Information blackout: Àwọn aṣòfin yọwọ́ nínú àbádòfin tí yóò fòfin de àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn àwọn ilésẹẹ́ ìròyìn

Lẹyin ọjọ méji ti awọn oniwe iroyin Naijiria ṣe ifẹhonuhan lori abadofin ti wọn ni yoo fofin de awọn akọroyin ni Naijiria, awọn aṣofin ti yọwọ lori abadofin naa.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin ifẹhonuhan ti awọn ileeṣẹ iroyin kan ṣe kaakiri Naijiria, paapaa niwaju awọn iwe iroyin to lamilaaka Mi ò lè fọwọ́ sí àbádòfin kankan tí yóò fòfin de iṣẹ́ akọ̀ròyìn- Femi Gbajabiamila
Awọn oniwe iroyin naa sọ pe ifẹhonuhan wọn da lori igbesẹ lati ma jẹ ki ijọba maa fofin de awọn lọna ti ko tọ, eyii ti ko ni jẹ ki wọn le ṣiṣẹ wọn bo ti tọ ati bo ṣe yẹ.
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
- Ààrẹ Buhari ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn sẹ́nétọ̀ 109 lálẹ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá
- Irọ́ ni o! Awujale ilẹ̀ Ijebu kò wàjà, ẹ sinmi ariwo
- Mi ò lè fọwọ́ sí àbádòfin kankan tí yóò fòfin de iṣẹ́ akọ̀ròyìn- Femi Gbajabiamila
Ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu Keje ọdun yii ni awọn iwe iroyin naa bẹrẹ si ni ṣe ifẹhonuhan ọhun niwaju awọn iroyin wọn pẹlu akọle "Information Blackout."
Wọn n sọ pe abadofin naa kii ṣe ọna lati fofin de awọn akọroyin nikan, ṣugbọn o tun jẹ ọna lati maa ṣakoso irufẹ iroyin ti awọn eeyan yoo maa ni anfani lati gbọ.
Lara awọn iwe iroyin to kopa ninu ifẹhonuhan ọhun ni Punch, Vanguard ati Guardian wa.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Mi ò lè fọwọ́ sí àbádòfin kankan tí yóò fòfin de iṣẹ́ akọ̀ròyìn- Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, BBC hausa
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ti sọ pe oun ko ni lọwọ si abadofin kan to n gbero lati fofin de awọn akọroyin lẹnu iṣẹ wọn.
Gbajabiamila sọ pe irufẹ abadofin bẹẹ ko le di ofin labẹ iṣakoso oun ninu ile naa.
Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn to ni iwe iroyin, NPAN, ẹgbẹ awọn ọga agba nidii iṣẹ iroyin, NGE to fi mọ ẹgbẹ awọn akọroyin ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan.
Won ṣe e niwaju awọn iwe iroyin kan lodi si abadofin kan ti yoo maa ṣakoso iṣẹ wọn, eyii to kede owo itanra nnkan bii miliọnu marun un naira fun awọn to ba tapa si ofin naa.
- Irọ́ ni o! Awujale ilẹ̀ Ijebu kò wàjà, ẹ sinmi ariwo
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Wọ́n ti yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún Baba Ijesha ní Ireland kúrò lórí ayélujára
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń gbé lẹ̀yìn tí wọ́n rí ẹ̀dà Covid-19 "Delta variant" tuntun níbẹ̀
- Gbogbo owó àjẹmọ́nú ti mo ti gbà láti 2017 ni màá dá padà fún ìjọba- Ìyàwó aarẹ Ghana
- Èèyàn 2,371 ni wọ́n jí gbé, N10biliọnu owó ìtúsílẹ̀ làwọn ajínigbé gbà lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021
Lara awọn iwe iroyin ni Najiiria to lamilaaka to kopa ninu ifẹhonuhan naa niwaju iwe iroyin wọn ni Punch, Vanguard ati Guardian wa.

Oríṣun àwòrán, vanguard
Gẹgẹ bi ohun ti gbajabiamila sọ, awọn yoo ṣe atunṣe awọn abala to n da wahala silẹ ninu abadofin naa, tabi ki wọn yọ abala naa kuro patapata.
Gbajabiamila lo fi ọrọ naa lede lasiko to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Abuja.
O ni oun ti ba ẹni to ṣagbatẹru abadofin naa sọrọ, ati pe oun ti ni ki wọn fi ẹda rẹ ṣọwọ si oun fun ayẹwo.
Agbẹnusọ ile naa ni "Emi ko ni wa lara awọn eeyan ti yo ṣofin ti yoo fofi de awọn akọroyin."
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀
- Ìròyìn ayọ̀! Emir tí wọ́n jígbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀, báwó ló ṣe ṣeé láàrin ọ́jọ́ méjì?
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
O ni ko yẹ ko si abadofin kankan ti yoo wa siwaju ile, eyii ti afojusun rẹ yoo jẹ lati tẹ ẹtọ awọn akọroyin loju mọlẹ lẹnu iṣẹ wọn.
Gbajabiamila pari ọrọ rẹ pe iyatọ wa laarin abadofin ti yoo fofin de awọn akọroyin ati eyii ti yoo maa ṣakoso iṣẹ wọn.
Lẹyin naa lo ni "Emi gẹgẹ bii agbẹnusọ ile ko ni gbe ofin kankan kalẹ ti yoo fofin de awọn akọroyin.
Ki lo ti ṣẹlẹ?
Àwọn ìwé ìròyìn yarí lórí àtúnṣe tí ilé aṣòfin ń ṣe lórí òfin tó de iṣẹ́ akọ̀ròyìn

Awọn ọmọ Naijiria ṣadeedee ji lọjọ kejila oṣu keje ọdun 2021 ri akori iroyin kan naa lori awọn iwe iroyin.
Ki kuku ṣe aṣiṣe, ohun ti ajọ to n ri si ọrọ iwe iroyin ni Naijiria, Press Organisation [NPO] ti pinnu lati ṣe ni.
Ajọ NPO pe e ni ''Information Blackout'' ti o tumọ si ''aisi iroyin'' lati tako ohun ti wọn sọ pe ijọba n gbero lati ominira ati sọrọ awọn akọroyin ti ijọba fẹ tẹ mẹrẹ.
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- Mo fẹ́ kí a dá Yorùbá Nations sílẹ̀ kí a lè máa mójútó àwọn adarí tó bá kọsẹ́ fúnra wa- Peter Fatomilola
- Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Gbogbo ìgbà ni Ooni Ogunwusi tí Ile Ife máa ń sọ̀rọ̀ Wolii TB Joshua pé....Olori Naomi Silekunola
Awọn gbajugbaja iwe iroyin bii Punch, Vanguard ati Guardian lo kọ ninu iwe iroyin pe ohun ti ijọba fẹ ṣe niyii pẹlu atunṣe ofin NPC ati NBC ni lati tẹ ẹtọ awọn akọroyin.
Ẹgbẹ awọn to ni iwe iroyin, NPAN sọ pe ohun ti ijọba fẹ ṣe pẹlu atunṣe ofin yii lati maa fun awọn akọroyin ni faini N.25m nigba tawọn ileeṣẹ iroyin yoo maa san san faini N5m.
NPAN ni awọn akoroyin tiẹ le ri ẹwọn bi ọdun mẹta he.

Ẹgbẹ NPAN ni ifẹhonuhan awọn ileeṣẹ iwe iroyin yoo tẹsiwaju lọjọ kẹtala oṣu keje.
Ẹgbẹ naa ni lọjọ kẹrinla oṣu keje lawọn iwe iroyin yoo ṣalaye ni kikun idi ti wọn fi tako atunṣe ofin NPC ati NBC naa.
Igbimọ NPO ni ijọba fẹ maa ṣe itọpinpin ohun tawọn iwe iroyin n gbe sita ni wọn fi fẹ ṣe atunṣe ofin to wa nilẹ ọhun.














