Ghana first lady: Rebecca Akufo-Addo dá Ghc899,000 owó àjẹmọ́nú ti ó ti gbà láti 2017 padà fún ìjọba

Oríṣun àwòrán, Office of the 1st lady and 2nd lady
Aya Aarẹ Nana Akufo Addo, Rebecca Akofo- Addo ti da owo to gba gẹgẹ bii owo ajẹmọnu lati ọdun 2017 pada sapo ijọba ilẹ Ghana.
Arabinrin Rebecca seleri lati da owo naa pada lẹyin ti awọn ara ilu ṣe iwọde.
Iwe sọwedowo banki Consolidated Bank Ghana Limited ni Rebecca fi kọ iye owo naa to da pada si asunwon ijọba.
- Gbẹgẹdẹ gbiná, ṣọ́jà àtàwọn jàǹdùkú fìjà pẹẹ́ta lọ́jà Ladipo l'Eko
- Mr. Portable sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Mr. Latin lórí gbas-gbos tó ń wáyé lágbo òṣèré tíátà Yoruba
- Omiyalé ní Ghana, èèyàn 28 dolóògbé!
- Saraki pe fun ajọṣepọ Ghana ati Naijiria
- Ààrẹ Akufo-Addo la Mahama mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ Ghana fún sáà kejì
- Wọn le awọn olutaja kuro niwaju ile Aarẹ Ghana
- Buhari fẹ ran Ghana lọwọ lori iwa ibajẹ
- Nàìjíríà àti Ghana léwájú nínú wíwá òògun ìsẹ́yún
O da Ghc899,000 to jẹ gbogbo owọ to ti gba gẹgẹ bii ajẹmọnu lati ọdun 2017 ti ọkọ rẹ ti dori aleefa.
Ninu lẹta to kọ ranṣẹ si adari awọn oṣiṣẹ, eyi ti arabinrin Shirley Laryea buwọlu lo ti salaye pe eyi jẹ owo ti aya aarẹ gab lati ọjọ keje, oṣu kinni, ọdun 2017 titi di isinyi.

Oríṣun àwòrán, Screenshort
Kete leyin ti Rebecca aya aarẹ Nana Akufo-Addo gbe igbesẹ yii naa ni Lady Samira Bawumia to jẹ aya igbakeji aarẹ naa gbe igbesẹ kan naa pe owo ti oun ti gba lati 2017 ti di dida pada ni Ghana.

Gbogbo owó àjẹmọ́nú ti mo ti gbà láti 2017 ni màá dá padà fún ìjọba- Ìyàwó aarẹ Ghana
Iyawo aarẹ lorilẹede Ghana, Rebecca Akufo-Addo ti ṣeleri lati da gbogbo owo ajẹmọnu ti oun ti gba lati ọdun 2017 ti ọkọ rẹ ti jẹ aarẹ pada fun ilu.
Eyi ko ṣẹyin igbe ti awọn eniyan n ke lori owo gọbọi ti awọn oloṣẹlu n gba gẹgẹ bi owo oṣu.
Rebecca Akufo-Addo tun sọ wi pe oun ko ni gba owo oṣu ti Ile Igbimọ Aṣofin ṣẹṣẹ buwọlu fun oun.
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń gbé lẹ̀yìn tí wọ́n rí ẹ̀dà Covid-19 "Delta variant" tuntun níbẹ̀
- Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí Sẹ́nétọ̀ Adelere Oriolowo, APC tó fi opó ẹ̀rọ ayélujára Airtel ṣe iṣẹ́ àkànṣe ìlú ní Osun
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Ìròyìn ayọ̀! Emir tí wọ́n jígbé ní Kaduna gba ìtúsílẹ̀, báwó ló ṣe ṣeé láàrin ọ́jọ́ méjì?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde òní ọjọ́ Ajé gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi nítorí ikú ìgbákejì gómìnà Bantex tó dolóògbé
- A ti gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè agbẹjọ́rò tó dántọ́ kí Kanu lè rí ìdájọ́ òdodo gbà - Ohaneze Ndigbo
Rebecca ni pe oun yoo da gbogbo owo ti oun ti gba gẹgẹ bi ajẹmọnu pada, eleyii to to 899,097.84 ni iye owo ilẹ Ghana cedis ($151,618; £109,111).
''Mi o bere owo yii lọwọ ara ilu amọ oun ti wọn fun mi gẹgẹ bi ajẹmọnu ni awọn owo yii ti mọ fẹ da pada. ''
''Mo fẹ da pada nitori nkan ti awọn eniyan n sọ nipa mi pe mi o ni ifẹ awọn araalu, ti ipenija wọn ko si jomiloju, amọ ko si ohun to jọ bẹẹ.''
- Àkójọpọ̀ àwòrán láti àpéjẹ ìdúpẹ́ Aisha Buhari
- Ìròyìn nípa ìyàwó túntún fún ọkọ mi kò mì mí lọ́kàn rárá-Aisha Buhari
- Ẹ yéé purọ́ kiri! Ìdí rèé tí Aisha Buhari kò tíì padà sí Nàìjíríà- Iléeṣẹ́ ààrẹ
- Bí mo ṣe mórí bọ́ nínú ọkọ̀ bàálù tí kò bá já - Aisha Buhari
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Aisha Buhari ké gbàjare pé ètò ìjọba Buhari kò ṣànfàní f'óbìrin
Oṣu to kọ̣ja ni awọn araalu faraya lẹyin ti awọn aṣofin buwọlu lati ma a san owo oṣu fun iyawo aarẹ ati iyawo igbakeji aarẹ fun ipa ti wọn n ko lati gbaruku ti ijọba.

Oríṣun àwòrán, Facebook
Owo ti wọn yoo ma gba yoo ṣe deede pẹlu owo ti awọn aṣofin n gba lati ọdun 2019 ti wọn ti buwọlu.
Ko to di asiko yii ni awọn iyawo aarẹ ati iyawo igbakeji aarẹ ti ma n gba owo ajẹmọnu lati ọwọ ijọba.
- Ta ni yóò borí láàrin Aisha Buhari àti ọkọ rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ‘First Lady’?
- Aisha Buhari, ohun mẹ́fà tò fi yàtọ̀ sí àwọn aya ààrẹ tó ti jẹ kọjá!
- Taló ya fídíò ibi tí Aisha Buhari ti ń bínú ní Aso Rock?
- Mo ti gba pé ológun ni ọkọ mí- Aisha Buhari
- Buhari kò láànú ọmọ Nàìjíríà lójú - Aisha Yesufu
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo















