Ọmọ Naijiria 350 ló dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni aadọta le lọọdunrun eeyan to ba omi lọ lẹyin ijamba ọkọ oju omi ni Naijiria lọdun 2020.
Alaga ileeṣẹ to n ri si idagbasoke awọn agbegbe ti wọn ti n pese ina ijọba, HYPPADEC, Joseph Ityav, lo fi ọrọ naa lede ni ipinlẹ Niger.
Ityav lo sọ ọrọ naa niluu Malale, ni ijọba ibilẹ Borgu lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ gige awọn igi to wo sinu odo Kainji ati Shiroro.
- Ìgbìmọ̀ olùwádíì ìpínlẹ̀ Eko tẹ́wọ́ gba èsì àyẹ̀wò "Autopsy" òkú 99 tí wọ́n rí he lásìkò ìwọ́de EndSARS
- Ìwà àbùkù tí kò bá ojú mu ni Yomi Fabiyi àti Dele Matti hù pẹ̀lú eré Ọkọ Iyabọ- TAMPAN
- 'Ìròyìn òfegè ni! Olóyè Sunday Igboho kò ṣàbẹ̀wò sí Ọba Oluwo'
- 'Ọkọ̀ ojúomi Noah kò gbádùn tó, làwọn ẹ̀ṣọ́ orí omi fi dèé mọ́lẹ̀ ní Ipswich''
- Bobrisky fi àwòrán tuntun léde lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
O ni wọn n ṣe akanṣẹ iṣẹ naa pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ omi ni Naijiria.
Ityav sọ pe awọn ijamba naa n waye nitori ipo ti ọpọ ọkọ oju omi wa ni Naijiria, bi wọn ṣe maa n ko ero akoju to fi mọ awọn igi to wo sinu omi.
O ni ti wọn ba ti ko awọn igi to wa loju omi atawọn idọti naa tan, adinku yoo de ba iye ijamba to n waye ati iṣoro ti awọn olugbe agbegbe eti omi n doju kọ.
Lasiko to n sọrọ, adari agba ileeṣẹ HYPPADEC, Abubakar Yelwa ni ileeṣẹ ọhun yoo bojuto awọn iṣoro ati ifẹmiṣofo to waye lasiko ti wọn n ṣatunṣe adagun omi Kainji ati Shiroro.
Ọdun 1964 ni wọn kọ adagun omi Kainji pẹlu $209 miliọnu, ti wọn si ṣi lọdun 1968.
Nigba ti wọn kọ adagun omi Shiroro nipinlẹ Kaduna lọdun 1983.
- A ń gbóhùn àdúrà sókè ní orílẹ̀èdè 127 lágbàáyé torí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Baptist tí wọ́n jígbé ní Kaduna -Baptist Convention
- CAN faraya lórí ikọlù agbofinro sàwọn ajàfẹ́tọ̀ bí Sunday Igboho
- Buhari jọ̀ọ́ dárí jin Sunday Igboho, ohun tó ń ṣe kò ye ni - Oluwo
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ti dájọ́ fún Yomi Fabiyi àti igbákejì rẹ̀ lórí fíìmù Oko Iyabo
















