pe ẹda arun naa tuntun ti ran awọn eeyan kan ni ipinlẹ Oyo, afojusun awọn ni bi awọn yoo ṣe kapa rẹ ti ko si ni burẹkẹ si i.

O fi kun pe awọn ti bẹrẹ itanilolobo, awọn yoo si pada si awọn ilana ti wọn gbe kalẹ tẹlẹ lasiko ti arun ọhun kọkọ gbode kan lọna ati kapa rẹ.

Adisa ni "Awọn ohun ti an ṣe tẹlẹ ni a o pada si lati kapa ẹda tuntu yii."

"O da bi pe arun naa ti n lọ lo jẹ ki ọpọ awọn eeyan turaka, ṣugbọn bayii ati bẹrẹ igbeṣe tuntun lati pana arun ọhun."

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni awọn ti bẹrẹ si n wa awọn eeyan to ti ṣalabapade awọn eeyan to ti fara kasa ẹda arun naa tuntun.

Lẹyin naa, Adisa rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati bẹrẹ si n tẹle awọn ilana to rọ mọ arun naa bii fifọwọ ẹni loorekoore pẹlu omi ati ọṣẹ, to fi mọ awọn ilana mii bii lilo ibomu lawujọ ati itakete siraẹni.

Àkọlé fídíò, Royal Hugs Surprises: Ìyá ẹni ọdún 50 tó dọlọ́mọ láyé fi ìdùnnú hàn bí a ṣe kàn síi- Debor

Adisa pari ọrọ rẹ pe awọn yoo ṣe ikede lori iye eeyan ti yoo maa korajọ lawọn ile ijọsin laipẹ lẹyin ipade igbimọ to n bojuto arun naa l'Oyo.

Bo tilẹ jẹ pe o ni awọn dẹwọ awọn ilana kan to rọ mọ Covid-19 tẹlẹ, kii ṣe pe awọn ti kasẹ rẹ nilẹ patapata, o si ṣeeṣe ki awọn ṣe ikede tuntun lori rẹ laipẹ.

Ẹ̀dà àrùn Coronavirus gbẹ̀mí-gbẹ̀mí tuntun ti wọ ìpínlẹ̀ Oyo

Ìjọba Oyo kìlọ̀ fún àwọn èèyàn láti tẹ̀lé ìlànà tó de àrùn Coronavirus

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede pe awọn ti ri arun Coronavirus, ti iru Delta Variant nipinlẹ naa.

Alamojuto eto pajawiri nipinlẹ Oyo, Dokita Olabode Ladipo to fi ikilọ naa lede, rọ awọn araalu lati ṣe jẹjẹ, ki wọn si tẹle gbogbo alakalẹ ajọ amuṣẹya to n gbogun ti aarun Coronavirus nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti ijọba fi sita ni wọn ti sọ fun awọn eniyan pe ẹni to ni arun Coronavirus ti ẹya Delta Variant ti wa ni ibi iyaraẹnisọtọ nipinlẹ ọhun.

Iru arun Coronavirus yii ma n tete ran awọn eniyan, ti o si lagbara ju ti tẹlẹ lọ fun ẹnikẹni to ba lugbadi rẹ.

''Eleyii ni lati kilọ fun awọn araalu pe arun Coronavirus si n ja ranyin nilẹ, ki onikaluku sọ ara rẹ.''

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ke si awọn eniyan lati tẹle ofin ti yoo dena itankalẹ arun naa.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

"Ati pe awọn ti wọn ba n ti ilẹ okeere bọ wa si ipinlẹ Ọyọ gbọdọ kọkọ ya ara wọn sọtọ fun ọjọ meje, ki wọn si fi ara wọn kalẹ fun ayẹwo.

"Lilo ibomu ati fifọ ọwọ loore-koore ṣe koko lasiko yii paapaa nigba ti awọn eniyan ba wa ni gbangba.''

"Ti ara ẹnikẹni ko ba si ya, o pọn dandan ki awọn araalu lọ si ileewosan abi ojuko ayẹwo fun aarun Coronavirus.''

Atẹjade naa pari pẹlu ọrọ iyanju pe "O ṣe pataki ki ijọba ati awọn ar ṣiṣẹ pọ lati ri pe aarun naa ko tankalẹ ju bayii lọ nipinlẹ Oyo.''