Ondo Bank robber, Olubunmi Afuye: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo àtàwọn ọ̀rẹ̀ ń ṣèdárò lẹ́yìn olóògbé

Oríṣun àwòrán, Oluwafunmi James
Lẹyin idigunjale to waye niluu Ilara-Mokin, nipinlẹ Ondo lọjọbọ, ọpọ eeyan kaakiri ipinlẹ Ondo lo ti bẹrẹ si ṣedaro akọroyin kan to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Akọroyin ọhun, to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Adaba FM, niluu Akure nigba kan ri, Olubunmi Afuye lo jade laye lẹyin to fara gbọta ibọn nibi iṣẹlẹ ọhun.
Lara awọn to n ṣedaro Afuyẹ ni Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimni Akeredolu, ẹgbẹ awọn akọroyin, NUJ, ẹka ti ipinlẹ Ondo, awọn akẹgbẹ rẹ lẹnu iṣẹ, awọn ẹbi rẹ, atawọn eeyan mii.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ gomina Akeredolu, Richard Olatunde buwọlu, o ni adanu nla ni iku oloogbe naa jẹ.
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa "food poisoning" àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀
- Ọmọ Yorùbá ni onímọ̀ ẹ̀rọ ‘Rọ́bọ́tì’ tó ń gbowó jùlọ ní UK
- Ìjókòó ilé aṣofin tòní dàrú, ìjà bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ fífi ẹ̀rọ ìgbàlódé gbé èsì ìbò jáde
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Bí ọkọ mi ṣe fi ẹ̀wọ̀n irin dè mí mọ́ bẹ́ẹ̀dí tó fipà bá mi lòpọ̀ títí oyún fi bàjẹ́ lára mi'
Aketi sọ pe "Afuye sun mọ wa gidi, a si gbadun bo ṣe maa n ṣiṣẹ rẹ ati bo ṣe maa n dari ayẹyẹ eyii ti a ti ni anfaani lati foju ganni lọpọ igba."
"Iku rẹ ko dun wa nikan, iku ọhun jẹ ohun ti a ko le mumọra."

Oríṣun àwòrán, Photo Afrique
Akeredolu tun ba gbogbo ẹbi oloogbe naa kẹdun, paapaa iyawo ati awọn ọmọ to fi silẹ saye lọ.
Ni ti ẹgbẹ awọn akọroyin, NUJ, ẹka ti ipinlẹ Ondo, wọn ni bi awọn adigunjale ṣe gẹ ẹmi oloogbe naa kuru jẹ ohun kan to ṣoro fun awọn lati ṣalaye.
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Leke Adegbite buwọlu, o ni wọn ba ẹbi rẹ kẹdun, paapaa iyawo rẹ atawọn ojugba rẹ niga rẹ nigba kan ri nileeṣẹ redio Adaba FM.
NUJ Ondo ni awọn yoo saaro ipa ribiribi ti Afuye n ko ninu ẹgbẹ naa nitori ẹkọ nla ni awọn ti kọ lara rẹ.
Lara awọn alabaṣiṣẹ rẹ nigba kan ri to tun n ṣedaro lẹyin Afuye ni Ojo Awogbemi, ti ọpọ mọ si Kabiesi.
Awogbemi sọ sọ pe oun ṣi ba oloogbe naa ṣorọ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye to si sọ pe oun yoo kan si oun, ṣugbọn iroyin iku rẹ ni oun gbọ lẹyin wakati marun un si asiko naa.
Bunmi Afuye ni alukoro fasiti Elizade to wa niluu Ilara-Mokin ki ọlọjọ to de.
Olubunmi Afuye: Ohun táa mọ̀ nípa akọ̀ròyìn tó kàgbákò ikú lọ́wọ́ Adigunjalè tó fọ́ Báńkì l'Ondo

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Iroyin to n t wa lọwọ sọ pe awọn agbebọn ti pa oniroyin kan ati eeyan meji mii ni banki ti wọn ti lọ ja ole lỌjọbọ ọjọ kẹẹdogun oṣu keje.
Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o ṣẹlẹ ni ilu Ilara Mokin, ijọba ibilẹ Ifedore.
Akọroyin naa ti orukọ rẹ n jẹ Olubunmi Afuye jẹ ẹni ti wọn ṣẹṣẹ gba siṣẹ gẹgẹ bii agbẹnusọ fun Fasiti Elizade.
- Ó kéré tán, ajínigbé ti pa èèyàn 222 láàrìn oṣù mẹ́ta ní Kaduna- Gomina El Rufai
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
- Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Aarẹ Muhammadu Buhari gúnlẹ̀ sí Kano láti fi ìpìlẹ̀ ojú ọna irin lélẹ̀
- Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin
- Awujale Ijebu Ode, Ọba Adetona wọ́gilé àjọ̀dún Ojude Oba tọdún yìí
Ki ni Olubunmi ba de ibi to ti kagbako iku ojiji ati ohun ti a mọ nipa rẹ?
Iroyin ni Olubunmi n lọ sibi iṣẹ rẹ ni lo ba ṣaadede ko sọwọ awọn adigunjale to n ko banki kan lọwọ lo ba fori la iku gbigbona.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ASP Tee-Leo Ikoro ti sọ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Oyewamide Ojo
Awọn iroyin kan tilẹ n sọ pe ọlọpaa ni awọn meji mii ọhun ti wọn pa amọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn yoo to fi atjade sita lori iṣẹlẹ ọhun.
A gbọ pe awọn adigunjale ọhun fọ ilẹkun ayẹta banki naa pẹlu awọn okuta dynamite ki wn to ri aaye wọle sinu ile.
Gẹg bi eeyan kan to ṣoju rẹ ṣe sọọ, ọlọkada kan ati oṣiṣ Fasiti Elizade n kọja lọ ni ọpọ ọta ibọn ba wọn.
- Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ ògbóǹtagì oníṣòwò òògùn olóró méje
- Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí èèyàn 265 ní ìpínlẹ̀ Ogun- TRACE
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
- Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin




















