Timothy Adegoke: Ọ̀gá Ọlọ́pàá ti jẹ́rìí lórí bí wọ́n ṣe rí òkú Timothy Adegoke

Rahmon Adedoyin ati Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, Rahmon Adedoyin and Timothy Adegoke/Facebook

Ọga Ọlọpa Olaniyan Afeez ti jẹri ni ile ejo giga ipinle Osun niwaju Adajọ, Adepele Ojo pé ọmọ Ramon Adedoyin tó jẹ́ alaga ni ile ìtura Hilton Hotel ni kí àwọn osise fi Bíbélì bura lẹyin ti Timothy Adegoke kú ní ilé itura naa.

Ọga Ọlọpa náà sọ pé ọ̀kàn lára àwọn afurasi ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Adeniyi Aderogba sọ nígba tí wọn gba ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ silẹ pe lẹyin ti wọn rí òkú Timothy Adegoke nínú yàrá room 305 ni ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ramoni Adedoyin sọ pé kí àwọn fi Bíbélì bura lẹyin ti iwadi ti fi mulẹ pe oun lọ tún ìwé eto Ile itura náà padà tí ó sì yọ orúkọ Timothy Adegoke kúrò lára àwọn tó wà sì ilé itura ọhun.

"Ọ̀rọ̀ tí Adeniyi Aderogba sọ fún wa nígbà tí a gbà ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ ní pe oun pẹlu arábìnrin Chiofina Madalina ni won rí òkú Timothy Adegoke nínú yàrá tí wọn ke si awon alakoso ilé itura pé nkan tó ṣẹlẹ ree.

Aderogba sọ pé ọmọ Ramoni Adedoyin darapo mọ àwọn nibẹ tí ó sì mú àwọn lọ sí inu yàrá kan pé kí a wọn fi Bíbélì bura pe awọn òní sọ fún ẹni kankan nipa iku àlejò náà.

Àkọlé fídíò, 'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'

Lẹyin tí wọn burú tán ni ago mọkanla àlè ni ojo Kàrún oṣù Kọnkanla ni iroyin sọ pe àwọn afurasi pẹlu orukọ yìí Kazeem Oyetunde, Adeniyi Aderogba àti Raheem Adedoyin gbé òkú náà lọ si ọna ilu Ẹdẹ ni ilu Ile Ifẹ tí wọn sì gbé e sì ẹ̀bá ọna pẹlu awon dukiya rẹ bii ẹrọ ayarabiaṣa laptop, ẹrọ ibanisọrọ ati owo oloogbe náà.

Bakan naa, Oga Ọlọpa, insipẹkitọ Olaniyan Afeez naa jẹri ni iwájú Adajo Adepele Ojo ti ilé ejò gíga ipinle Osun lórí bí wọ́n ṣe rí òkú Timothy Adegoke lèyín tí àwọn mọlẹbi pé akési ilé ìṣe Ọlọpaa ipinlẹ Osun.

Olaniyan Afeez sọ fun Ile ẹjọ pe awọn afurasi mẹta jewọ pe awọn ni wọn gbe ọku Timothy Adegoke lọ sí opopona Ẹdẹ ni ilu ile ìfẹ́ leyin ti awon bá òkú rẹ ni ninu yara 305 tí Hilton Hotel.

O tẹ siwaju pé ọkan larin awon afurasi naa ti oruko rẹ n jẹ Adesola Adedeji ni o tan imọle si ọrọ naa látàrí pé ó fi ẹrọ ibanisọrọ rẹ fi yà àwòrán iwe orukọ àwọn to wa sun ni ilé itura náà ati pe oloogbe fi owó orun ọjọ méjì ransẹ sii lórí ẹrọ transfer code nígbà tí ó fẹ gba yara naa.

Ọlọpaa naa ni, "a gbéra kúrò ní ìlú Osogbo lọ sì ilé ifẹ láti lọ sí ilé itura Hilton, nibẹ ni mo ti bere fún ìwé eto bí wọ́n ṣe gba àwọn tó sún wọlé láti oṣù kẹjọ sì oṣù konkanla ọdún lọ."

"Nínú iwadi wa, a ríi pé ìwé eto ti wọn gbé fún mi ní mọndaru nínú tí mo sì bere fún ẹni tó wà ní ẹnu ìṣẹ ni ojo Kàrún oṣù Kọnkanla náà."

O ṣalaye pe arabinrin to wa ni ẹnu ìṣe náà ni ojo Kàrún oṣù konkanla tí orúkọ ẹ jẹ Adesola Adedeji ni awọn gbé lọ si ìlú osogbo láti lọ fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ pẹlu ẹ ti a si gbe ìwé èto bí wọ́n ṣe gba àwọn eyan wọlé ní ọjọ́ Kàrún oṣù konkanla jade."

"Arabinrin naa yari pé kin ṣe ìwé tí óun fún oludari "manager àti checker" òun ti orukọ wọn n jẹ Adeniyi Aderogba àti Lawrence Oluwole ti wọn si buwọlu niyẹn ati pe èyí tí a fi han òun kí n ṣe nan tí òun yà sí orí ẹrọ ibanisoro òun."

o ni awọn afurasi to wa ni ọdọ awọn ti ṣaaju yari pé àwọn ko mọ nípa ikú arákùnrin náà àti pé oloogbe Timothy Adegoke kò wá sí ilé itura naa "ṣugbọn a tẹsiwaju níbi iwadi wá láti ìgbà èrò ẹnu wọn sílè, lẹyin ti a gbà ọrọ ẹnu wọn silẹ̀ ti a ṣí ìwé eto Ile itura Hilton hotel ni a rii pe ọwọ kiko arákùnrin Adeniyi Aderogba ni."

Lẹyin rẹ lo ni arákùnrin Adeniyi Aderogba jẹwo pe oun pelu arábìnrin Chiofina Madalina ni àwọn jọ rí òkú Timothy Adegoke nínú yàrá 305 tí wọn pe akiyesi awon alamojuto ilé itura naa eyi tí ọkan lára àwọn ọmọ Ramoni Adedoyin ton je Roheem Adedoyin wa to sì ni kín àwọn fi Bíbélì bura pe awon ó ní sì sọ fún ẹni kankan."

Iroyin ni lẹyin ti wọn ba òkú Timothy Adegoke nínú yàrá ni wọn gbé òkú náà lọ sí ilé kan ni ọna ilu Ẹdẹ ni Ilé ifẹ."

"A gbéra lọ síbẹ nibi ti a ti rí òkú Timothy Adegoke níbi tí àwọn ará àdúgbò tí wọn sin ín sí ti ń sọ pé òórùn òkú náà n da awọn láàmú."