SoundSultan is dead: Àwọn olórin ti ń ṣèdárò Olanrewaju Fasasi tó dágbére fáyé

Soundsultan

Oríṣun àwòrán, soundsultan

Lẹyin ti iroyin iku gbajugbaja olorin takasufe, SoundSultan jade lori ayelujara, ọpọ awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ orin atawọn ọmọ Naijiria mii lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ.

Lara awọn eeyan naa ni Tuface Idibia, ti ọpọ eeyan mọ si Tubaba, DJ Neptune, DJ Cuppy atawọn olorin mii kaakiri Naijiria.

Lasiko to n sọrọ lori iku Sound Sultan, Tuface ni " Sun re ninu ogo arakunrin mi, titi ayeraye ni oo maa wa ninu ọkan wa. Ọlọrun lo n fun ni..."

Nigba ti Imohiosen Patrick, ti ọpọ eeyan mọ si DJ Neptune n sọrọ ni tirẹ, o ni "Ẹgbọn Sound Sultan, o ṣoro lati gbagbọ fun mi pe ẹ ti dagbere faye nitori a ṣi sọrọ ni nnkan bii oṣu kan ṣeyin. Ẹni ire ti lọ!"

Ni ti DJ Cuppy, ko sọ ọrọ pupọ ju pe ki Ọlọru tẹ Soundsultan si afẹfẹ rere.

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Lara awọn gbajumọ mii to tun n ṣọfọ Soundsultan ni Mr macaroni to sọ pe adanu nla ni iku oloogbe naa jẹ.

Lẹyin naa lo tun gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn mọlẹbi rẹ ninu.

Lara awọn eeyan miran to tun n ṣọfọ Soundsultan ni ajafẹtọọmọniyan, Aisha Yesufu atawọn ẹlomiran.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Olórin tàka-súfèé, Sound Sultan ti jáde láyé

Soundsultan

Oríṣun àwòrán, soundsultan

Gbajugbaja olorin takasufe, Olanrewaju Fasasi, ti ọpọ eeyan mọ si Sound Sultan ti jade laye.

Sound Sultan, ti iroyin ti kọkọ sọ pe o ni arun jẹjẹrẹ ọna ọfun tẹlẹ dagbere faye lẹni ọdun mẹrinlelogoji.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oloogbe naa ti kọkọ n gba itọju nile iwosan kan nilẹ Amẹrika.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun awọn mọlẹbi rẹ, Kayode Fasasi fi lede, lo ti kede iku rẹ.

Atẹjade ọhun ni "Inu wa bajẹ gidi lati kede ipapoda gbajumọ olorin takasufe, Olanrewaju Fasasi, ti awọn eeyan mọ si SoundSultan."

Soundsultan

Oríṣun àwòrán, soundsultan

"O jade laye lẹni ọdun mẹrinlelogoji lẹyin to ti kọkọ ba arun "Angioimmunoblastic T-cell lymphoma" finra.

Ọjọ kẹtadinlọ́gbọ̀n, oṣu Kọkanla, ọdun 1976 ni wọn Soundsultan sinu ẹbi tọkọtaya Fasasi Adeyinka Ajarat, Fasasi Liadi Alarape.

Iyawo, awọn ọmọ mẹta atawọn ibatan ni olooge naa fi silẹ saye lọ.

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'