Ogun Cultism: Ọlọ́pàá mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ta tí wọ́n fi típa mú akẹgbẹ́ wọn wọ ẹgbẹ́

Ogun Cultism: Ọlọ́pàá mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ta tí wọ́n fi típa mú akẹgbẹ́ wọn wọ ẹgbẹ́

Oríṣun àwòrán, Ogun

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ní àwọn ti mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ta tí ẹgbẹ́ Viken fún mímú àwọn akẹ́gbẹ́ wọ́n tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ẹgbẹ́ òkùnkùn wọ ẹgbẹ́ ní túlàsì.

Wọ́n fi ọwọ́ òfin mú àwọn àwọn afurasí náà lẹ́yìn tí Celestin Oyebuchi mú ẹjọ́ lọ sí àgọ́ ọlọ́paàá Igbesa pé àwọn mẹ́ta kan, Omoori a.k.a Tension, Edet Godswill àti Emmanuel Dimgba jí òun gbé.

Lẹ́yìn èyí ló ni wọ́n gbé òun lọ sí ilé àkọ́kù kan níbi ti wọ́n ti fi ìyà jẹ ti wọ́n sì mú ni tipa láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn.

Ó tẹ̀síwájú pé wọ́n fìyà jẹ òun lọ́nà àìtọ́, wan tún fún []oun ni ẹ̀jẹ̀ mu gẹ́gẹ́ bi àmì pé òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ náà.

Lẹ́yìn tó mú ẹjọ́ yìí lọ sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ni DPO Igbesa SP Abayomi Adeniji ran àwọn ọmọ rẹ̀ l;áti lépa àwọn ọdaran náà ti wọ́n sì rí wọn mú ni ìlú Igbesa.

Àkọlé fídíò, Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua

Lásìkò ìfọ̀rọ̀wọ́nilẹ́nuwò, àwọn mẹ́ta òun jẹ́wọ́ pé ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Vikens ni àwọn àti pé nítorí àwọn ń fẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti darapọ mọ́ àwọn ni wọ́n se ji gbé.

Ẹ̀wẹ̀ Kọmísọnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Edward Awololwo Ajogun ti ni ki wọ́n gbé ẹja náà lọ sí ẹka to n gbogun ti ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìpínlẹ̀ egun kí wọ́n sì ṣe ìwádìí lẹ́kunrẹ́rẹ́.

Àkọlé fídíò, TB Joshua Burial: Wolii Synagogue SOAN jẹ́ Akàndá ẹ̀dá- Oba Enitan Ogunwusi, Ooni Ile Ife

Bákan náà ni Kọmísọ́nà wá kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìpínlẹ̀ náà pé ọlọ́pàá kò ni sínmi láti máa gbogun ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìpínlẹ̀ náà.

O rọ̀ wọ́n láti lọ so ewé agbéjẹ mọ́wọ́ kí ọwọ́ òfin tó tẹ̀ wọ́n.

Àkọlé fídíò, Royal Hugs Surprises: Ìyá ẹni ọdún 50 tó dọlọ́mọ láyé fi ìdùnnú hàn bí a ṣe kàn síi- Debor