Kaduna Emir kidnapped: Alhaji Alhassan Adamu, Emir tí wọ́n jígbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Kajuru Emirate
Ni yajoyajo ni iroyin naa tẹ wa lọwọ pe Emir ti Kajure ni ijọba ibilẹ Kajure ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbepawo.
Ni ile rẹ ni wọn ti jii gbe lọjọ Ẹti lopin ọsẹ to kọja lọ ni ilu Kaduna.
Ọmọ rẹ toun naa jẹ oloye ni ijọba Kajuru fi aridaju iroyin pe wọn ti tu baba oun silẹ han fun BBC.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, wn kan joko si ile lọsan ni wọn ṣaadede rii ti Ọba naa wọle de.
Ẹwẹ, o fi kun un wipe wọn ko tii tu awọn mẹtala to ku ti wọn jọ ji wọn gbe pẹlu Emir naa silẹ.

Oríṣun àwòrán, @others
Àwọn tó jí Emir gbé ní Kaduna ti kọ́kọ́ kàn sí Mọ̀lẹ́bí- Emirate Kajure
Lanaa ọjọ Aiku ni awọn ajinigbe pawo ṣọṣẹ ni aafin Emir ti Kajure nijọba ibilé Kajure, nipinlẹ Kaduna.
Wọn wọle lọganjọ oru nibi ti wọn ti gbe awọn ayaba ati ọmọ ọmọ emir naa lọ.
Emirate Council to jẹ igbimọ lọbalọba Kajure ti fidiẹ mulẹ fun BBC pe awọn ko tii mọ iye owo itanran tabi ohunkohun ti awọn ajinigbe naa fẹ gba bayii.
- Ẹ̀dà àrùn Coronavirus gbẹ̀mí-gbẹ̀mí tuntun ti wọ ìpínlẹ̀ Oyo
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- A ti gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè agbẹjọ́rò tó dántọ́ kí Kanu lè rí ìdájọ́ òdodo gbà - Ohaneze Ndigbo
- COVID-19 variant tó wà ní Nàìjíríà tún yàtọ̀ sí ti UK - NCDC
- Àwọn tó jí emir gbé ní Kaduna ti kàn sí Mọ̀lẹ́bí- Emirate Kajure
- Kí gbogbo ilé ìjọsìn Eko padà sí ìlàjì iye ènìyàn tó lè wa jọ́sìn- Sanwo Olu
Sugbọn mọlẹbi Alhaji Alhassan Adamu to jẹ Emir Kajure ti sọ fun BBC Hausa pe awọn ajinigbe naa ti fi foonu emir pe.
Won si sọ fun mọlẹbi pe alaafia ni awọn emir ati gbogbo awọn ti wọn ji gbe wa.
Ẹni mẹ́wàá ni wọ́n jí gbé pẹ̀lú Emir Kajuru, Alhaji Alhassan Adamu
Àwọn agbébọn ti jí Emir, àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ gbé ní Kaduna.

Oríṣun àwòrán, @EmirateKajuru
Awọn agbebọn kan ti ji Emir ilu Kajuri, Alhaji Alhassan Adamu atawọn iyawo rẹ gbe lọ ni ipinlẹ Kaduna.
Iroyin sọ pe Emir naa atawọn eeyan mẹtala ninu ẹbi rẹ ni awọn agbebọn ọhun ji gbe lọ lorumọju.
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Port Harcourt mú ẹ̀mí ènìyàn 5 lọ
- Ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kò rọrùn rárá ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mó di ayaba- Jaye Kuti
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
Iroyin naa ni nkan bii aago mejila orumọju oni ọjọ Aiku ni awọn agbebọna naa ya wọ aafin Emir Kajure.
Bi iroyin kan se ni pe ẹni mejila ni wọn jigbe ni awọn agbofinro ti ni mẹwaa ni wọn le fidi ẹ mulẹ.
Ọkunrin kan ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede ṣalaye fun BBC pe ori ade naa, awọn iyawo rẹ mẹta, awọn ọmọ-ọmọ rẹ meji, awọn oṣiṣẹ rẹ mẹta to fi mọ awọn eeyan marun un miran ni wọn gbe lọ.
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- Ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi kò rọrùn rárá ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ mó di ayaba- Jaye Kuti
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Port Harcourt mú ẹ̀mí ènìyàn 5 lọ
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ko tii fidi ijinigbe naa mulẹ, iroyin ni Emir ọhun ṣe ipade pẹlu awọn eeyan kan lori oniruru ijinigbe to n waye lagbegbe ọhun lọjọ Ẹti.
A ṣi n ko iroyin yii jọ lọwọ, a o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun yin laipẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ni ninu ile Alhaji Alhassan Adamu ni wọn ti jii gbe.
Ijoba ibile Kajuru ni ipinlẹ Kaduna ni iṣẹlẹ yii ti sẹlẹ.
Awọn eniyan ni pe ko tii pe wakati mẹrinlelogun ti Emir naa pe ipade eto aabo ni ẹkun rẹ ni ijinigbe naa ṣelẹ bayii ni Kaduna.















