Baba Ijesha: Ta ló yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún afurasí Olanrewaju Omiyinka kúrò lórí ayélujára?

Baba Ijesha nile ẹjọ

Wọn ti yọ oju opo GoFundMe ti ẹnikan ṣi fun Baba Ijesha lati ba kowojọ lori igbẹjọ ifipa ba ọmọde lopọ kuro lori ayelujara.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le sọ ni pato boya ọgbẹni Oladele Matti to ṣi oju opo naa lo yọ ni tabi ileeṣẹ GoFundMe funra rẹ.

Ṣugbọn iroyin sọ pe igbeṣe naa waye lẹyin ti awọn eeyan kan bẹrẹ si n ṣe ifẹhonuhan lori ayelujara lẹyin ti Matti ṣi oju opo naa tan.

Ṣaaju ni ni wọn ti kọkọ fẹsun kan Baba Ijesha pe o ba ọmọde ni ibalopọ lọna ti ko tọ, eyii to lodi si abala ofin 135, 137, 261, 202, 262 ati 263 to rọ mọ ibalopọ ni ipinlẹ Eko.

Asiko ti igbẹjọ naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn ololufẹ rẹ to fi orilẹ-ede Ireland ṣebugbe, Oladele Matti ṣi oju opo GoFundMe fun Baba Ijesha pẹlu erongba lati ko €50,000 jọ ko le fi ṣe ẹjọ ọhun.

Baba Ijesha

Nigba to n sọrọ lori idi to fi gbe igbeṣe naa, Matti ni "Mo n ṣe ikowojọ yii lati ran Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha lọwọ lori igbejọ rẹ."

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams

"Afojusun mi ni ki Baba Ijesha le ri idajọ ododo gba lori ẹsun ti wọn fi kan an."

Ẹwẹ, igbesẹ naa ko dun mọ awọn kan ninu, ti wọn si woye eredi ti ẹnikan yoo fi gbiyanju lati ko owo jọ fun ẹni ti wọn fi ẹsun biba ọmọde lopọ kan.

Lasiko ti BBC Yoruba ṣe abẹwo si oju opo naa, a ri wi pe ko si nibẹ mọ pẹlu akọle pe "A ko ri oju opo yi ṣi mọ."

Gofundme

Oríṣun àwòrán, Gofundme

Ileeṣẹ GoFundMe jẹ ileeṣẹ kan to n fun awọn eeyan lanfani kaakiri agbaye lati ṣe ikowojọ fun eredi kan tabi omiran.

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'