Imo Police: Pàsítọ̀ tó ń dí ọkọ lọ́wọ́ láti máṣe gun aya rẹ̀ ní ọ̀bẹ, ló gún pa

Oríṣun àwòrán, Gordon Johnson
Yoruba bọ, wọn ni onlaja níí fara gbọgbẹ, ti apọnmilamu si maa n ri eegun nigba mii.
Bayii gan-an lọrọ ṣe rí fun pasitọ ijọ Redeem kan, Thompson Onyekwuru niluu Owerri nibi to ti n la ija laarin ọkọ ati iyawo.
Ileeṣẹ ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ ọhún mulẹ sọ pe, ọkunrin kan, Obumneke Onyemechileuzo lo n lu iyawo rẹ, Ogechi ni alubami, ki pasitọ naa to gbiyanju lati lawọn nija.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo, Mike Abattam ṣalaye pe pasitọ n gbiyanju lati ri pe ọkunrin naa ko gun iyawo lọbẹ ni ọkunrin yii fi gun pasitọ lọbẹ, lẹyin to si ṣubu lulẹ gbi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn agbẹjọ́rò tó dáńtọ́ ti wà ní Cotonou láti gba ìdáǹdé Sunday Igboho - Akitoye
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba Naijiria ti fi pampẹ̀ òfin mú Sunday Igboho?
- "Á dá ohun àlùmọ́ọ́nì wa jọ láti gbèjà Sunday Igboho nílé ẹjọ́"
- "Buhari, kí ló dé tó ń mu Sunday Igboho àti Kanu, amọ́ tó mu àwọn agbébọn?"
- Adájọ́ kò yọjú lọ́jọ́ ọdún Iléyá fún ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tí DSS kó nílé Sunday Igboho
- Ẹ rántí Buhari àtàwọn gómìnà nínú àdúrà bí ẹ ti ń ṣọdún Iléyá - Tinubu
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
"Nigba t'awọn ọlọpaa de ibi iṣẹlẹ naa, wọn ba ọkunrin yii nibi to ti n lu aya rẹ lọwọ.
Ti Ọgbẹni Onyemechileuzo ṣe rí awọn ọlọpaa ni o mura ìjà tí o sí gbiyanju lati gun ọlọpaa kan lọbẹ lọrùn.
Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa yinbọn fun un lẹsẹ lati le daabo bo ara wọn," Ọgbẹni Abattam ṣalaye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Onyemechileuzo pada ku lẹyin to ṣeṣe pẹlu ibọn to ba a lẹsẹ.
Ọgbẹni Abattam ṣalaye siwaju sii pe wọn gbe pasitọ ati Ọgbẹni Onyemechileuzo pẹlu aya rẹ lọ sile iwosan, nibi ti awọn dokita ti fìdí rẹ múlẹ pe pasitọ ati ọkunrin naa ti di oloogbe.
O ni iyawo rẹ si n gba itọju lọwọ nile iwosan nigba ti wọn si ti ko awọn oku lọ si mọṣuari.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa ti mu ọbẹ ti afurasi naa fi gun pasitọ lọ si agọ ọlọ́pàá.
Ẹwẹ, kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Imo ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa ṣe iwadii kikun lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.
Bakan naa ni kọmiṣọnna ọlọpaa rọ àwọn araalu lati maa lepa alaafia kí wọn sì maa bọwọ fún ofin.


















