LGBT+ gay men arrested: Ọkùnrin márùn-ún tó jọ ń ṣe kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam

Onibalopọ akọsakọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọlọpaa ẹsin Islam ni ipinl Kano ti fi panpẹ ofin mu ọkunrin marun kan ti wọn fi ẹsun kan pe wọn n ni ibalopọ akọsakọ.

Ẹgbẹ ọlọpaa ẹsin Islam ni awọn mu awọn ti wọn furasi naa pe wọn n ba ara wọn lopọ lasiko ti wọn n ṣiṣẹ dọdẹ kiri ni ibi ipamọ kan to wa ni agbegbe Kumbotso lẹyin ti awọn araalu ibẹ fi ẹjọ sun.

Ipinlẹ Kano jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ ẹkun Ariwa Naijiria to n lo ofin Islam tabi Sharia papọ mọ ti orilẹede Naijiria.

Ninu ofin mejeji, ibalopọ akọsakọ tabi abosabo lodi si ofin.

Awọn alaṣẹ ni afurasi ni awọn ọkunrin naa pe awọn si n ṣe iwadii lọwọ. Bi wọn ba rii pe wọn jẹbi, wọn lee fi ẹwọn to to ọdun mẹrinla jura ni ilana ofin ilẹ Naijiria.

Ọfiisi awọn onibalopọ ẹ̀dà kan náà ní Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni Naijiria, igbesẹ akin lo wade lati fi panpẹ ofin mu awọn to ba n ni ibalopọ ẹ̀dà kan náà eyi ti wọn n pe wọn lawọn orilẹede mii ni LGBT.

Lọdun 2014 ni ijọba tun gbe ofin kan jade ti wọn kede rẹ pe bi obinrin ba n ba ara wọn lopọ tabi ọkunrin lo n ṣe iru ẹ, iwa ọdaran ati arufin gidi ni.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Latari eyi, ninu oṣu kẹjọ ọdun 2018, awọn ọlọpaa orilẹede Naijiria mu ọkunrin mẹtadinlọgọta ti wọn jẹ afurasi onibalopọ akọsakọ amọ wọn pada tu wọn silẹ pẹlu beeli.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb