Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin ayọ fawọn ọmọ Naijiria to fẹ lọ ṣiṣẹ aje tabi gbe loke okun.
Awọn ọdọ to ba ni owo kan tabi omiran lati ṣe ti wọn si ṣetan lati fi ilu wọn silẹ lọ orilẹede Italy yoo jẹ ẹbun owo tabua.
Ẹkun Calabria lorilẹede Italy ti ṣeleri lati fun ẹnikẹni to ṣetan lati maa gbe abule naa ni owo to le ni miliọnu mẹtala ati aabọ, N13.6m( ($33,000) laarin ọdun mẹta.
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Oluwo àti Oba Kuta nìkan ló tíì jáde lòdì sí Oduduwa Republic, àwọn Ọba tó pọ̀ wà lẹ́yìn wa lábẹ́nú- Iba Gani Adams
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- Bí a ṣe gbé agbára àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Wòlíì mi TB Joshua lé mi lọ́wọ́ látọrun wá - Prophet Moses Olawale
- Àbúrò mi TB Joshua ló ń darí gbogbo ayé wa bó tilẹ̀ jẹ́ àbúrò kẹta si mi - Àkọ́bí ìdílé TB Joshua
- 'Ẹ wòó, ẹ máa retí ìdájọ́ àwọn olùwọ́de Yoruba Nation 49 tó wà láhàmọ́ Ọlọ́pàá ní ọjọ́ ...'
Abule Calabria wa ni bebe okun, awọn eeyan ilu naa ko si ju ẹgbẹrun meji lọ.
Pipe awọn eeyan lati wa maa gbe nibẹ jẹ ọkan lara ọna ti ijọba Italy fẹ gba lati jẹ ki eeyan to wa ni ilu naa gberu sii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kansilọ ẹkun kan ni Italy, Gianluca Gallo sọ fun CNN pe awọn eeyan to ba ṣetan lati wa maa gbe ilu naa yoo maa gba owo oṣu to to 800-1,000 owo Euro.
O ṣalaye pe wọn yoo gba owo yii fun bi ọdun mẹta tabi ki wọn gba owo naa lati fi da okowo kan tabi ile ọunjẹ tabi oko silẹ.
Amọ, N13.6 million ($33,000) ti wọn fẹ fun awọn eeyan kii ṣe ọfẹ lo ba de o.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ọna ti o le fi di ẹni amuyẹ fun anfaani yii.
O gbọdọ ṣetan lati bẹrẹ okowo tabi lati ṣiṣẹ nibẹ gẹgẹ bi akọsẹmọṣẹ.
Iru awọn akọṣẹmọṣẹ ti wọn n wa niluu naa ni iwọnyii:
- O gbọdọ ṣetan lati maa gbe ilu naa.
- Ẹnikẹni to ba fẹ maa gbe ilu naa ko gbọdọ ju ogoji ọdun lọ.
- O gbọdọ ṣetan lati fi ilu rẹ silẹ lọ si Calabria laarin oṣu mẹta si igba ti o ba fi orukọ silẹ lati gba iwe igbelu Calabria.












