Baba Ijesha: Lẹ́yìn tí a gbọ́ àwíjàre lẹ́nu Dele Matti tó jẹ́ olùdarí eré Ọkọ Iyabọ àti Yomi Fabiyi, a ríi pé wọ́n jẹ̀bi- TAMPAN

Oríṣun àwòrán, @Fabiyi
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Yomi Fabiyi ti tun fesi si igbesẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN lori bi wọn ti jawe gbele ẹ fun lori fiimu OKO IYABO to gbe jade.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita lọjọ Ẹti lo ti kede pe igbesẹ naa waye nitori iwa abuku ati eyi ti ko ba oju mu gẹgẹ bi oṣere ti Fabiyi hu nipa fiimu Ọkọ Iyabọ to gbe jade laipẹ yii.
Fiimu naa to gbe jade ni ọjọ Aiku to kọja da lori ọrọ ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan osẹre miran, Baba Ijesha.
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
- ''Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo''
- 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
TAMPAN sọ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti oun gbọ awijare Yomi Fabiyi to jẹ olukọtan, olootu ati oludari fiimu naa, ati oludari keji, Ọgbẹni Dele Matti.
"A ri pe wọn jẹbi hihu iwa ti ko bojumu fun akọṣẹmọṣẹ oni tiata.''
Amọ, Yomi tutọ soke o tun foju gba a ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ ;ọjọ Abamẹta.
Yomi ṣalaye pe oun ko figba kankan jẹ ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, koda oun ko ni kaadi idanimọ ọmọ ẹgbẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Yomi Fabiyi
TAMPAN kò lè ní kí fíìmù OKO IYABO má jáde, mi kìí ṣ'ọmọ ẹgbẹ́ wọn- Yomi Fabiyi
O ni ọpọ awọn gbajugbaja oṣere ni ko ni kaadi idanimọ ẹgbẹ TAMPAN lọwọ ti wọn ṣi n ṣere wọn lọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
''Ẹgbẹ ANTP ni gbogbo wa jọ wa tẹlẹ, asiko ti to bayii lati pada di ọmọ ẹgbẹ ANTP pada.
- Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- 'Ariwò tí ẹ̀ ń pa kò lè dóòlà ẹ̀mí Sunday Igboho, kò leè sá mọ́ ìjọba lọ́wọ́'
- Gbogbo ìgbèsẹ̀ tí Sunday Igboho ń gbé ni mo mọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí Aare Ona Kakanfo - Gani Adams
O dami loju pe inu oloogbe Ogunde yoo dun si eleyii nibi to wa bayii.
Ẹ bami bi awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN pe ki wọn fi fọọmu ti mo fi darapọ mọ ẹgbẹ naa sori ayelujara ki awọn eeyan rii ki wọn si le mọ bo ya ọmọ ẹgbẹ ni mi.
Fun idi eyi, iwe lọọ rọkun nle ti wọn kọ si mi, mo ti da a pada fun wọn.
Ohun ti gbogbo ẹgbẹ awọn oṣere wa fun ni lati maa ja fawọn ọmọ ẹgbẹ ati lati maa wa igbayegbadun ọmọ ẹgbẹ.
Ẹyin TAMPAN, e bi ara yin leere bo ya ẹ n ṣe awọn nkan yii ninu ẹgbẹ.
Lẹta ti ẹ kọ si mi, n ko tiẹ ri tiyin ro rara, o si dami loju pe ẹ mọ daju wi pe ko si ẹni to le dami duro lati maa ṣe fiimu ti mo n ṣe mọ.
Fiimu to dara ni OKO IYABO, ẹ ko si lagbara lati ṣe ayẹwo rẹ gẹgẹ bi ẹ ṣe sọ ninu lẹta ti ẹ kọ si mi.
Ati pe gbogbo awọn awawi yin lori ilana ati ihuwasi ọmọ ẹgbẹ ko ni itumọ kankan.
- Mó ṣèlérí láti buwọ́lu àtúntò Naijiria, Ilé Aṣòfin o kù sí ọwọ́ yín - Ààrẹ́ Buhari
- Èèyàn kan ti kú, 99 di àwátì lẹ́yìn tí ilé alájà méjìlá wó lulẹ̀ l'óru
- Ẹ wo ọ̀nà àbáyọ tí adigunjalè bá kọ lẹ́tà sí yín pé àwọn fẹ́ ẹ́ wá jà yín lólè
- Olofa Ina tọrọ àforíjìn lọ̀wọ̀ àwọn òṣèré tíátà obìrin lórí ọ̀rọ̀ tó sọ níbi ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- Ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò oògùn olóró yóò di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbé'yàwò láìpẹ́- Buba Marwa NDLEA
- NDLEA mú dókítà àti sọ́jà lórí ẹ̀sùn títà egbòogi olóró
Mo fẹ sọ fun yin pe fiimu naa yoo pada jade laipẹ ti akoko ba ti to.
Mo si maa ba awọn agbaagba ẹgbẹ TAMPAN kan sọrọ ki n to gbe igbesẹ to kan,'' Yomi lo ṣalaye bẹẹ.
















