Husband rapes wife: Angẹ́lì ni ọkọ mi, ó sì fipá bá mi lòpọ̀ títí oyún fi bàjẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lalẹ ọjọ igbeyawo rẹ ni ọkọ Safaa to jẹ ẹni ọdun merinlelogbon fipa baa lopo. Èyí si ti jẹ ko farapa laarin ibi itan rẹ sí ikùn, ọrun ọwọ ati ni ẹnu - Ẹ o máa woye pe kayefi leleyii, bawo ni iyawo ṣe n sọ pe ọkọ fipa ba oun lo pọ?
Laipẹ yìí, awọn obinrin lorileede Egypt ti bẹrẹ sí ní la ohun ti wọn ni figbe sita lori oniruuru iwa fifi ipa Ibalopọ fiya jẹ ni eyi tó sì wọpọ laipẹ yii ni ija lati lodi si ifipabanilopo ninu igbeyawo lohun to jẹ eewọ tẹlẹ.
Safaa ni "mo n ṣe nkan oṣu lọwọ ni mi o si ṣetan rara lati ni Ibalopọ lalẹ ọjọ naa, ọkọ mi ro pe mo ni mo n sa fún nini ibaṣepọ to dánmọrán pẹlu oun ni. O ba bẹrẹ si ni lu mi, o kọ ẹwọn irin (Handcuff) si mi lọwọ, o di mi ni ohun ọrọ o si fipa ba mi lopọ".
Amọ Safaa ko lati fi to olopaa leti torí ìbẹrù oju ti awọn ara àdúgbò yóò máa fi woo eyi to wọpọ niluu wọn paapaa bí ẹni naa ba jẹ obinrin.
O yi biri! Ayipada de ninu oṣu kẹrin nigba ti eto ori ẹrọ amohunmaworan kan tó n jẹ Newton's Cradle eyi ti wọn ṣafihan rẹ lasiko aawe Ramadan ti awọn Musulumi ninu eto naa ti ọkọ n mu iyawo rẹ ni tipa tipa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun ọpọ obìnrin, abala eto naa mu iranti buruku wà fún wọn amọ o tun wà fún wọn ni igboya lati bọ sori ayelujara máa sọ iriri wọn ni gbangba.
Laarin ọsẹ melo kan, onírúurú ẹrí lo ti hande koda to fi mọ ojú òpó eedegberin lori Facebook to ṣẹṣẹ dide ti won n pe ni "Speak Up".
Lara wọn ni ẹni ọdun metadinlogun, Sanaa.
"Angẹli ni ọkọ mi. Laarin ọdún kan taa ṣẹṣẹ gbeyawo, mo loyun mo sì ti fẹẹ bímọ, o kọ eyi loju opo naa. "Ija de saarin wa lori ọrọ yẹpẹrẹ kan lo ba pinu lati fiya jẹ mi.
O fi ipa gun le mi lori o si fipa ba mi lopọ. Bi oyun ara mi ṣe bajẹ nìyẹn".
- Cubana Chief Priest ra màálù 46 fún ìsìnkú ìyá ọ̀gá rẹ̀, àwọn ọmọ Naijiria ń fi èrò wọn hàn
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìwọ́de tí apá ọlapáà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ọdẹ tó tẹ Ẹ̀pẹ́ dó láti ìgbà ìwásẹ̀?
- 'Restructuring' la fi ta Buhari fún ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n ó dùn mi pé irọ́ ni Buhari pa- Olagunsoye Oyinlola
- Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Wo bí o ṣe le fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tàbí gba ọ̀rọ̀ lórí WhatsApp láì lo fóònù rẹ
Saara gbee sinu, o dá ija naa já lati jáwé ituka igbeyawo o si ti kọ ọkọ rẹ silẹ báyìí amọ o si n ṣe ọfò ọmọ to padanu.
Ibalopọ tipa tipa wọpọ kaakiri ilẹ Egypti paapaa lalẹ ọjọ igbeyawo.
Itakuroso lori iwa ipa yìí ru soke síi to si gbóná janjan nigba ti iyawo tẹlẹ gbajugbaja Olorin kan bọ soju opo Instagram lati so ohun tójú rẹ rí bi ọkọ rẹ ṣe n fipa baa lopọ. Pẹlu omije loju, fidio to ṣe tan kálẹ̀ tó sì n bi ọpọlọpọ akọle fún àwọn oniroyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bó tilẹ jẹ pé ọkọ rẹ ni irọ ni ọrọ naa ninu fidio ti oun naa fi sita, arabinrin naa pe fún ayipada ofin ko lee pe iwa yii ni iwa odaran.
Ninu ọpọlọpọ atẹjade ìwádìí, àjọ to n rí si ọrọ awọn obinrin fi sita pe o le ni ẹgbẹta abọ obinrin lọdọọdun tó n kojú iwa ipa ninu Igbeyawo.
"Ifipabanilopo ninu igbeyawo nibi, wọn máa n dáa lori aṣa kan ni Egypti pe adehun igbeyawo pàṣẹ pé obìnrin gbudọ gbe ara rẹ fún okunrin fún gbogbo wakati merinlelogun to wa lojo kan". Reda Danbouki to jẹ agbejoro lo sọ bẹẹ.
Wọn gbagbọ koda ninu awọn ẹsìn kan pé obìnrin tó bá kọ, o ti di ẹlẹsẹ awọn angẹli yóò sì máa ṣepe fún ùn ni gbogbo ale ọjọ naa. O fi kun un.
Lati yanju eyi, ṣe láwọn olugbani nimoran esin Islam náà ba da sii pe "okunrin to ba ti fipa mu iyawo rẹ lati baa lopọ ti di ẹlẹsẹ labẹ ofin iyawo sí ní àṣẹ lati lọ sí ile ẹjọ".
Sibẹ sibẹ, ofin orilẹede Egypti ko pẹ ifipabanilopo ninu igbeyawo ni iwa odaran lohun tí àjọ eleto ilera agbaye WHO atawon ile ẹjọ náà ríi pé o nira lati mú aridaju jade.
Ọpọ nínú àwọn ẹjọ ifipabanilopo ninu igbeyawo to lọ ilé ẹjọ ni kii ni eredi ati da ebi ru èèyàn kan.
Amọ, Ọgbẹni Danbouki ni o ṣeeṣe nipa ṣíṣe ayẹwo gbogbo ara obirin naa lati wa ibi ìpalára tabi egbo ita ara. Egbo lagbegbe ẹnu ati ni orun ọwọ".
Wọn máa n dakẹ tabi jee mọlẹ ni ni Egypti amo fún àwọn tí wọn ni fipa ba lopo ninu igbeyawo, won ti bẹrẹ sí ní pariwo sita bayii.
A ṣe ayipada oruko le fi ri Safaa ati Sanaa, kii ṣe orúkọ àwọn to sẹlẹ sí gangan lati lee dáàbò bo idanimọ wọn ni















