AFCON 2021 FINAL: Ta ni yoo gba ife ẹyẹ Afcon laarin Mane ati Salah?

Sadio Mane ati MO Salah n waako lori papa

Oríṣun àwòrán, John Powell/Getty Image

Ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba jẹ eleyi ti ọpọ maa n foju sọna fun ninu idije Afcon to maa n waye nilẹ Afrika.

Ti ọdun yii ko yatọ si tatẹyinwa. Koda oju awọn ololufẹ ere bọọlu n bẹ lọna nitori awọn ikọ meji to rapala de aṣekagba yii, ina piti ni wọn.

Egypt ati Senegal ni yoo dijọ waako lọjọ Aiku lati mọ ẹni ti wọn yoo de lade Ọba ere bọọlu ni Afrika.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni bayi, wọn ti gba ifẹsẹwọnsẹ mọkanlelaadọta ninu idije Afcon Cameroon 2021, ti papa iṣere Paul Biya to wa ni Olembe yoo si gbalejo asekagba naa.

Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo awọn ikọ mejeeji ati iru aṣeyọri ti wọn ti ni ṣẹyin ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii.

Sadio Mane ati MO Salah n waako lori papa

Oríṣun àwòrán, Shaun Botterill/Getty Image

Odu ni Egypt nibi ka maa gba ife ẹyẹ Afcon:

Ni meni meji, ba ba ni ka maa ka, Egypt ti gba ife ẹyẹ Afcon ni igba meje ọtọọtọ.

Ninu akọsilẹ, ko si orileede miran ni Afrika to sunmọ wọn tabi to gba ife ẹyẹ yii ju wọn lọ.

Ọdun 2010 ni wọn gba ife ẹyẹ naa kẹyin pẹlu bi wọn ti ṣe fagba han Black Stars Ghana pẹlu goolu kan sodo ninu aṣekagba.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba lati le fi kopa ninu idije Afcon, ta mọ si ''qualifiers'' ami ayo mejila ni wọn ko jọ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfaa.

Wọn lewaju isọri Keje lati le fi kopa ninu idije Afcon 2021.

Nigba ti wọn de idije naa, Naijiria da wọn lagbo sina pẹlu goolu kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ isọri kẹrin.

Ifidirẹmi yii dabi ẹni pe wọn ko ni tẹsiwaju ṣugbọn wọn gbọnra nu, ti wọn si gbiyanju titi ti wọn fi de aṣekagba.

Senegal naa ko kẹrẹ, o ni atamátàsé ati adẹ̀yìnmú gidi:

Orileede Senegal le ma gborukọ lori bi ti Egypt ṣugbọn awọn naa kii se aimọ lawujọ awọn orilẹede agbabọọlu ni Afrika.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ mejila ti wọn gba lera wọn, wọn ko fidi rẹmi ninu wọn. Wọn jawe olubori ninu mẹsan, wọn si gba ọmi ninu mẹta.

Goolu mẹrinlelogun ni wọn ti jẹ lati oṣu Keje ọdun to kọja ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn kopa ninu rẹ, ti goolu mẹfa pere si wọle si awọn wọn.

Bi a ba ni ka sọ nipa ikọ to ni atamatase ati awọn adẹyinmu ti ko kẹrẹ rara, Senegal jẹ ikọ to duro wamu wamu.

Lọdun yii ohun to wa lọkan wọn ni bi wọn yoo se ṣaseyọri ninu aṣekagba.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà mẹẹ̀dógún ni mo ti ṣẹ́ oyún'

Ki lo ti waye sẹyin ninu idije AFCON?

Lọdun 2002, Cameroon lo fidi wọn rẹmi ninu aṣekagba nipa pẹnariti, ti Algeria naa si gbewuro soju wọn ni Egypt pẹlu goolu kan sodo.

Ninu irinajo wọn de aṣekagba lọdun yii, wọn ko jẹ goolu pupọ ni ipele kini ṣugbọn wọn tẹsiwajulati leke isọri keji.

Igba ti wọn de abala komẹsẹoyọ ni wọn bẹrẹ si ni pitu. Goolu meji ni wọn fi da bantẹ iya fun Cape Verde lati ọwọ Sadio Mane ati Ahmadou Bamba Dieng.

Equitorial Guinea naa gba igbaju ati igbamu lọwọ wọn pẹlu goolu mẹta sookan.

Nigba ti Burkina Faso koju wọn ni abala to kangun si aṣekagba, goolu mẹta sookan lawọn naa fi gbara.

Nkan to ku bayi ni ki wọn koju Egypt ni aṣekagba. Boya wọn yoo gba ife yẹ Afcon ni igba akọkọ ninu itan orileede wọn.

Sadio Mane, Mo Salah, ta ni yoo ja mọ lọwọ?

Bo ti lẹ jẹ wi pe orileede meji ni yoo koju ara wọn, orukọ awọn agbabọọlu mejeeji yii, Sadio Mane ati Mo Salah lawọn eeyan n ran lẹnu.

Idi ni pe awọn mejeeji jijọ n ṣe ọrọ aje pẹlu ẹgbẹ agbagbọọlu Liverpool nilẹ Gẹẹsi ni.

Atamatase lawọn mejeeji, ti wọn si ti jijọ gba ami ẹyẹ agbabọọlu to pegede julọ ni Afrika.

Ti Senegal yoo ba bori Egypt, Sadio Mane yoo ni ipa ribiribi lati ko nipa didoju ija kọ awọn adilemu Egypt.

Amọ Salah naa ko ni gbẹni wa nitori pe oun naa yoo ja fita fita lati se bii ọkunrin.

Ipade wa di ori papa nirọlẹ oni lati mọ irin ti yoo tẹ fun ekeji laarin ikọ Egypt ati Senegal, Sadio Mane ati Mo Salah, ẹ ku oju lọna.

Àkọlé fídíò, Jejere