Yoruba World Centre: Ìdíje fún sísọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ girama dí "Millionaire" lọ́dọọdún gbéra sọ

Oríṣun àwòrán, @YWC
Idije koriya fun awọn ọmọ ilẹ Oodua to n ṣo ede Yoruba daadaa bẹrẹ.
Ọpọlọpọ owo lo ti wa nilẹ ti yoo sọ awọn akẹkọọ Yoruba di ọlọla lawujọ.
Ní oṣù kẹrin ọdún yìí ni àjọ Yorùbá ní àgbáyé (Yoruba World Centre) yóò bẹ̀rẹ̀ ìdíje láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ní àwọn ìpínlẹ̀ ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀ èdè yìí, ìpínlẹ̀ Kwara àti Kogi.
Ìdíje náà tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní "Àkókò láti gba àwọn ọ̀dọ́ wa padà" jẹ́ ọ̀nà láti pèsè ààyè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ̀bùn owó àti àwọn nǹkan mìíràn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́.
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Kí ló fà ogun Ìjàyè àti ìṣubú Kurunmi, ìfẹ́ ìlú ni àbí orí kunkun?
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Ìtàn ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko
- Ìtàn Manigbagbe: Àwọn àjakalẹ-àrun to ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tí kìí ṣe ọmọ káàárọ̀ oòjíire
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
Awọn wo lo n ṣe agbatẹru eto idagbasoke ede Yoruba naa?
Àwọn aláṣẹ àjọ náà ló kéde ọ̀rọ̀ ọ̀hún nìbi ìpàdé wọn kan pẹ̀lú àwọn adarí Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè ilẹ̀ Nàìjíríà níbi tí gbogbo àwọn alága wọn káàkiri Nàìjíríà péjú pésẹ̀ sí.
Alákoso àjọ Yorùbá World Centre, ọ̀gbẹ́ni Alao Adedayo ní ìdíje náà yóò wáyé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ilé iṣẹ́ Odu'a Investment Company Plc. àti DAWN Commission.
Adedayo ní àwọn ti rí àṣẹ gbà lọ́dọ̀ Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ àti àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀ èdè yìí àti Kwara láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdíje náà.
Ó ní ìjọba ìbílẹ̀ ní ìdíje náà yóò ti gbérasọ kó tó bọ́ sí ipele ìjọba ìpínlẹ̀ kó tó kan ipele àṣekágbá.
Kini Osinbajo ti kọkọ kede ṣaaju?
Ẹ ó rántí pé nínú oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá ni igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí, ọ̀jọ́gbọ́n Yemi Osinbajo ṣe ìfilọ́lẹ̀ Yorùbá World Centre, tó jẹ́ àkànṣe ètò International Centre for Yoruba Arts and Culture.
Adedayo ṣèrántí pé lára àfojúsùn àjọ náà ni bí àṣà, ìṣe àti ìgbàgbọ́ tó ti ń bọ́ sọnù lára àwọn ọ̀dọ́ ìwòyí yóò ṣe jẹ́ dídá padà.
Se 2022 nikan ni eto yii yoo waye?
Adadayo wòye pé ìdíje ọlọ́dọọdún yìí yóò jẹ́ ọ̀nà láti tọ́ àwọn ọ̀dọ́ sọ́nà kí ó sì mú ọjọ́ ọ̀la dúró ire pàápàá nípa kíkọ́ nípa ìtàn, àṣà, ìṣe àti èdè Yorùbá.
Bákan náà ló ní yóò jẹ́ ọ̀nà láti mú ìgbéga bá àṣà àti èdè Yorùbá bí ìmọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò ṣe máa lékún síi tí èdè Yorùbá kò sì ní lè parun láéláé.
- Mọ̀ sí i nípa Oba Yesufu Asanike, Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Tí òògùn owó bá wà nínú Ifa ni, n kò bá ti kọ́ ilé ńlá fún ara mi- Babaláwo
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Àwọn ọlọ́pàá méjì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀
- 'Mílíìkì ni a fẹ́ máa fi ẹbu tí a bá ri lára orí Sofia ti a jó pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé á máa di olówó'
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé


















