Ahmed Musa: Balogun Super Eagles ti fẹ́ ẹ̀lẹ̀ kan ní aya kẹta

Ahmed Musa ati Iyawo tuntun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Bi wọn ṣe n ṣe nile ibi kan, ewọ ibomii ni, eyi lo difa fun oriṣiriṣi ero awọn eniyan lori bi Balogun ikọ Super Eagles, Ahmed Musa ṣe gbe iyawo kẹta bayii.

Lopin ọsẹ to kogba wọle lọ yii naa ni Ahmed Musa so yigi pẹlu ololufẹ rẹ.

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn yii ni iroyin taa gbọ sọ pe o ṣe igbeyawo naa ni bonkẹlẹ lọjọ Satide to kọja.

Lọdun 2017 ni igbeyawo to ṣe pẹlu iyawo akọfẹ rẹ tuka.

Lẹyin eyi lo pinu to tun fẹ Juliet, iyawo mii lọdun 2017 kan naa ti wọn si ti jọ n gbe pọ gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo latigba naa titi di asiko yii.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

Mariam to ṣẹṣẹ fẹ yii ni yoo jẹ iyawo ile keji niwọn igba ti iyawo akọfẹ ti lọ.

Bakan naa ni ọpọ iroyin n kọ ọ pe laarin ọdun mẹsan lo fi ṣe awọn fifẹ ati kikọ iyawo mẹtẹẹta naa.

Ẹwẹ, agbabọọlu naa ṣẹṣẹ tọwọ bọwe adehun ọnigba ranpẹ ni pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Kano Pillars ni Naijiria.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Rilwan Malikawa fi sita lọjọ Ẹti, Musa ṣẹ tọwọ bọwe adehun naa lỌjọbọ ni nipinlẹ Kano leyi to ni oun wa ni ẹgbẹ naa lati ko ipa niwọnba ti oun ba le ko.

Ọdun mẹwaa sẹyin ni Musa ni oun fi ẹgbẹ Pillars silẹ lai bori ninu liigi amọ o ni lagbara Ọlọrun, oun yoo ṣe ohun to laami laaka nipa didari ẹgbẹ naa lọtẹ yii.