Sunday Igboho: Yomi Aliyu ní àhámọ́ Igboho ní ìjọba Benin ń lò láti jẹ lára Nàíjíríà

Laipẹ yii ni iroyin kan ti ẹnu amofin to n duro fun awọn eeyan mejila ti awọn agbofinro DSS ko nile Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, eyiun Pelumi Olajengbesi, fi iroyin kan lede pe laipẹ laijina, gbajumọ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba naa yoo pada wale.
Amọṣa lọjọ Aiku ni iroyin jade lati ẹnu agbẹjọro Oloye Igboho funrarẹ gan an, iyẹn Amofin agba Yọmi Aliyu pe ko jọ rara o nitori pe awọn alaṣẹ lorilẹede Benin Republic nibi ti Sunday Igboho ti n jẹjọ ti fi oṣu mẹfa kun asiko rẹ lahamọ.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba kan si Amofin Yomi Aliyu lati mọ idi ti agbẹjọro meji se n tako ara wọn lori ọrọ Sunday Igboho.
Ninu alaye rẹ, Amofin agba Aliyu ṣalaye fun BBC Yoruba pe titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko si ẹsun kankan ninu iwe ipẹjọ tabi iwe ifisun Sunday Igboho ni Benin Republic, amọṣa, awọn alaṣẹ orilẹede naa ti n lo ẹjọ naa lati fi ṣe idunadura pẹlu ijọba orilẹede Naijiria.
Benin Republic ati Naijiria n fi ọrọ itimle Igboho ṣe idundura ni
O ni bi o ba ti ni ohunkohun tawọn alaṣẹ orilẹede Benin Republic ba fẹ gba lọwọ orilẹede Naijiria, ọrọ igbẹjọ ati itimọle Sunday Igboho ni wọn fi n ṣe idunadura rẹ.
"Ko ṣe nnkankan fun wọn. Ko si nnkankan ninu faili rẹ ṣugbọn wọn sun itimọle rẹ siwaju fun oṣu mẹfa.

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi
Ohun ti Pelumi Olajengbesi ba sọ nipa Igboho, ahesọ ọrọ ni - Aliyu
Nigba ti yoo tun sọrọ lori amofin Pẹlumi Olajẹngbesi ati ikede rẹ laipẹ yii pe Igboho ti n sunmọ itusilẹ ati ipada wale, Yọmi Aliyu ṣalaye pe, gbogbo iroyin nipa Igboho to ba ti ẹnu amofin naa jade kii ṣe ọrọ
Igboho nitori kii ṣe amofin fun ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba naa.
Aliyu ni bẹẹ ni Olajengbesi ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu Igboho lẹyin pe oun gba a lati gbẹjọ ro fun awọn eeyan mejila tawọn agbofinro ko nile Igboho ni ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.
O fi kun un pe o fihan pe eeyan miran lo n ran amofin Ọlajẹngbesi niṣẹ, kii ṣe Igboho mọ.
Amofin agba Aliyu sọ siwaju pe, " To ba sọrọ nipa Sunday, ẹlomiran lo ran an, kii ṣe Sunday Igboho.'
Lori Sunday Igboho o, ohun to ba sọ, ahesọ ni.'
Ko si ohun ti orilẹede Benin se, ti ko ni ọwọ ijọba Naijiria ninu tori ijẹ tiwọn:
Agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho naa ṣalaye pe orilẹede Benin ko lee da ohunkohun ṣe laifi ti Naijiria ṣe.
O ni idi ni pe ko si bi ọrọ aje wọn ṣe le gberu laisi ọwọ Naijiria nibẹ ati pe gbogbo ohun ti wọn n ṣe, ọna lati ṣeto ọna ijẹ fun orilẹede wọn ni.
O wa kan sara sile ẹjọ Naijiria pe wọn ti ṣe ohun to yẹ ni ṣiṣe lorilẹde Naijiria nipa gbigbe idajọ kalẹ ni kanmọkanmọ.
O ni iṣẹlẹ ikọlu si ile oloye Igboho waye ni oṣu keje, ile ẹjọ Naijiria si ti da a lare ni ọṣu kẹsan ọdun kan naa ṣugbọn orilẹede Benin Republic ni ọrọ ku si lọwọ bayii lati ṣe ohun to tọ.
Amọ Aliyu ni ṣugbọn oun ko da wọn lẹbi lori bi wọn ṣe n fi ẹsẹ falẹ nitori
Sunday Igboho yóò tún lo oṣù mẹ́fà si ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - Yomi Aliyu

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho, Agba amofin Yomi Aliyu SAN ti tako ọrọ kan ti akẹẹgbẹ rẹ nidi isẹ ofin, Pelumi Olajengbesi sọ pe Sunday Igboho ko ni pẹ kuro ni ọgba ẹwọn Cotonou laipẹ.
Pelumi Olajengbesi lo n soju fun awọn eeyan mejila ti DSS ko nile Sunday Igboho nigba ti Yomi Aliyu n soju fun Igboho lori ẹjọ to pe DSS ni Naijiria.
Ni ọjọ Abamẹta ni Olajengbesi fi ikede kan soju opo Facebook rẹ pe ijọba orilẹede Benin ko ni pẹ fi Igboho silẹ, ti iran Yoruba yoo si jo ijo ayọ, ọrọ naa si da ohun loju.
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Gani Adams ṣàlàyé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ń dènà ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho ní àhámọ́
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
- "Ẹ tètè gbé Sunday Igboho lọ fún ìtọ̀jú lókè òkun, kó tó pẹ́ jù"
- Iṣẹ́ wa rèé lábẹ́lẹ̀ láti gba ìdáǹdè Sunday Igboho ní Cotonou - YCE
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun
Ikede yii lo dun mọ ọpọ ọmọ Yoruba ninu, ti wọn si n fo fayọ pe awọn n reti ọjọ ti awọn yoo foju kan Igboho to ba gba ominira.
Yomi Aliyu tako Olajengbesi pe ohun to sọ, ko ri bẹẹ:
Amọ nigba to n fesi si ọrọ yii, Amofin Yomi Aliyu salaye fun iwe iroyin Vanguard pe ikede ti Olajengbesi se ko ri bẹẹ rara.
Aliyu ni lọwọ lọwọ bayii, ijọba orilẹede Benin ti pari gbogbo eto lati tun sọ ahamọ ti Igboho di ọtun fun osu mẹfa miran gbako.
Aliyu tọkasi pe bi o tilẹ jẹ pe wọn ko ri ẹsun iwa ọdaran kankan ka si Igboho lẹsẹ tabi tako iwe to ni ki wọn tu silẹ, amọ ijọba Benini ti tun gbe igbesẹ lati fi Igboho si ahamọ siwaju si.
"Yatọ si ikede ti agbẹjọro kan fisita, ijọba Benin tun ti gbe igbesẹ miran lati fi Oloye Sdunday Igboho si ahamọ ọgba ẹwọn fun osu mẹfa miran gbako.
Lootọ ni wọn ko ri ẹsun tabi ẹsẹ kankan ka si lọrun, ti ijọba Naijiria naa ko si beere pe ki wọn gbe wa si orilẹede yii amọ wọn sa tun fẹ se Igboho mọ aahamọ fun osu mẹfa miran si ni."
Ki lo sẹlẹ sẹyin?
Sunday Igboho ni awọn osisẹ agbofinro ni orilẹede Benin mu si ahamọ ni ọjọ Kkandinlogun osu Kejila ọdun 2021 ni papakọ Ofurufu Cadjèhoun nilu Cotonou, lorilẹede Benin.
Orilẹede Germany ni Igboho n lọ lati lọ gba itọju lasiko to sese nigba ti awọn osisẹ DSS ya bo ile rẹ ni ọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021.
Wọn pa eeyan meji nibẹ, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ pẹlu, bẹẹ ni wọn tun ko eeyan mejila lọ amọ wọn ko ri Sunday Igboho mu rara.
Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko awọn ohun ija oloro pamọ sinu ile rẹ lati doju ogun kọ ijọba Naijiria, to si tun n beere fun iyapa Yoruba Nation kuro lara Naijiria.
Ọjọ Kọkanlelogun osu Keje ọdun 2021 ni wọn fi oju Igboho ba ile ẹjọ Kotẹmilọrun ni Cotonou, ti wọn si sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ Aje to tẹle igbẹjọ naa.
Amọ lẹyin rẹ ni wọn sun igbẹjọ ọhun siwaju di ọjọ miran, ọjọ re lori awijare pe awọn si n se iwadi ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa lọwọ.
Lati igba naa ni ileẹjọ ti pasẹ pe ki wọn fi Sunday Igboho si ọgba ẹwọn nilu Cotonou ti wọn ko si se ẹjọ rẹ mọ.
Gbogbo igba si ni ọpọ ọmọ Yoruba atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ wọn n beere pe ki wọn fi Sunday Igboho silẹ ni ahamọ.

"Sunday Igboho yóò jáde ní àhámọ́ láìpẹ́, ariwo ayọ̀ yóò sọ nílẹ̀ Yorùbá"

Ilumọọka ajafẹtọẹni kan to tun jẹ gbajumọ agbẹjọro lorilẹede Naijiria, Pelumi Olajengbesi ti fi ọwọ sọya fun awọn ọmọ Yoruba pe wọn yoo ho iho ayọ laipẹ.
Olajengbesi jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro fun Sunday Igboho tẹlẹ, oun si lo gba idande awọn eeyan mejila ti DSS ko nile Igboho laipẹ yii.
Agbẹjọro naa lo kede bẹẹ loju opo Facebook rẹ pe iho ayọ naa n bọ nilẹ Yoruba nigba ti wọn ba tu gbajugbaja ajijagbara nni, Siunday Igboho silẹ ni ahamọ lorilẹede olominira Benin.
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- "Ajínigbé, ẹ sá kúrò nílẹ̀ Yorùbá, àwa Agbekoya ti jáde"
- Àwọn aráàlú Igboho bẹ̀rẹ̀ ìjà ẹ̀mí fún ìdáǹdè Sunday Igboho
- Ẹ gbé Sunday Igboho kúrò láhàmọ́ ọlọ́pàá wá sí ibi ìpamọ́ mìí ní Cotonou títí tí... - Adájọ́
- Igboho ń jà fún ìran rẹ̀ ni, kìí ṣe apànìyàn, ìjọba Benin, ẹ bá wa tú u sílẹ̀
- Akọ̀ròyìn tó fi fọ́nrán ohùn Igboho síta ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- "Àwọn ọ̀dọ́ ti ṣetán láti dá wàhálà sílẹ̀ fún ìdáǹdé Sunday Igboho"
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
Olajengbesi, ẹni to ni oun ko fi ọwọ sọya lori asan fikun pe, ọrọ naa da oun loju to ada, to si tun n fi ogun rẹ gbari pe Sunday Igboho ko ni pẹ kuro ni ahamọ.
Bakan naa lo fikun pe laisi aniani, akikanju eeyan, ẹni to ni igboya ni Sunday Igboho, to si ni àyà pupọ.
Alanikanjọpọn ni awọn agbaagba Yoruba - Olajengbesi
Bakan, lẹyin to kede itusilẹ Sunday Igboho ni ahamọ tan, ni ajafẹtọ ẹni naa tun bu ẹnu atẹ lu ọpọ awọn asaaju iran Yoruba.
Olajengbesi ni ọpọ awọn asaaju Yoruba yii lo mọ ti ara wọn nikan, ti wọn si tun jẹ awọn alanikanjọpọn.
O wa gba awọn ọmọ Yoruba nimọran pe ki wọn dẹkun iwa imọtaraẹni nikan, ki wọn si jẹ ki nnkan rere leke.
Olajengbesi ni "Laipẹ ni oloye Sunday Igboho ko ni pẹkuro ni ahamọ, ti ariwo ayọ yoo si gbalẹ kan jakejado ilẹ Yoruba.
Ko si aniani pe akikanju ati onigboya ẹda ni Sunday Igboho i se.
Ohun ti mo sọ yii da mi loju gan ni amọ mo fẹ ki awọn asaaju wa dẹkun iwa imọtaraẹninikan, ki wọn si gba nnkan rere lati fidi mulẹ."
Bawo ni Sunday Igboho se de ahamọ ati ibi ti ọrọ rẹ duro:

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi/ Facebook
Ki lo sẹlẹ sẹyin:
Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho lo n jija gbara fun ilẹ Yoruba, to si n doju kọ awọn afurasi darandaran to n jinigbe, paniyan ati afipabanilopọ.
Amọ nigba to ya, o n beere fun agbekalẹ orilẹede Yoruba, to si ni ọpọ eeyan to n tle lẹyin.
Ni ọjọ kinni osu Keje ọdun 2021 ni awọn osisẹ agbofinro DSS lọ sile rẹ ni oru nilu Ibadan, ti wọn si se ikọlu si nipa biba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ, ti eeyan meji si ku.
Lẹyin eyi ni wọn ri Igboho ni papakọ ofurufu nilu Cotonou ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn osu Keje ọdun 2021, to ni oun fẹ lọ gba itọju lorilẹede Germany amọ ti wọn mu si ahamọ.
O yọju sile ẹjọ amọ wọn ko gba idande rẹ, lati igba naa si lo ti wa ni ahamọ ni ọgba ẹwọn naa, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si ti n pe fun idande rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- ''Ọjọ́ ti mo jẹ́ 127,000 Pounds nídì tẹ́tẹ́ logún ọjọ́ pípẹ́ bẹ̀rẹ̀ nínú ayé mi''
- Ta ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON laarin Mane ati Salah?
- Ọbabìnrin Elizabeth kéde pé kí Camilla di ayaba tí ọkọ rẹ, Charles bá gun orí ìtẹ́
- Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún
- ''Àwa ẹgbẹ́ Agbekoya ṣetán láti tú Sunday Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n pẹ̀lú agbára àwọn àgba''
- Ènìyàn 24 dágbére fáyé, 9 farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abuja, Yobe
- Ìdíje fún sísọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ girama dí "Millionaire" lọ́dọọdún gbéra sọ- Yoruba World Centre
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ America fi sún ọjọ́ ìdájọ́ Hushpuppi síwájú
- Dominic Adigezi àti ọmọ rẹ̀ mẹ́ta kú sínú oko ní Abuja, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí




















