Timothy Adegoke: Falana sọ fún ọ̀gá ọlọ́pàá láti dáwọn afurasí lórí ikú Timothy Adegoke padà sí Osun

Oríṣun àwòrán, Rahmon Adedoyin and Timothy Adegoke/Facebook
Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti ke pe ọga ọlọpaa Naijiria lati da awọn afurasi lori iku Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti OAU to ku sile itura, pada si ipinlẹ Osun fun igbẹjọ.
Falana ṣalaye ninu iwe to kọ si ọga agba ọlọpaa, Usman Baba pe, nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye lo yẹ ki igbẹjọ ti waye.
Igbẹjọ ọhun ti bẹrẹ nilu Abuja bayii, ti ipe Falana naa si bọ si asiko ti gbẹjọ miran yoo si waye lonii nibi ti awọn afurasi ati awọn ẹbi oloogbe Adegoke yoo peju si.
- Ṣé lóòtọ́ làwọn ọmọ Sunday Igboho kó COVID-19 ní Germany?
- Mo Abudu fèsì sọ̀rọ̀ tó gbòde pé o torí owó ní ìbálòpọ̀ pẹlú àwọn olóṣèlú
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
- Ìná alágbára ba ẹgbẹ́ta eékà ilẹ̀ ọgbà ẹranko jẹ́
- Ipò alága n da omi àlàáfíà ẹgbẹ́ APC rù l‘Oyo
- Ọgá ọlọ́pàá kìlọ fàwọn ọmọ iṣé rẹ tó yan ṣọ́ọ̀ṣì lilọ láàyò jù iṣẹ́ lọ,ẹ gbọ́ ohun tó sọ
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
Ọrọ ti Femi Falana sọ fawọn ọga agba ọlọpaa:
Falana sọ ninu iwe to kọ ranṣẹ si ọga agba ọlọpaa , IGP pe ko da gbogbo iwe ipẹjọ lori ọrọ naa pada fun agbẹjọro agba ipinlẹ Osun.
Falana ni "gẹgẹ bi ohun ti ẹbi oloogbe Adegoke sọ fun wa, ileeṣẹ ọlọpaa fọwọ ofin mu awọn afurasi kan lori isekupani Timothy nigba ti wọn si n wa awọn mii.
Amọ, ohun to ya wa lẹnu ni pe ileẹjọ giga niluu Abuja ni wọn gbe awọn afurasi ọhun lọ.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn ni igbimọ pọ ati ṣekupaniyan, igbimọ pọ lati fọwọ kan oku eeyan lọna aitọ ati igbiyanju lati ba ẹri jẹ.
Gbogbo awọn ẹsun iwa ọdaràn yii lo waye ni Ile Ife eyi to tumọ si pe ileẹjọ to wa nipinlẹ Osun lo yẹ ki igbẹjọ naa ti waye."
Bi Femi Falana ṣe di agbẹjọro fun ẹbi oloogbe Timothy Adegoke ree:
Ẹgbọn oloogbe, Olugbade Adegoke ṣalaye pe Femi Falana funra rẹ gan lo n pe oun lori ẹjọ Timothy ati bo se n lọ.
O ni Falana tẹwọ gba ẹjọ naa nigba to gbọ igbe awọn ọmọ Naijiria.
"Baba funra wọn gan ni wọn pe mi nigba ti wọn gbọ ohun tawọn ọmọ Naijiria n se, o ni Olugbade awọn ko ni gba owo lọwọ yin, ẹ ma sare kiri.
Owo ti awọn eeyan ba da, ẹyin ẹbi oloogbe, ẹ gbaa, kẹ maa fi se nnkan miran tori ẹni to n tọju yin lo ti ku yii.
Ti Timothy ba jẹ ọmọ inu mi, maa sa gba idajọ ododo fun."
Ni ọjọ kẹta oṣu keji ọdun 2022 yii ni ẹbi Timothy kọ iwe si ilumọọka agbẹjọro Falana lati bẹrẹ si ni ṣoju wọn ninu ẹjọ ọhun.
Iṣẹlẹ isekupani Timothy Adegoke se waye ni Ile Ife:
Ọjọ karun un oṣu kọkanla ọdun 2021 ni Adegoke rinrin ajo lati Abuja lọ si Ile Ife lati ṣe idanwo MBA ni fasiti OAU.
Ile itura Hilton hotel ni a gbọ pe o wa ki o to di pe o kan ṣadeedee di awati.
Lẹyin ọ rẹyin, oku Timothy ni wọn pada ri.
Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa mu oludasilẹ ile itura Hilton hotel, Ramon Adedoyin at'awọn afurasi mẹfa mii.
Ileeṣẹ ọlọpaa gbe wọn lọ sile ẹjọ niluu Abuja lori ẹsun pe wọn lọwọ si iku Adegoke.


















